Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Republican 'fẹ́ pa mí', ọmọ ààrẹ Amẹ́ríkà fọhùn lórí ìgbẹ́jọ́ owó orí tó ń kojú

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọmọ ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, Hunter Biden ti fẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Republican pé an fẹ́ pa òun nítorí wọ́n ń w aọ̀nà láti gba ipò ààrẹ lọ́wọ́ bàbá òun.
Ó ní èrò wọn ni pé ikú òun máa lágbára fún bàbá òun, Joe Biden láti gbà mọ́ra.
Hunter Biden sọ èyí nígbà tó ń bá olórin kan, Moby sọ̀rọ̀ lórí ètò kan èyí tí wọ́n gbé sórí afẹ́fẹ́ lọ́jọ́ Ẹtì.
Ṣáájú ni Hunter Biden ti ń kojú ìgbẹ́jọ́ oní ẹ̀sùn mẹ́sàn-án lórí wí pé ó kọ̀ láti san owó orí.
Ìwé ìpẹ̀jọ́ oní abala mẹ́rìndínlọ́gọ́ta náà fẹ̀sùn kàn Hunter pé ó kọ̀ láti san owó orí tí iye rẹ̀ tó $1.4m láàárín ọdún 2016 sí ọdún 2019 àmọ́ tó ń gbé ìgbé ayé fàmílétè kí n tutọ́.
Gbogbo àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà sí Hunter lọ́rùn ló wáyé lásìkò tí bàbá rẹ̀ jẹ́ igbákejì ààrẹ lábẹ́ àkóso Barrack Obama.
Gbogbo àwọn ẹ̀sùn tí Hunter ń kojú yìí kò kan bàbá rẹ̀ tó jẹ́ ààrẹ Amẹ́ríkà lọ́wọ́lọ́wọ́, tí wọn kò sì dárúkọ rẹ̀ nínú ìwé ìpẹ̀jọ́ náà.
Tí Hunter bá jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tó ń kojú náà, ó ṣeéṣe kó fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́tàdínlógún gbára.
Báwo ni Hunter Biden ṣe ń pa mílíọ̀nù dọ́là sápò
Ẹ̀sùn tí wọ́n kà sí Hunter lọ́rùn ọ̀hún ṣàfihàn bí owó tùùlù tuulu tí iye rẹ̀ tó mílíọ̀nù méje dọ́là láàárín ọdún 2016 sí ọdún 2020 ṣe ń wọ akoto owó rẹ̀.
Wọ́n ní ọ̀pọ̀ owó náà ló wọ akoto owó àwọn ilé iṣẹ́ rẹ̀, Owasco, PC àti pé wọ́n tún gba àwọn owó náà sí akoto ilé iṣẹ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Skaneateles tó ní ìdá márùndínláàádọ́rin ìdókoòwò sí.
Fún ọdún méjì, bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2015 ni Hunter Biden fi bá iléeṣẹ́ ohun àmúṣagbára kan tó jẹ́ ti orílẹ̀ èdè China ìyẹn CECF China Energy dòwò pọ̀.
Ní ọdún 2017 ni wọ́n ṣèlérí láti fún Hunter ní mílíọ̀nù kan dọ́là lórí iṣẹ́ kan pẹ̀lú iléeṣẹ́ CECF, State Energy HK, iléeṣẹ́ Hong Kong kan.
Bákan náà ló tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú fún ilé iṣẹ́ ohun àmúṣagbára ti orílẹ̀ èdè Ukraine kan ìyẹn Burisma Holdings ní oṣù Kẹrin ọdún 2014 tí wọ́n sì ń fun ní owó oṣù tí iye rẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù kan dọ́là lọ́dún.
Nígbà tó di oṣù Kẹta ọdún 2017 ni wọ́n dín owó náà kù sí nǹkan bíi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta dọ́là lọ́dún.
Ìwé ìpẹ̀jọ́ tí wọ́n fi pe Hunter lẹ́jọ́ ka àwọn owó tó wọlé fún Hunter pé ó gba $1,002,016 lọ́dún 2016, $630,556 lọ́dún 2017, $491,939 lọ́dún 2018, àti $160,207 lọ́dún 2019.
Hunter sọ fún BBC pé wọ́n gba òun láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Burisma nítorí wọ́n pàtàkì orúkọ òun.
Báwo ni Hunter Biden ṣe ná àwọn owó náà?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn tó pe ọmọ ààrẹ náà lẹ́jọ́ ní egbògi olóró, obìnrin, ọkọ̀ bọ̀gìnì, aṣọ àtàwọn afẹ́ ayé ni Hunter ná owó rẹ̀ lé lórí.
Ìwé ẹ̀sùn náà ní ó ná tó $1m lọ́dún 2016, $1.4m lọ́dún 2017, $1.8m lọ́dún 2018, àti $600,000 lọ́dún 2019.
Wọ́n ní $1.6m ló gbà jáde láti ẹnu ATM láàárín ọdún 2016 sí 2019 nìkan.
Bákan náà ni wọ́n tún fẹ̀sùn kàn-án pé ó ná owó tó lé ní $683,000 fún àwọn obìnrin oríṣiríṣi àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó mìíràn lórí àwọn afẹ́ ayé.
Wọ́n ní ọ̀kan-ò-jọ̀kan ilé ìtura ni Hunter Biden ná owó lé lórí tó sì kọ̀ láti ní ibùgbé kan pàtó. Ní New York City, Los Angeles àti Washington DC ni àwọn ilé ìtura náà wà.
Báwo ló ṣe kùnà láti má san owó orí ?
Olùpẹjọ́ fẹ̀sùn kan Hunter Biden pé ó máa kọ àwọn owó tó ná lọ́wọ́ ara rẹ̀ bíi pé ìdí iṣẹ́ rẹ̀ ló náwọn lé nítorí kó má ba à fi san owó orí tó pọ̀.
Wọ́n ní ó máa ń kọ àwọn ọkọ̀ tó máa ń yá láti fi ṣafẹ́ ayé sábẹ́ wí pé òun fi ṣe iṣẹ́ ni.
Wọ́n fi kun pé lọ́dún 2018 ló sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ kan láti fi orúkọ àwọn obìnrin mẹ́ta tó ń bá ní àjọṣepọ̀ sábẹ́ ètò ìlera adójútòfò.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ní ó kọ pé òun ṣwe ìrìnàjò lọ́dún 2018 tó sì jẹ́ pé kò lọ sí ibikíbi.
Báyìí ni Hunter ṣe fi ọ̀rọ̀ kóbá ara rẹ̀
Àwọn olùpejọ́ ní ìwé tí Hunter Biden kọ nípa ara rẹ̀ ìyẹn Beautiful things ló ti fi gbogbo àwọn ẹ̀sùn tí àwọn kà si lọ́rùn múlẹ̀.
Wọ́n ní ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun kò ṣiṣẹ́ púpọ̀ lọ́dún 2018 àmọ́ tó ná àwọn owó rẹ̀ lórí ọtí àti egbògi olóró fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù.
Wọ́n ṣàlàyé pé nígbà tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn olùsirò owó California lọ́dún 2018, ó ní òun ná tó owó $388,810 lórí iṣẹ́ àmọ́ tó kọ sínú ìwé rẹ̀ pé egbògi olóró, fífa sìgá ni òun ń fi gbogbo ọjọ́ òun ‘se lọ́dún náà.
Hunter kọ sínú ìwé rẹ̀ pé láti oṣù Kẹrin ọdún 2018 síwájú, òun àtàwọn jàgùdà, ọlọ́tí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni àwọn jọ máa ń wà ní gbogbo ìgbà.
Bákan náà ni wọ́n ní àwọn ilé ìtura tó kọ sínú ìwé rẹ̀ pé àwọn ti máa ń ṣe àwọn ìwà kò tọ́ yìí náà ló máa ń kọ kalẹ̀ pé òun lò láti fi ṣiṣẹ́.
Ẹgbẹ́ òṣèlú Republican fẹ́ pamí – Hunter Biden fèsì

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọmọ ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, Hunter Biden ti fẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Republican pé an fẹ́ pa òun nítorí wọ́n ń w aọ̀nà láti gba ipò ààrẹ lọ́wọ́ bàbá òun.
Ó ní èrò wọn ni pé ikú òun máa lágbára fún bàbá òun, Joe Biden láti gbà mọ́ra.
Hunter Biden sọ èyí nígbà tó ń bá olórin kan, Moby sọ̀rọ̀ lórí ètò kan èyí tí wọ́n gbé sórí afẹ́fẹ́ lọ́jọ́ Ẹtì.
Ṣáájú kí wọ́n tó pe Hunter Biden lẹ́jọ́ lórí wí pé ó kọ̀ láti san owó orí tó yẹ lọ́jọ́bọ̀ ni wọ́n ti ṣe ètò náà kalẹ̀ àmọ́ tí wọn kò ìtíì gbe jáde lórí afẹ́fẹ́.
Ẹgbẹ́ Republican ni wọ́n ti ń fẹ̀sùn kan ààrẹ Biden àti ọmọ rẹ̀ pé wọ́n ń lo ipò wọn láti máa hu àwọn ìwà kò tọ́ kan.
Hunter Biden ní àwọn Republicans ń wá gbogbo ọ̀nà láti fi dojú ìjọba bàbá òun délẹ̀ tí wọ́n sì fẹ́ lo òun gẹ́gẹ́ bí pàṣán.
Ọmọ ààrẹ náà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń móríbọ́ lọ́wọ́ lílo oògùn olóró ní wọ́n fẹ́ kí òun padà lílo oògùn olóró ni àmọ́ òun kò ní gbà fún wọn.
Ó fi kun pé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n ń kà sí òun lọ́rùn kìí ṣe nítorí ti òun bíkòṣe nítorí bàbá òun.















