Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan ń yí ìwé lórúkọ Akeredolu, Kọmísọ́nà pariwo síta

Oríṣun àwòrán, Ondo State Govt
Kọmisọna fun ọrọ alumọni nipinlẹ Ondo, Engr Razaq Obe ti kọ lẹta si igbakeji gomima, Lucky Ayedatiwa lati pe akiyesi rẹ si ohun to pe ni bi awọn eeyan kan to di ipo ṣelu mu ni ipinlẹ naa ṣe yii iwe lorukọ gomina naa, Rotimi Akeredolu.
Obe ni oun kẹfin iwa yii ninu iwe ti wọn fi ransẹ si ẹka ìjọba oun lati ọdọ akọwe ijọba ipinlẹ Ondo.
"Mo kẹfin iwa yii lẹyin ti mo ri bi wọn ṣe buwọlu iwe yii ati ilana ti wọn fi kọ ọ.
"Pẹlu gbogbo bi nnkan ṣe ri lasiko yii, mo ti ṣe ẹtọ mi lati mu eyi wa si eti igbọ rẹ gẹgẹ bii ọkan lara agba nidi oṣelu ijọba ipinlẹ Ondo
Obe wa rọ Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo lati mu ọrọ naa ni ọkundundun ki wọn si gbe igbesẹ ni kiakia.
Bakan naa ọkan lara agba Agbẹjọro lorilẹede Naijiria, Dr Kayode Ajulo naa pẹlu awọn to pariwo sita lori ẹrọ momaworan Arise, to si fẹsun kan awọn osisẹ ìjọba ninu isejọba ipinlẹ Ondo tí yi iwe lorukọ Gomina Ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu.
Ifẹsun yìí lo ti da wahala silẹ laarin awọn osisẹ ìjọba.
Ẹgbẹ OEA fesi pada Kọmisọna
Ẹgbẹ ọmọ ilu ipinlẹ Ondo tí bu ẹnu atẹlu bi Kọmisọna fun eto alumọni nipinlẹ Ondo, Rasaq Obe ṣe kọ lẹta si igbakeji gomima lati so fun pe awọn kan yii iwe lorukọ Gomina Ipinlẹ Ondo.
Ẹgbẹ naa fẹsun kan Obe pe o n gbinyanju lati tan awọn araalu ati lati da wahala silẹ laarin ilu lati kọyin si ijọba.
Oloye Yemi Oladiran, akọwe ẹgbẹ lọ gba ẹnu ẹgbẹ naa sọrọ sita pe ọrọ ti Obe sọ le da wahala silẹ.
"Ohun iyalẹnu lati ri ọmọ ẹgbẹ isejọba kan to n pe fun iwadi fun ẹsun pe awọn kan yi iwe lai gba àṣẹ lọwọ Gomina, ẹni to yan sì isẹ..
"Kí lode tí Kọmisọna yii ko sọrọ sita nigba ti Gomina buwọlu owo lati tun ọfisi rẹ ṣe, kí lóde tí pariwo síta pe wọn yii iwe.
"Nigba ti Gomina buwọlu N150m lati se eto DevelopOndo, kí ló de tí ko sọrọ sita."
"Igbesẹ lati fi iwe han síta tabi pe fun iwadi lẹyin ti Gomina ni ọrọ ko ri ẹ.
"O yẹ ki Kọmisọna sọ fun awọn ẹsọ alabo lati se iwadi.
"Bakan naa ni o fura si bi Kọmisọna Rasaq Obe ṣe kọ lẹta to yẹ ko kọ sí Gomina sì Igbakeji gomima mu ifura dani.
"Àṣẹ wo ni Obe ni lati ṣe ayẹwo lori iwe Gomina lai gba àṣẹ lọwọ Gomina.
Bakan naa ni ẹgbẹ naa ni o se koko ki awọn ẹlẹsọ abo ṣe iwadi lori ẹsun naa.












