Ilé ẹjọ́ tó ga jù ní Colorado yọ ọwọ́ Trump kúró nínú ìdìbò 2024

Aworan Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ile ẹjọ to ga julọ nipinlẹ Colorado, lorilẹede America, lo ti dajọ pe Donald Trump ko le kopa ninu idibo aarẹ ọdun to n bọ nipinlẹ naa.

Igbimọ ẹlẹni meje ile ẹjọ naa ni mẹrin ninu wọn wi pe Trump ko lẹtọ lati kopa ninu idibo naa nitori iwa iditemọjọba to hu ni bii ọdun mẹta sẹyin.

Ẹwẹ, idajọ yii ko da Trump duro lati kopa ninu idije naa lawọn ipinlẹ miran.

Igbimọ ipolongo ibo fun Ọgbẹni Trump lo ni awọn yoo kọja siwaju ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede America lati kọ idajọ naa ti wọn juwe bii ohun to ni aleebu.

Ninu idajọ ọhun ni awọn adajọ ti darukọ eto idibo abẹle ti ẹgbẹ oṣelu Republican lọjọ karun oṣu kẹta, ọdun to n bọ lati yan oludije sipo aarẹ lẹgbẹ naa, amọ ti idajọ naa le nipa ni Colorado lori idibo apapọ ti yoo waye loṣu kọkanla.

Eyi ni igba akọkọ ti wọn yoo lo abala kẹta ninu atunṣe kẹrinla si ofin ilẹ America lati fi da oludije sipo aarẹ kọkan duro.

Idajọ naa, ti wọn gbe kalẹ lọjọ iṣẹgun, ti wọn si ti gba idaduro imulo rẹ titi di igba ti ipẹjọ kotẹmilọrun yoo waye loṣu to n bọ, ni imuṣẹ rẹ ko kọja ipinlẹ naa.

Awọn adajọ naa kọ sinu idajọ wọn pe “Lasan kọ la gunlẹ si ikorita yii, a wo gbogbo ibeere to wa niwaju wa finnifinni.

“Bakan naa la ro arojinlẹ lori ṣiṣe amulo ofin lai bẹru tabi ṣe ojuṣaaju, ati lati maṣe jẹ ki ohun tawọn araalu n sọ o yi ohun ti ofin sọ pada.”

Idajọ yii lo tako ohun ti ile ẹjọ kan ni Colorado sọ ṣaaju pe ọrọ iditemọjọba ti wọn sọ ni atunṣe kẹrinla si ofin ilẹ naa ko ni ohunkohun ṣe pẹlu awọn aarẹ nitori pe ko si orukọ awọn aare nibẹ.

Idajọ ile ẹjọ giga Colorado ni ko le bẹrẹ iṣe titi di ọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2024, to jẹ adọla ọjọ ti wọn gbọdọ tẹ iwe idibo abẹle nipinlẹ naa.

Kini awọn eeyan sọ nipa idajọ yi?

Aworan Vivek Ramaswamy

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Steven Cheung, to jẹ agbẹnusọ fun ikọ ipolongo ibo Trump, tabuku awọn adajọ naa to jẹ pe gomina ẹgbẹ Democrats lo yan wọn sipo.

Cheung wi pe “Awọn adari ẹgbẹ oṣelu Democrat ni ọkan wọn ko balẹ mọ nitori bi Trump ṣe n gbajumọ sii to si n lewọ iwaju ninu awọn ibo ori ayelujara.

“Won ko nigbagbọ ninu ijoba Biden mọ, wọn wa n ṣe gbogbo nkan ti wọn lee fi da awọn oludibo duro lati ma lee le wọn kuro lori aleefa loṣu kọkanla ọdun to n bọ.”

Cheung fi kun pe awọn agbẹro Trump yoo fiwe ṣọwọ sileẹjọ to ga julọ l’America laipẹ, nibi ti awọn kọnsafetifu ti jẹ mẹfa si mẹta.

Awọn to n ṣe agbatẹru ipadabọ Aarẹ Biden ni ko sọ ohunkohun nipa idajọ naa, amọ agba ọjẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Democrat to si nii ṣe pẹlu ipolongo ibo Biden wi pe idajọ naa ṣegbe lẹyin awijare ẹgbẹ wọn pe akọlu to waye ni Capitol lo jẹ iditẹmọjọba.

O fi kun pe eyi yoo jẹ ki ẹgbẹ wọn o lee ṣe afihan iyatọ nla to wa laarin Aarẹ Biden ati Ọgbẹni Trump.

Ẹwẹ, awọn aṣofin to jẹ ọmọ ẹgbẹ Republican lo ti tabuku idajọ naa, to fi mọ abẹnugan ile aṣojuṣofin, Mike Johnson, to pee ni “a dọgbọn ṣegbe lẹyin ẹgbẹ kan”.

Johnson wi pe “lai fi ti ẹgbẹ oṣelu ṣe, gbogbo ẹni to ba forukọ silẹ lati dibo lo yẹ ko lẹtọ lati lee ṣe atilẹyin fun aarẹ wa tẹlẹ ri ati ẹni to jẹ olubori ninu gbogbo ibo abẹle to n waye lẹgbẹ Republican”.

Awọn oludije miran lẹgbẹ Republican naa lo ti bu ẹnu atẹ lu idajọ naa, ti Ọgbẹni Vivek Ramaswamy si wi pe oun yoo kọ lati kopa ninu eto idibo naa ti wọn ko ba gba ki Trump o kopa.

Ọgbeni Trump ni ko mẹnu ba ọrọ naa lakoko to n ba awọn oludibo sọrọ ni Iowa lalẹ ọjọ Iṣẹgun, amọ atẹjiṣẹ ti igbimọ ipolongo rẹ fi ranṣẹ sawọn alatitilẹyin rẹ n lo wi pe “bi ijọba apasẹ waa ṣe maa n bẹrẹ ree”.

Bakan naa ni ẹgbẹ Republican nipinlẹ Colorado wi pe awọn yoo yọwọ nibi idibo abẹle naa ti idajọ naa ba duro.

Ki ni atunṣe kẹrinla ofin America?

Atunṣe kẹrinla ni wọn buwọ lu lẹyin ogun abẹle ilẹ America. Abala kẹta ofin naa ni wọn fi gbero lati fofin de awọn to fẹẹ yapa kuro lati ma lee pada sipo ijọba ti wọn wa ti awọn ipinlẹ guusu ba pada darapọ mọ iṣokan America.

Wọn lo ofin naa tako aarẹ ‘Confederate States of America’, Jefferson Davis, ati igbakeji rẹ, Alexander Stephens, ti wọn jijọ wa nile aṣofin ki wọn to yapa.

Iṣamulo ofin yii ni ko fi bẹẹ wọpọ lati igba naa wa.