South Africa Polyandry law: Àwọn aṣòfin ń gbé ìgbésẹ́ lórí òfin tí yóò fààyè gba obìnrin láti ní ọkọ méjì

Oríṣun àwòrán, People daily
Ki lo ṣe bi orilẹede Naijiria ba gbe ofin kan kalẹ pe awọn obinrin le e fẹ ju ọkọ kan lọ, gẹgẹ bi awọn ọkunrin kan ṣe n fẹ ju iyawo kan lọ bayii?
Idi ta fi n beere ibeere yii ni pe oye to kan ara Iwo, le kan ara Ẹdẹ, bẹẹ si ni iku to n pa ojugba ẹni, owe nla lo n pa fun ni.
Lorilẹede South Africa, igbesẹ ti n wa bayii lati gbe ofin kan kalẹ eleyi ti yoo fi aye gba awọn obinrin lati fẹ ju ọkọ kan ṣoṣo lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Màá pe Kọ̀mísánà ọlọ́pàá Eko àti igbákejì rẹ̀ lẹ́jọ́ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha - Amofin
- Ojú mi rí màbo nígbà tí mo bímọ àkọ́bí, ẹ̀ṣẹ̀ ni ká bímọ láì rí owó tọ́jú rẹ̀ - Lizzy Anjorin
- Shehu Sani fi olùwọ́de Yoruba Nation ṣe ẹlẹ́yà torí òjò tó tú wọn ká
- Àgbà ọ̀jẹ̀ akọrin Fuji, Amoo Igisekele, jáde láyé
- Àwọn olùwọ̀de Yoruba Nation mú afurasí òṣìṣẹ́ DSS níbi ìwọ́de l‘Osogbo
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá rí ọmọ oṣù kan he lẹ́ba ọ̀nà lẹ́yìn tí wọ́n gbé e sọnù l'Eko
- Kò sẹ́ni tó lè ní kí n má yan àwọn Baálẹ̀ nílùú Akure- Ọba Aladetoyinbo Aladelusi
Eyi wa lara awọn atunṣe tuntun ti wọn fẹ ko de ba ofin igbeyawo lorilẹede naa.
Amọṣa, awọn ẹgbẹ oṣelu kan to fara ti awọn ẹlẹsin gẹgẹ bi oludibo wọn, ti fariga lori eyi.
Alaga ẹgbẹ oṣelu Al-Jama-ah, Ganief Hendricks ni, ẹgbẹ oṣelu naa yoo fara mọ awọn iwọde itagbangba lati tako igbesẹ naa.
Eyiun bi aba lori agbekalẹ ofin ti yoo faye gba obinrin lati ni ju ọkọ kan ṣoṣo lọ, eleyi to wa ninu iwe aba ijọba orilẹede naa, ba parada di ofin.
Gẹgẹ bi ẹgbẹ naa ṣe sọ, ojuṣe ijọba ni lati "rii daju pe iwa ọmọluwabi jọba lawujọ"
Igbimọ onidajọ ẹsin musulumi lorilẹede naa, Muslim Judicial Council ṣalaye pe, ajeji ni aṣa ki obirin ni ju ọkọ kan lọ jẹ ninu ẹsin Islam.
Agbẹnusọ fun igbimọ naa, Muneer Abdouroaf ni awọn ko ni lee fọwọsii rara.
Bakan naa ni aarẹ ẹgbẹ ACDP, Ẹni ọwọ Meshoe MP ṣalaye ni tirẹ pe, bi wọn ba yiri ọrọ naa ni igba igba, awọn ko lee fọwọ si igbesẹ naa.
Agbẹnusọ fun Biṣọọbu agba ijọ Anglican nilu Capetown, Wendy Kelderman sọ wi pe mimẹnu le ọrọ naa lai ti jẹ pe aba naa ti de iwaju igbimọ awọn ijọ Ọlọrun lorilẹede South Africa, yoo fẹ dabi ẹni n ṣiwaju ẹlẹẹdẹ pẹẹdẹ.
Nigba to n gbe iwe aba naa sita, minisita fọrọ abẹle, Ọmọwe Aaron Motsoaledi ni ibẹrẹ ijiroro to ṣe pataki ni eyi jẹ, eyi ti yoo ṣe afọmọ eto igbeyawo lorilẹede South Africa.
"Igbesẹ naa wa lati ṣawari awọn ohun to n mu ipaya ba awọn eeyan lori ọrọ igbeyawo, ṣugbọn yoo faye silẹ fun ijiroro lorilẹede South Africa ati loke okun."


















