Women inclusion Agenda: Mọ̀ nípa òfin mẹ́ta tó mú Aisha Buhari àti àwọn obìnrin yabo ilé aṣòfin

Aisha Buhari ati olori ile a#sofin, Femi Gbajabiamil

Oríṣun àwòrán, HOUSENGR

Ọjọ Iṣẹgun ni ile aṣofin Naijiria gba lati jiroro lori awọn aba ofin mẹta to nii ṣe pẹlu awọn obinrin, ati idagbasoke wọn.

Lara aba ofin naa ni eyi to sọ pe anfaani gbọdọ wa fun awọn obinrin lati ko ìdá marundinlogoji ipo oṣelu. Ṣugbọn, awọn aṣofin kọ aba naa.

Amọ, ni ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọjọ to jẹ ayajọ awọn obinrin, ogunlọgọ obinrin lo ṣe iwọde lọ si ile aṣofin naa fun igba keji, lati bere fun awọn ofin ti yoo mu ilọsiwaju ba wọn.

Ile aṣofin sọ pe oun kọ awọn aba naa nitori pe awọn aṣofin to fọwọ si ko pọ to iye to jẹ, lasiko ti wọn n ṣe agbeyẹwo ati ofin ọdun 1999 ni ọsẹ to kọja.

Awọn aṣofin kọ awọn aba naa, botilẹ jẹ pe iyawo aarẹ, Aisha Buhari fun'ra rẹ lọ si ile aṣofin naa lasiko ti igbimọ to ṣagbeyẹwo ofin gbe abọ iwadii rẹ kalẹ, lati ri daju pe wọn buwọlu wọn.

Lasiko iwọde naa, awọn obinrin kọ̀ lati fi ọgba ile aṣofin silẹ titi awọn olori fi ba wọn sọrọ.

Eyi si lo mu awọn alaṣẹ jẹjẹ pe awọn yoo tun ṣe agbeyẹwo awọn aba ofin naa.

Àkọlé fídíò, Ṣé ó lòdì sí òfin Ọlọ́run kí Krìstẹ́ni jẹ Ọba ilẹ̀ Yorùba? Pásítọ̀ ìjọ Deeper Life sọ ìran tó rí tó fi gbà láti jẹ Ọba
Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf

Kini awọn aba ofin mẹta yii to jẹ ẹdun ọkan fun awọn obinrin Naijiria?

Wọn fẹ ki ọmọ ilẹ okeere ọkunrin to ba fẹ wọn ni ẹtọ lati di ọmọ Naijiria

Awọn obinrin to se iwọde lọ sile aṣofin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lara awọn aba naa ni pe ki ayipada ba ofin to nii ṣe pẹlu ipo ọkunrin to jẹ ọmọ ilẹ okeere, amọ to fẹ obinrin Naijriia gẹgẹ bi iyawo.

Wọn ni awọn n fẹ ki ọkunrin to ba fẹ obinrin ni Naijiria le kọwe lati di ọmọ Naijiria, gẹgẹ bi igbeyawo sẹ ma n sọ obinrin to ba fẹ ọmọ ilẹ okeere di ọmọ onilu ni orilẹ-ede ọkọ rẹ.

Ki obinrin le di ọmọ ipinlẹ ọkọ rẹ

Ofin keji ti awọn obirin tun n fẹ ki wọn o buwọlu ni pe ki obinrin ni ẹtọ lati di ọmọ ipinlẹ ti ọkọ rẹ ti wa ni Naijiria.

Wọn ni ti igbeyawo wọn ba ti le ni ọdun marun, obinrin naa gbọdọ le pe ara rẹ ni ọmọ ipinlẹ ọkọ rẹ.

Aisha Buhari ati awọn obinrin ti wọn jọ lọ sile aṣofin

Oríṣun àwòrán, Aisha buhari

Ipo oṣelu

Ofin kẹta ni pe wọn n fẹ ki ida marundinlogoji awọn ipo oṣelu jẹ ti awọn obinrin, ninu gbogbo ẹgbẹ oṣelu to wa ni Naijiria.

Bakan naa ni wọn sọ pe awọm fẹ ki ida marundinlogoji ninu ọgọrun awọn aṣofin jẹ obinrin.