Plateau state couple death: Ojú mi báyìí ni ọmọ mi pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ ṣe jóná gúrúgúrú- ìyá olóògbé

Oríṣun àwòrán, Others
"Ojú mi ni ọmọ mi pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ ṣe jóná gúrúgúrú"
Iya to bi Mercy Joseph, arabirin ti oun ati ọkọ rẹ jona kọja ala ni ipinlẹ Plateau ti sọ pe iṣẹlẹ naa da omi tutu si oun lọkan.
Arabirin Kaneng ṣlaye fun BBC pe digbadigba ni oun sare lọ sile tọkọ-taya naa nigba ti oun gbọ pe ile wọn ti n jona, ti oun si ri ọpọ awọn eeyan ti wọn pohunrere ẹkun nibẹ.
- Ọkùnrin àkọ́kọ́ tó ṣàṣeyọrí lílo ọkàn ẹlẹ́dẹ̀ láti mi ti padà kú o!
- 'Gbogbo ẹ̀yà ara Bamise Ayanwole ló pé nígbà tí mo rí òkú rẹ̀'
- A ti rí ilé ti à ń lọ lọ́ọ̀kán báyìí díẹ̀ ló kù - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye lásíkò àjọyọ̀ ìtúsílẹ̀ Sunday Igboho
- Ademola Adeleke ní igun kíni PDP ní Osogbo fà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ oyè láti díje dupò gómìnà Osun
- Timothy Adegoke: Ìyàwó Timothy Adegoke jẹ́rìí nípa ọkọ rẹ̀ nílé ẹjọ́, gbọ́ nípa ìjà tó jà fún ọkọ̀ rẹ̀
- Ademola Adeleke ní igun kíni PDP ní Osogbo fà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ oyè láti díje dupò gómìnà Osun
Kini o kọ́kọ́ sẹlẹ̀?
Ọjọ kẹta, oṣu Kẹta yii ni tọkọ-taya ọhun, Mercy Joseph ati Gideon Pam jade laye lẹyin ti ina kan ṣadede sọ ninu ile wọn ni ijọba ibilẹ Iwọ oorun Jos.
Oṣu Kẹfa, ọdun to kọja ni wọn ṣe igbeyawo, awọn mejeji si bi ọmọ kekere jojolo ti ọjọ ori rẹ ko tii ju iwọn ba oṣu diẹ lọ.
Gbogbo nnkan ti tọkọ-taya naa ni lo jona guruguru ayafi ọmọ wọn jojolo ti wọn ti kọkọ gbe kuro ninu ile naa ṣaaju.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye:
Iroyin ni epo diesel ni ọkọ n ta ni orita Zawan, o si ti pẹ to ti n ṣe owo naa.
Lọjọ ti iṣẹlẹ laabi naa waye, ẹnikan lo wa ke si oloogbe ọhun pe epo wa nile epo to ti maa n ra epo, ko si tete lọ ra nitori ọwọngogo epo to wa lode.
Eyii lo mu ko sare tete lọ sinu ile lati lọ ko awọn kẹẹgi wa, amọ bo ṣe n rọ epo lati inu kẹegi kan si omiran ni ina sọ lara ọkan lara awọn kẹẹgi ọhun, ti ko si le jade mọninu ile naa.

Oríṣun àwòrán, @Plateau Fire Service
Ni kete ti iyawo rẹ wọle to si ri pe ina ti mu ọkọ oun loun naa kan lu ina ọhun lọna ati doola ọkọ rẹ, amọ ina tun mu oun naa.
Nigba ti awọn oṣiṣẹ panapana to pa ina ọhun ba BBC sọrọ, wọn gba awọn araalu niyanju lati dẹkun ati maa ko epo pamọ sinu ile.
Wayi o, iya oloogbe naa ti sọ pe inu ibanujẹ nla ni oun wa bayii ati pe yoo pe oun lati ku pẹlu awọn oloogbe naa ju ki oun wa laye lọ.
"Lọwọ yii, ko si ohun ti mo n duro ṣe mọ nile aye, ni ṣe lo yẹ ki wọn jẹ ki n jona pẹlu wọn."















