Mauricio Pochettino: Ṣé Pochettino lè gba ife ẹ̀yẹ UEFA Champions League tí PSG ń wá fún wọn?

Mauricio Pochettino

Oríṣun àwòrán, PSG

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lẹyin ọ rẹyin, Mauricio Pochettino di akọnimọọgba tuntun fẹgbẹ agbabọọlu Paris St-Germain(PSG).

Pochettino ti buwọ luwe adehun lati ṣiṣẹ gẹgẹ akọnimọọgba fun ikọ agbabọọlu PSG fun ọdun meji pẹlu adehun miran lati fi ọdun kan kun un.

Oun lo rọpo Thomas Tuchel to padanu iṣẹ rẹ lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2020 lẹyin to ti tukọ ẹgbẹ agbabọọlu naa fun ọdun meji ati aabọ.

Pochettino ko ti ṣiṣẹ akọnimọọgba lati igba to ti fi ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham silẹ ti Jose Mourinho si rọpo rẹ.

Akọnimọọgba Pochettino naa ti figba kan ri ṣoju PSG gẹgẹ bi agbabọọlu laarin ọdun 2001 si 2003.

Ipo kẹta ni PSG lori tabili idije Lique 1, ati pe Barcelona ni wọn yoo koju ni ipele ẹlẹni mẹrindinlogun(round of 16) ninu idije Champions League loṣu keji ati ikẹta ọdun 2021 yii.

Ọjọ Aiku ọjọ kẹta oṣu kinni ọdun 2021 yii ni Pochettino yoo bẹrẹ iṣakuso rẹ ni PSG.

Mauricio Pochettino

Oríṣun àwòrán, Getty Images

''Idunnu lo jẹ fun mi lati de ipo akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu yii. Gbogbo igba ni mo maa n ṣafẹri ẹgbẹ agbabọọlu yii,'' Pochettino lo sọ bẹẹ.

Pochettino ni oun ''ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbaọjẹ agbabọọlu to wa ni PSG.''

Ninu ọrọ tirẹ, alaga igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa, Nasser Al-Khelaifi sọ pe Pochettino gan an lo to gbangba sun lọyẹ lati tukọ ẹgbẹ agbabọọlu PSG.

Ẹgbẹ agbabọọlu Espanyol ni Pochettino ti kọkọ ṣiṣẹ gẹgẹ bi akọnimọọgba.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Lẹyin naa lọ si ikọ agbabọọlu Southampton nibi to ti lo ọdun kan ati abọ ki o to darapọ mọ Tottenham lọdun 2014.

Amọm ibeere kan tawọn eeyan n beere ni pe bo ya Pochettino le gba ife ẹyẹ UEFA Champions League ti PSG ti n gbiyanju lati gba fun wọn.

Lootọọ ni Pochettino gbe Tottenham de ipele aṣekagba Champions League lọdun 2019 ṣugbọn wọn fidi rẹmi, Liverpool lo lu wọn gba ife naa.