Mí ò gba àbẹ́tẹ́lẹ̀ rí ní ọgbọ̀n ọdún ti mo fi ṣíṣẹ́ ọlọ́pàá- CSP Francis Osagie

Mí ò tí gba àbẹ́tẹ́lẹ̀ rí ní ọgbsn ọdún ti mo fi ṣíṣẹ́ ọlọ́pàá- CSP Francis Osagie

Oríṣun àwòrán, Igberetv

Ọ̀gá ọlọ́pàá kan ti kọ̀wé fi iṣẹ́ ọlọ́pàá sílẹ̀ nítorí ǹkan ti ó pè ni ìyànjẹ lẹ́nú iṣẹ́ ọlọ́pàá.

CSP Francis Osagie Erhabor, DPO ọlọ́pàá tó wà ní ẹ̀ka 'D' divison Itam ni Uyo tó jẹ́ olúùlú ìpínlẹ̀ Akwa Ibom.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lásìkò tí àwọn ilé iṣẹ́ kan fún ni àmìn ẹ̀yẹ ọlọ́pàá tọ pegedé jùlọ ni Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bi àwọn ènìyàn ṣe díbò fun lórí ayélujára, lò ti sọ pé, ní ìwọ̀n ọgbọ̀n ọdún tí òun tí n ṣíṣẹ́ ọlọ́pàá òun kò ti gbà àbẹ̀tẹ́lẹ̀ rí.

Erhabor tó ti kọ̀wé fiṣẹ́ ọlọ́pàá sílẹ̀ báyìí sọ pé òun ti kọ mílíọ̀nù 864 owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ rí.

Lásìkò tó n ṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú IgereTV , ló fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn pé wan yan òun jẹ lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́pàá bi wọ́n ṣe kọ̀ láti fún òun ni ìgbéga ni ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ akin tí òun ti ṣe.

Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ; Mo wọ iṣẹ́ ọlọ́pàá gẹ́gẹ́ bi "Cadet inspector" ni ọjọ́ keji , oṣù kẹrin ọdún 1990, mo wà ni ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún nígbà náà.'Ọ̀pọ̀ àwọn ọgá àgbà ti mó bá lẹ́nu iṣẹ́ lásìkò náà lo sọ fún mi pé, irú mi gan ni wọ́n ń wá lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́pàá.

"Mo nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè yìí gan, mo si ri iṣẹ́ ọlọ́pàá gẹ́gẹ́ bi ibi tí mo ti le sin ilú bàbá mi"

Báwo ni ọ̀rọ̀ owó #864 mílíọ̀nù ṣe jẹ́?

" Gẹ́gẹ́ bi olùdári àgbàgbè ọ̀pá epo ni ìpínlẹ̀ Edo, mo kọ mo kọ mílíọnù mẹ́fà abọ ọlọ́ṣọ̀ṣẹ̀, owó náà jẹ́ 288mílíọ̀nù ni ọdún kan àti 864 ni ààrín ọdún mẹ́ta tí mo lò níbẹ̀bẹ̀"

"Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ àwọn alábà ṣiṣẹ́ pọ̀ mi ló ń pè mi ni òpònú, sùgbọ́n ò''otọ́ ìbẹ̀ ni pé, bí wọ́n bá tun gbá àdáwò irú rẹ̀ wá ni ọjọ́ míràn, ń o tún bori.

"Ibanujẹ ọkàn ló jẹ́ fún mi láti ri àwọn ọmọ tọ wọ iṣẹ́ lẹ́yìn mi tí wan sì n gba ìgbéga, odidi ọgbọ̀n ọdún ni mo fi sòfò"