Side effects of birth control: Wo ipa tí òògùn ìfètò sọ́mọ́ bíbí le ní lára rẹ

Oríṣun àwòrán, others
Ṣé o fẹ́ lo òògùn ìfètò sọ́mọ́ bíbí?
Wo ipa tó le ní lára rẹ kí o tó lò ó
Bi ẹgbẹẹgbẹ̀rún obinrin ni agbaye ṣe n lo oogun oyinbo lati feto si ọmọ bibi, naa ni Vanessa , obìnrin kan to n gbe ni ilu Boston, lorilẹ-ede America naa se n lo.
Sugbọn abajade rẹ fun Vanessa yatọ si ti si ti awọn obinrin to ku.
O ti ẹ sọ pe abajade oogun naa lara oun ti yi igbeaye oun pada titi aye.
- Ṣé lóòtọ́ ní àwọn jàǹdùkú jó ìlé 200 àti ọ̀kọ́ 29 ní Ibadan?
- ''Èmi àti òkú ìyá mí ni a jọ ń gbé fún ọdún mẹ́wàá ''
- Wo ọ̀nà márùn ún tí o fi lè rí owó láti fi ṣòwò lọ̀dún 2021 pẹlu ìrọ̀rùn
- Wo bí o ṣe lè di ọmọ onílùú ní Dubai pẹ̀lú òfin tuntun orílẹ́èdè U.A.E.
- Èèyàn mẹ́tàdínlógún(17) jọ́ná ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ bọ́ọ̀sì lópòpóónà Bode-Saadu sí Jebba
Kini o ṣẹlẹ si Vanessa?
Vanessa salaye pe: 'Mo ro pe mo ni aisan ẹjẹ rírú ni'
Ile ni mo wa lọjọ naa, ti mo fẹ ẹ gun oke, ni mo sakiyesi pe o nira fun mi lati mi.
"Iru nkan bẹ ẹ ko ṣẹlẹ si mi ri."
Vanessa kuku lọ si ibi isẹ rẹ lọjọ naa, lai fi ilera rẹ ṣe.
Àmọ́ o ya si ileewosan naa.
Kini Vanessa ba bọ nile iwosan to lọ?
Vanessa ni: "Wọn fun mi ni nkan ti yoo si ibi ti èémí n gba wọle-jade ni ara mi.
" Ara tu mi diẹ, mo si bẹrẹ si ni i mi.
"Wọn ni kí n lọ ya fọto ẹ̀dọ̀fòòró mi, nibẹ ni wọn ti sọ fun mi pe wọn ri òjìji kan."
Ojiji bi i ti bawo?
Ni ọjọ keji, wọn sọ fun Vanessa pe ko ni aisan ẹjẹ rírú, sugbọn yoo se ayẹwo míì.
Bawo ni irinajo Vanessa ṣe lọ nile iwosan?
O to oṣu kan ko to o ni anfaani lati ri dokita.
Nigba ti yoo si fi ri i, bo ṣe n mi ti buru ju ti tẹlẹ lọ.
Vanessa ni: "Ile ni mo wa lọjọ naa ti mo n fọ aṣọ. Mo fẹ ẹ lọ mu nkan ni oke, ni èémí mi tun salọ.
Vanessa ni: "Kia ni mo ṣi bọtinni aṣọ ti mo wọ, ki n to ṣubú si ilẹ ile ìdáná nitori pe mi o le mí mọ.
"Nise ni gbogbo ara mi dabi i pe o ti poora.
Ikùn, aya, ati apá bẹrẹ si ni i ro mi. Mo ro pe ma a mi ẹ̀jẹ̀ rírú ni."
Vanessa ko lọ sileewosan, sugbọn o pe dokita rẹ lori foonu. Oun lo si gba a nimọran pe ko tete lọ sileewosan ni kiakia.
Ayẹwo ti wọn ṣe fun lo fihan pe ẹ̀jẹ̀ ti di si àyà rẹ ni. Ohun lo si di ọna ti eemi n gba.
Dokita sọ fun un pe o ṣe e ṣe ko jẹ oogun ifetosọmọ bibi to n lo lo fa a.
Awọn anfaani oogun ifetosọmọ bibi:
Ti o ba lo deedee:
- Oogun ifetosọmọbibi a maa n dena oyun ni ọna ìdá mọkandinlọgọrun.
- Ko ni idiwọ fun ibalopọ
- O ṣaba ma n mu ki nkan oṣu rẹ wa deede, ko kere, lai mu inira lọwọ
- O le din irora ku saaju ki nkan oṣu to o bẹrẹ
- O le din ewu oyun iju, ati aarun ti kii se jẹjẹrẹ inu ọmú ku
- O le din kokoro ara ku
Kii ṣe gbogbo eeyan ni ẹ̀jẹ̀ maa n di si ni àyà ṣugbọn alaye ree lori bi o ṣe le ṣẹlẹ:
Iṣẹ ti eroja estrogen ati progesterone to wa ninu awọn oogun ifetosọmọ bibi ma n se ni pe o ma n da ẹyin obìnrin dúró 'ovulation' ati oyun.
Ni ṣe ni yoo mu ki omi to wa ni ẹnu ọna ile ọmọ obìnrin ko ki debi i pe àtọ̀ ọkùnrin ko ni le raaye kọja sinu ile ọmọ.
Gẹgẹ bi dokita onimọ nipa ẹ̀yà ara obinrin kan ṣe sọ lorilẹ-ede South Africa, Dokita Nene Zozo ṣe sọ, abajade ti awọn oogun naa ma n ni ni ara ni èébì, ara sísan, inu wiwu ati kokoro ara.
O ni, ori fifọ, ìrora ninu ọmú, tabi ki wọn o ma le jẹun daadaa ni abajade ti awọn obinrin mii ma n ni.
Dokita Nene ṣalaye pe awọn eroja to maa n pese ẹ̀jẹ̀ wa ninu ara, sugbọn ti wọn ba ti ko firi kokoro aifojuri, o se e ṣe ki ẹ̀jẹ̀ o ma a di ninu ara.
Yatọ si awọn abajade yii, ajọ to n mojuto eto ilera lorilẹ-ede United Kingdom, NHS, sọ lori ayelujara rẹ pe oogun ifetosọmọ bibi tun le fa Ẹ̀jẹ̀ riru.
Ki obinrin ma a ri ẹ̀jẹ̀ kekeeke ni oju ara rẹ fun oṣu diẹ lẹyin to ba bẹrẹ si ni i lo oogun naa.
Bakan naa ni ayẹwo fihan pe o lọwọ ninu bi awọn obinrin kan ṣe ni jẹjẹrẹ ọmú ati bi ẹ̀jẹ̀ ṣe n di ninu ara wọn.
Awọn kan wà ninu oogun naa to le fa aisan rọpa-rọsẹ.
Sugbọn ṣa, anfaani wa lati tete parọ ilana ifetosọmọ bibi naa ti ko ba ọ lara mu. Sugbọn rii daju pe o ba dokita sọrọ nipa akiyesi rẹ.
- 82% ọkùnrin ní kó mọ̀ pé òun ní àìsàn jẹjẹrẹ asẹtọ ní Naijiria
- Kí ni àyájọ́ ‘Má wọ kọ́mú’ wà fún?
- Ṣé lọ́ọ̀tọ̀ ní àkúdááyà wà? ẹ̀ wo ìrírí àwọn tó rí ènìyàn wọn tó kú láàyè
- Ẹ yé ṣí ìhòhò ara yín síta lórí ayélujára torí ‘Silhouette Challenge’ - Adeboye
- Wo ọ̀nà márùn ún tí o fi lè rí owó láti fi ṣòwò lọ̀dún 2021 pẹlu ìrọ̀rùn





















