Abuja accidents: Àjọ FRSC ní ọ̀kànlélúgba èèyàn(201) ló dèrò ọ̀run nínú ìjàmbá ọkọ̀ l'Abuja

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijamba ọkọ mẹrindinlẹgbẹrun(994) lo ṣẹlẹ ni olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja ni ọdun 2020 to lọ.
Ọga ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC, Ọgbẹni Gora Wobin lo fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin niluu Abuja.
Ọgbẹni Wobin ṣalaye pe iye ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lasiko tawọn ṣe agbeyẹwo rẹ fihan pe nọmba ijamba to ṣẹlẹ ti dinku si ti ọdun 2019.
- Ìdí tí wọn kii fi jẹ́ kí obìnrin jẹ Ọ̀ọ̀ni ni Ile Ife
- Ìdí rèé tí Ibadan ṣe ja ogun Kiriji pẹ̀lú Ekiti àti Ijesha f'ọ́dún mẹ́rìndínlógún
- Kábíyèsí Ooni ti forí jin Sunday Igboho lẹ́yìn tó túúbá- Ààfin Ile Ife
- Ta ló pa ẹbí olùrànlọ́wọ́ Gómìnà Rotimi Akeredolu nínú oko rẹ̀ l'Ondo?
- Wo ìdí tí ìjọba Buhari fi ti àkáúǹtì àwọn tó ń ṣe kátà kárà owó ''cryptocurrency'' pa
Ọga ajọ FRSC ni ijamba ọkọ mejilelogoji le lẹgbẹrun lo ṣẹlẹ lọdun 2019.
''Ẹgbẹrun kan ati okoo le lugba le mẹta awọn ọkọ to ni ijamba niluj Abuja, nigba ti ojilelugba eeayan le mẹjọ(248) lo ku niluu Abuja,'' ọga ajọ FRSC lo sọ bẹẹ.
Ọga FRSC Abuja ni eeyan sọ pe eeyan mọkalelugba(201) lo ku ninu ijamba ijamba ọkọ lọdun 2020.
''Iye awọn to farapa naa dinku lọdun 2020 si ọdun 2019, eeyan 1,728 lo farapa ninu ijamba ọkọ ni 2020 nigba ti 2,385 ṣeṣe lọdun 2019.

Eeyan 2, 603 lo mori bọ ninu ijamba ọkọ lọdun 2020, nigba ti ori ko 3,375 eeyan yọ ni 2019.
Ọgbẹni Wobin sọ pe ere asapajude, ẹru adiju, taya fifọ, yiya ọkọ mii lọna aitọ ati aifọkan si ọkọ wiwa lawọn nkan to maa n ṣe okunfa ijamba ọkọ.
- Wo àwọn gbajúgbajà ojú ti EFCC máa ba ṣe ẹjọ́ ní 2021
- Ìdí tí wọn kii fi jẹ́ kí obìnrin jẹ Ọ̀ọ̀ni ni Ile Ife
- Ta ló pa ẹbí olùrànlọ́wọ́ Gómìnà Rotimi Akeredolu nínú oko rẹ̀ l'Ondo?
- Wo ìdí tí ìjọba Buhari fi ti àkáúǹtì àwọn tó ń ṣe kátà kárà owó ''cryptocurrency'' pa
- Dúkìá mi tó tó N500m ni mo pàdánú, àmọ́ ó wù mí láti padà sí Igangan- Seriki Fulani



















