HIV Death: Mọ̀ sí i nípa obìnrin alárùn HIV, tó n ran àwọn alárùn bí tiẹ̀ lọ́wọ́ láti kú ikú rere

Thembi duro pẹlu patako to ni awọn ami idanimọ HIV

Oríṣun àwòrán, Shali Reddy

Ogunlọgọ eeyan lo ti ti oju Thembi Nkambule ku, nitori aarun Aids, ni Eswatini - orilẹ-ede nibi ti eeyan kan ninu mẹrin ti ni HIV.

Oriṣiriṣi ẹkọ si ni Thembi ti kọ lati ara awọn iṣẹlẹ, ati itumọ ki eeyan ku iku rere.

Oriṣi iku mẹta ni Thembi ti ri laye.

Akọkọ ni eyi to wọpọ julọ. Ẹni naa yoo wo oju Thembi, yoo si sọ pe "O pari, mo ti gba kamu". Iku buruku ni iru iku yii, nitori pe igbeaye ikọkọ ati itiju ni ẹni naa gbe.

Iku keji gẹgẹ bi Thembi ṣe sọ, ni eyi to jẹ pe "ẹni naa ni ikilọ tabi imọran fun ẹbi to gbẹhin rẹ. Wọn fẹ ki awọn eeyan wọn kẹkọọ lara igbeaye wọn.

Iku kẹta lo dara ju. Ẹni naa ti mọ pe oun yoo ku, o si mọ pe ipo to dara ni oun yoo fi ẹbi oun silẹ si lai si ija. Iru ẹni yii ko nilo Thembi lati wa nibẹ to ba fẹ ku, amọ ko wọpọ ko ma si nibi ti alaisan ba ti fẹ ku.

Aisan naa ni AIDS.

Thembi

Oríṣun àwòrán, Shali Reddy

Àkọlé àwòrán, Apẹẹrẹ ti Thembi fi ma n mọ ẹni to ti ni HIV ni pe 'wọn ma n poora, wọn si ma n pa ẹkọ wọn ti ni fasiti

Orilẹ-ede Eswatini, to ti fi igba kan jẹ Swaziland - ni ibi ti ajọ World Health Organization pe ni ibi ti aarun HIV ati AIDS pọ si ju ni agbaye.

Bo tilẹ jẹ pe orilẹ-ede naa ti gbiyanju lati bi ọdun diẹ ninu amojuto aarun naa, aarin eeyan 1.3 miliọnu to n gbe nibẹ ni HIV pọ si ju lọ ni agbaye. Ida mẹrindinlọgbọn lo ni.

Thembi ṣẹṣẹ wọ ile ọkọ ni, to si jẹ akẹkọọ ni Fasiti Swaziland ni nkan bi ọdun 1990, nigba to kọkọ gbọ nipa HIV.

Akoko naa jẹ igba ti awọn eeyan orilẹ-ede naa n finu-findọ fi ẹjẹ silẹ fun awọn alaisan.

Diẹ lara awọn ọrẹ naa fi ẹjẹ silẹ, amọ lẹyin ọsẹ diẹ, wọn ko wa sileewe mọ.

"Iroyin to n lọ nigba ni pe wọn ri aarun aṣekupani ninu ẹjẹ wọn. Ijọba ko sọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn iroyin to n lọ ni pe iku lo n gbẹyin ẹni to ba ti aarun naa."

Aworan bi Thembi ṣe n sọ fun ẹbi rẹ

Oríṣun àwòrán, Shali Reddy

Àkọlé àwòrán, Thembi sọ fun idile rẹ pe oun ko fẹ ẹ fi aarun naa ṣe ọrọ aṣiri nigba to ni i.

Ibẹru gba ilẹ ni fasiti naa, eyi ti ko si jẹ ki Thembi ati awọn ọrẹ rẹ yooku fi ẹjẹ silẹ.

"A lero pe ti a ko ba fi ẹjẹ silẹ, wọn o ni le sọ fun wa pe ẹjẹ wa ni aarun."

Ọdun diẹ lẹyin rẹ, ti Thembi ti di olukọ nileewe girama, ni imọ rẹ nipa HIV pọ si.

Ọpọ eeyan to mọ; awọn ọrẹ, akẹẹgbẹ, ati akẹkọọ rẹ, lo ti ni aarun naa.

Ohun kan to ma n jẹ ko mọ pe eeyan ti ni aarun naa ni pe wọn ma n di awati, nipa fifi ara pamọ. Lẹyin ọsẹ diẹ, ikede iku wọn ninu iwe iroyin lo ma n ri, amọ wọn ko ni i sọ orukọ aarun to pa wọn.

Bo tilẹ jẹ pe imọ ijinlẹ sọ pe aarun naa le ran nipa ibalopọ, sibẹ awọn olori ilu kan fi kun pe awọn to ba jẹ oniṣina, to n ni ibalopọ buruku nikan lo n ni.

Eyi si ni awọn pasitọ kan fi ma n waasu.

Aworan awọn to n fi ọwọ kan ọwọ

Oríṣun àwòrán, Shali Reddy

Àkọlé àwòrán, Thembi sọ pe iku rere ni iku akikanu, lai si aṣiri ikọkọ kankan

Ṣugbọn, Thembi gbagbọ pe irọ ni, nitori pe o mọ obinrin kan ti ko ni ibalopọ pẹlu ọkunrin mii lẹyin ọkọ rẹ, ṣugbọn ti AIDS pa.

Idẹyẹsi ati itiju ti awọn to ni HIV n ba pade lo mu ki Thembi pinnu lati ma a jẹ olutunu fun wọn.

O ma n lọ si ile wọn lati ba wọn ṣere, jiroro, titi di ọjọ iku wọn.

Amọ lọdun 2002, Thembi fun'ra rẹ di alarun HIV. Ọkọ rẹ naa ni. Ikọ lo kọkọ bẹrẹ, ki ayẹwo to o fihan pe HIV ni.

Igbesẹ akinkanju ti Thembi gbe ni pe o kede fun gbogbo eeyan pe oun ti ni aarun naa, eyi ti ẹnikẹni ko ṣe ri.

Wọn pe awọn ọmọ wọn ati ẹbi joko, wọn si ṣalaye fun wọn nipa aarun ti wọn ni, iru itọju ti wọn yoo gba, ati pe ko le ran ẹnikẹni nipa didimọ ara ẹni, tabi jọ lo baluwẹ kan naa.

Ibẹru iku mu oun paapaa, nitori pe aadọta Dọla ni wọn n ta oogun HIV ti eeyan yoo lo fun oṣu kan nigba naa, eyi to jẹ pupọ lara owo to n wọle fun thembi ati idile rẹ.

Thembi pada di oludari ajọ to n mojuto aarun naa ni Eswatini, o si n lo iriri rẹ pẹlu aarun naa lati mu ki awọn to ni i ba sọrọ.

Ọpọlọpọ alarun HIV si lo ma n sọ fun pe ko wa pẹlu wọn ni awọn ọjọ to gbẹyin aye wọn, nitori pe wọn mọ pe ara wọn ni.

"Mi o ki n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ẹbẹ wọn rara. Mo si mọ nkan ti wọn fẹ ni akoko naa laijẹ pe wọn sọ ọrọ kankan jade.

Aworan Thembi nibi to ti n kan ilẹkun

Oríṣun àwòrán, Shali Reddy

Àkọlé àwòrán, Thembi ma n ṣe abẹwo si awọn eeyan to mọ pe wọn ko ni alabaro lasiko ti HIV fẹ ẹ pa wọn

Awọn kan lara wọn kan fẹ ki n di wọn mu, awọn mi kan fẹ ki n ṣa wa pẹlu wọn nigba ti wọn ba mi eemi igbẹyin.

"Ohun ti wọn ba fẹ, ni mo n ṣe."

O ma n fun wọn ni iku rere.

Kini iku to dara?

Ọrọ nipa iku to dara ko jẹ tuntun. Lọdun 1601, alufa ijọ Church of England, Christopher Sutton kọ iwe pe iku to dara ni ki eeyan o ku si ori ibusun rẹ, lasiko ti ẹbi rẹ yii ka.

O ṣalaye pe iku ojiji ni eyi ti ẹni naa ko dagbere fun ẹbi, bikose pe aisan sọ di agbana fun wọn.

O si ti di ọrọ ijiroro laarin awọn to n pese itọju igbẹyin.

Awọn onimọ iṣegun nilẹ America sọ pe iku rere ni eyi ti ko mu inira dani fun alaisan, ẹbi ati awọn to n tọju rẹ.

Thembi sọ pe awọn ti aarun AIDS n pa bayii ti dinku ni Eswatini, ju ti igba ti oun funra rẹ ko aarun naa.

Amọ, pẹlu ilana isede fun itankalẹ aarun Covid-19, o ṣe e ṣe ki awọn to ni aarun naa tun pọ si.

Eyi to ti mu idiwọ ba iranwọ eroja idaabobo lọwọ aarun HIV ati AIDS.

Thembi ma n ri daju pe o ran ẹnikẹni ti aarun naa ba l'agbara ni ara rẹ leti pe, iku rere ni isinmi.

O ni, o ma n nira fun ẹnikẹni ti aarun HIV ba pa lati gba kadara, ki wọn si fi aye silẹ lai kabamọ .

"Mo ma n sọ fun wọn pe ki o ni isinmi ati ifọkanbalẹ ninu ara rẹ lo ṣe pataki ju ninu ipo ti o wa yii, nitori bi o ba ṣe ṣe ara rẹ, ni awsn eeyan yoo ṣe ṣe ọ.