Ondo Nurses'strike: Nítorí 'áfúsá', àwọn nọ́ọ̀sì bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì l'Ondo gba àsanpé owó oṣù wọn

Awọn nọọsi n wọde

Oríṣun àwòrán, thenewstrack.com.ng

Awọn nọọsi ati oṣiṣẹ agbẹbi ni ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ iyanṣẹlodi onikilọ ọlọjọ mẹta lati fi fa ijọba ipinlẹ naa leti lori sisan abọ owo osu fawọn.

Ẹgbẹ awọn nọọsi ati agbẹbi lorilẹ-ede Naijiria, (NANNM) ẹka ti ipinlẹ Ondo bẹrẹ iyanṣẹlodi lọjọ Aje, ọjọ kinni, oṣu kẹta, ọdun 2021.

Gẹgẹ bi ohun tawọn igbimọ adari ẹgbẹ naa fi sita pe awọn n ja fun, sisa asanpe owo oṣu wọn dipo aabọ eyi ti gomina ipinlẹ naa ni ki wọn maa san fawọn oṣiṣẹ pẹlu bibẹrẹ ilana owo osu tuntun fawọn nọọsi lẹka nijọba ibilẹ wa lara ohun ti wọn n beere fun.

Àkọlé fídíò, Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn

Ṣaaju ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ nọọsi ati agbẹbi naa ti kọkọ fun ijọba ni gbendeke ojọ meje lati fi yanju ibeere wọn naa ṣugbọn ti ko si igbesẹ to yanranti latọdọ ijọba.

Àkọlé fídíò, Femi Falana, Endsars: Awolowo kò fáààyè gba kí èèyàn máa yàgò fún Màálù nígboro

Lasiko ti BBC News Yoruba gbiyanju ati kan si alaga ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Ondo, ohun ti a gbọ ni pe ijọba atawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lẹka ilera wa ninu ipade kan eleyi ti ko ṣai nii ṣe pẹlu rukerudo iyanṣẹlodi lẹka ilera ni ipinlẹ Ondo.

Àkọlé fídíò, Mother tongue day 2021, Akomolede, YSAN: A ti parí iṣẹ́ lórí èdè ìperí Meta-Language Yorùb