Harry and Markle: Ọmọba Harry sọ nípa ìgbé ayé tuntun tó ń gbé pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ ní California ní Amerika

Oríṣun àwòrán, EPA
Ọmọba Harry, Duke Sussex ti sọrọ lori igbe aye tuntun rẹ pẹlu iyawo rẹ, Meghan Markle ati ọmọba tuntun Archie ni Amerika.
Harry ṣalaye ni kikun idi ti oun ati Markle ṣe fi London silẹ lọ si orilẹ-ede Amẹrika.
Wọnyii ni koko marun un ti Ọmọba Harry sọ nipa igbe aye tuntun ti oun ati idile rẹ n gbe l'Amerika.
1. Harry tẹsiwaju pẹlu ṣiṣe iranwọ fawọn eeyan:
Ọmọba Harry sọ pe ṣiṣe aanu fawọn eeyan ti oun ati aya rẹ jọ bẹrẹ niluu London ni oun si wa lori rẹ.
Lẹyin ọdun kan ti wọn ti fi ilu London silẹ lọ maa gbe ni ipinlẹ California lorilẹede Amẹrika, Harry ni oun ati Markle si n mu inu awọn eeyan dun naa ni.
2. Ọrọ ti ọmọba Archie kọkọ sọ:
Harry ṣalaye pe kii baba tabi mama ni ọrọ ti Archie kọkọ sọ.
Ọmọba Harry ni ọọni ni Archie kọkọ pe.
O ni ọmọ naa n dagba pẹlu abuda eeyan nla.

3. 'Haz ati Meg' orukọ adape tọkọtaya:
Harry tun sọ nipa orukọ adape ti oun ati Markle jọ n pe ara wọn.
O ni: 'Meg' to jẹ lẹta akọkọ ninu orukọ Meghan ni orukọ adape ti oun maa n pe Markle.
Bakan naa lo ṣalaye pe 'Haz' eleyi ti lẹta meji jẹyọ ninu orukọ Harry ni Markle maa n pe oun ni tirẹ.
- Ẹ má pa ìyàwó mi bí ẹ ṣé pa màmá mí-Prince Harry
- Ọmọọba Harry àti Meghan : Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọmọ ọba tí wọ́n fẹ́ bí
- Kíni Prince Harry, Meghan aya rẹ́ àti ọmọ wá ṣé ní Áfríkà?
- Ìgbéyàwó Harry àti Markle: Ohun tí ó yẹ kí o mọ̀
- Philip ẹni ọdún 99 tó jẹ́ ọkọ Ọbabìnrin Elizabeth ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn
- Obabinrin Elizabeth II ṣàfihàn àwòrán orí adé mẹ́ta tó lè jé lẹ́yìn rẹ̀
4. Harry ati Markle maa n wo ere idaraya lori bẹẹdi:
Harry ni lẹyin tawọn mejeeji ba ti ṣiṣẹ tan lati aarọ, ori bẹẹdi lawọn ti maa n wo ere idaraya tabi ere tiata.
Nibẹ naa ni awọn si ti n sinmi lẹyin iṣẹ.
5. Harry ko nija pẹlu ori-ade ilẹ Gẹẹsi:
Ọmọba Harry ṣalaye pe awọn akọroyin le maa kọ ohunkohun to wu wọn nipa oun, iyawo oun tabi idile oun lapapọ.
O ni oun ko ni ikunsinu tabi ija pẹlu ori ade rara.














