Bola Tinubu: BolaTinubu kò tíì rí ìwé ìpè gbà látọ̀dọ̀ EFCC lórí dúkìá rẹ̀

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Pm parrot

Tinubu ko ṣe nnkan etufu to lee maa kiyesi sẹyinkule si lori ọrọ ajọ EFCC ti wọn ni o fẹ wa gbe.

Ọrọ yii ni ọkan lara awọn itẹlẹ idi rẹ ti ko lee rii ti ṣalaye fun BBC News Yoruba nigba ti a pe lati beere ohun to bayiwa pẹlu iroyin to n kaakiri pe awsn oṣiṣẹ ajọ EFCC ti n gbradi lati fi panpaẹ ofin gbe agba oṣelu lẹgbẹ oṣelu APC naa.

Iroyin to n lọ kaakiri ni pe ajọ EFCC tun ti n gbero lati tun iwadii ṣe lori dukia agba oṣelu naa.

Ohun ti iroyin abẹle n sọ ni pe ajọ EFCC tun ti tun iwe kọ si ajọ to n ṣeto dukia awsn to dipo ilu mu, CCB pe ko fi iwe akọsilẹ dukia Asiwaju Bọla Tinubu ranṣẹ si wọn.

Ohun ti a gbọ lati igun oloye Tinubu ni pe iroyin to n lọ kaakiri naa ṣe awọn naa ni kayeefi nitori pe awọn gan ko tii ri iwe ipe tabi ohunkohun to jọ mọ ajọ EFCC gba.

Wọn ni ohun ti awọn eeyan n ri loju ewe iroyin lawọn naa n ri bayii.

Wọn ni ko tii si ẹnikẹni to kan si Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu lori ohunkohun latọdọ tabi nipa EFCC.