Sexual abuse: Ọkùnrin méjì dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tí wọ́n fipá bá ọmọ alábágbé wọn tó jẹ́ ẹni ọdún 16 lòpọ̀

cell

Oríṣun àwòrán, @princeiel

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi panpẹ ofin mu ọkunrin meji kan ti wọn fẹsun kan pe wọn gbimọ pọ lati fi ipa ba ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan to jẹ ọmọ alabagbe wọn lopọ.

Ọwọ tẹ awọn afurasi naa, Anthony John ati Jimoh Idowu lẹyin ti ọmọdebinrin ti wọn fi ipa balopọ fi ọrọ wọn lọ ni agọ ọlọpaa to wa ni Owode-Egba.

Ọmọ naa ṣalaye pe oun wa ninu ile pẹlu aburo oun ki awọn ọkunrin meji ọhun to fi ipa wọ oun lọ sinu yara Anthony, iyẹn ni nnkan bii aago meji oru.

O sọ siwaju si pe awọn ọkunrin ọhun mọ pe iya oun ti rinrinajo lo fun wọn ni igboya lati ja ilẹkun yara ti oun wa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni wọn fi aṣọ bo oun lẹnu ti wọn si ba oun ni ibalopọ leralera.

Àkọlé fídíò, Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn

Nigba ti ẹjọ na de iwaju DPO ọlọpaa to wa ni agbegbe Owode-Egba, Ediae Mathew, lọwọ kan naa lo fi awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣọwọ si ibi ti ile ti iṣẹlẹ naa ti ṣe, ti ọwọ si tẹ awọn afurasi ọhun.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo, awọn ọkunrin mejeji jẹwọ pe lootọ ni awọn ba ọmọ naa lopọ pẹlu ipa.

Àkọlé fídíò, Mother tongue day 2021, Akomolede, YSAN: A ti parí iṣẹ́ lórí èdè ìperí Meta-Language Yorùb

Awọn agbofinro ti gbe ọmọdebinrin naa lọ sile iwosa ijọba to wa ni Owode-Egba fun ayẹwọ ati itọju.

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajagun ti paṣẹ pe ki wọn gbe awọn afurasi mejeji lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si ọrọ awọn ọmọde fun ẹkunrẹrẹ iwadii ki wọn le foju bale ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Femi Falana, Endsars: Awolowo kò fáààyè gba kí èèyàn máa yàgò fún Màálù nígboro