Kagara school kidnap: Onímọ̀ tako Fayemi tó ní àfi kí ìjọba má báwọn jàndùkù ajínigbé sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Facebook/Sheikh Ahmad Gumi
Nibi ti ọrọ awọn janduku agbebọn to n ji awọn eeyan gbe kaakiri Naijiria de bayii, afaimọ ki awọn alaṣẹ ijọba ma ni ifọrọwerọ pẹlu awọn janduku ọhun.
Alaga ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria to tun jẹ gomina ipinlẹ Ekiti lo sọrọ yii nigba toun atawọn akẹgbẹ rẹ ṣabẹwo si Gomina Sani Bello ipinlẹ Niger lori iṣẹlẹ ijinigbe awọn akẹkọọ ileewe girama Kagara nipinlẹ naa.
Ọjọru ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun 2021 lawọn agbebọn yabo ile ẹkọ ọhun ni ijọba ibilẹ Rafi nibi ti wọn ti ji akẹkọọ mẹtadinlọgbọn ati oṣiṣẹ ile ẹkọ naa mẹẹdogun gbe lọ.
- Ó ti tó ọdún mẹ́fà, méje tí mo ti rí Àùntí Mide Funmi Martins gbẹ̀yìn, wọ́n tún ṣẹ̀ ń ṣèlérí - Damilare
- Kò tíì sí ọ̀rọ̀ ìyàwó báyìí o, kí n tó lè sọ̀rọ̀ pé mo fẹ́ gbé ìyàwó, màá ...- Oba Oloyede Akinghare II
- 'Torí Damilare, mo kara bọ agbo àwọn oní fíìmù, k'óun náà lè gòkè bíi Funmi Martins'
- Bí àsìkò ikú òṣèré Funmi, ìyá Mide Funmi Martins ṣe roo lágbo òṣèré nígbà náà nìyìí
- Àdó olóró ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí sekú pa èèyàn mẹ́wàá ní Maiduguri, ọ̀pọ̀ farapa yána yàna
- Èèyàn 170 ló kó coronavirus ní ìpínlẹ̀ Eko nìkan lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun
Ninu ọrọ rẹ, Fayemi pe fun ibaṣepọ to dan mọran laarin awọn oṣiṣẹ eleto abo lati le koju awọn ipenija eto abo ni Naijiria.
Gomina Fayemi sọ pe o sẹ pataki lati wa ọna miiran lati dẹkun iṣoro eto abo lorilẹede Naijiria yatọ si ohun tawọn ileeṣẹ ologun n ṣe.
O ni idi eyi lo fi ṣe pataki lati ba awọn janduku agbebọn sọrọ lati dẹkun ijinigbe.
Fayemi ṣalaye pe ina ti jo dori koko bayii lori ọrọ eto abo to mẹhẹ, eyi lo si fi ṣe pataki lati wa gbogbo ọna ti ''a le fi yanju iṣoro eto abo ni Naijiria.''
Gomina ipinlẹ Ekiti sọ pe biba awọn janduku agbebọn yii sọrọ wa lara awọn ọna lati wa ojutu si iṣoro eto abo.
O ni lẹyin naa, o tun ṣe koko lati ṣe iwadii lori ohun to ṣe okunfa iwa ọdaran ati ijinigbe to n ṣẹlẹ kaakiri bayii.
Gomina ipinlẹ Niger ki Fayemi ati awọn akẹgbẹ rẹ to ṣabẹwo si i, bakan naa lo sọ pe asiko ti to fun ijọba apapọ lati wa nkan ṣe si ọrọ eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.
Ṣugbọn onimọ nipa ọrọ eto abo, Ọgbẹni Richard Amuwa sọ fun BBC Yoruba pe igbesẹ lati ba awọn janduku agbebọn sọrọ buru jai.
O ni ti ijọba ba fi le ba awọn janduku ajinigbe sọrọ, eyi yoo fawọn iru janduku bẹẹ lati ṣẹyọ lawọn orilẹede Naijiria mii.
Ọgbẹni Amuwa sọ pe ọrọ eto abo ti di nkan mii ni Naijiria bayii nitori ko si ibi ti abo wa mọ ni Naijiria.
O ni ojutu si ọrọ abo to mẹhẹ ni ọlọpaa ipinlẹ, o ni ohun to yẹ ki awọn gomina maa ja fun ni eleyi kii ṣe ifọrọwerọ pẹlu awọn janduku.















