Lagos Kidnap: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí méjì tó nííṣe pẹ̀lú ìjínígbe Ọgá panápaná l'Eko

Oríṣun àwòrán, Lagos Police
Owo sinkun ofin ti mu awọn afurasi meji to nii ṣe pẹlu bi wọn ṣe ji adari ilé iṣẹ́ panápaná ipinlẹ̀ Eko, Rasaki Musibau atawọn mẹfa mii gbe.
Alukoro ile iṣẹ́ ọlọ́pàá, Bala Elkana sọ pe Blessing Bayo ati Smart Alfred lorukọ awọn afurasi ọun.
O ṣalaye wi pe iwadii si n lọ lọwọ lati mu awọn afurasi to ku ti wọn ṣiṣẹ laabi ọhun.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ilé iṣẹ́ ọlọpàádólàà adari ilé iṣẹ́ panápaná ipinlẹ̀ Eko
Ilé iṣẹ́ ọlọpàá ìpínlẹ̀ Eko ni àwọn ti dólàà adari ilé iṣẹ́ panápaná ipinlẹ̀ Eko, Rasaki Musibau.
Rasaki jẹ ọkan lara àwọn ti ajinígbé jígbé pẹ̀lú àwọn mẹ́fà míràn lọ́jọ́ kẹfà, oṣù yìí ní déédé ààgọ mẹ́jọ alẹ́ ní àgbègbè Kétu-Ereyun, Ikorodu.
Alukoro ile iṣẹ́ ọlọ́pàá, Bala Elkana nínú àtẹjade kan to fọwọ́si sàlàyé pe àwọn ajínígbe fi àwọn ènìyàn ọ̀hun silẹ̀ láì farapa.
O fí kún un pe gbogbo àwọn ti ọ̀rọ̀ náà kan ni wọn ti foju kan mọ̀lẹ́bi wọn láyọ àti alááfíà.
O ni pe àwọn igun kan nínú àwọn ọlọ́pàá to ń moju to ijinigbe ṣi wa nibi kọ́lọ́fin àti inu igbó níbi ti àwọn ọdàràn náà sápàmọ si láti ṣẹgun wọn.
Ajọ ọlọ́pàá fi kún un pé àtúnto to gbópọ̀n ni ọlọpàá tun ti se láti dènà irú ìṣẹ̀lẹ̀ yii lọ́jọ́ iwáju jákèjádò ìpínlẹ̀ Eko.
Bakan naa ni Ilé iṣẹ́ ọlọ́páà tún dupẹ́ lọ́wọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fún ìrànwọ àti gbogbo àrá ilú fún àwọn ìfitóniléti tí wọn ṣe to si ran àwọn lọ́wọ́ láti rí àwọn ènìyàn náà gba lọ́wọ́ àwọn ajínígbe.














