Osun Kidnap rescue: Àwọn ọlọ́pàá dóòlà ẹ̀mí arìnrìnàjò méje tí wọ́n jígbé ní Ibokun

Oríṣun àwòrán, AFP
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun ti kede pe awọn ti ribi doola arinrinajo meje lọwọ awọn ajinigbe.
Alukoro ileeṣẹ naa Yemisi Opalola lo lede ọrọ fun ileeṣẹ BBC ninu atẹjade kan lọjọ Abamẹta.
O ni awọn doola ẹmi awọn arinrinajo naa nipa ajọsepọ pẹlu awọn ẹsọ alaabo mii.
- Kò sí ǹkan tí a lè ṣe síi, àfi káwọn Fulani gbé ìbọn AK47- Gómìnà Ìpínlẹ̀ Bauchi
- Wọn yóò yẹgi fún àwọn ọmọ Nàìjíríà méjì lórí ikú ọmọbìnrin Takoradi tó dàwátì ní Ghana
- Buhari ni káwọn agbófinró ó yìnbọn fáwọn tó ń gbé ìbọn AK-47, àwọn ọmọ Nàìjíríà n pariwo "lórí irọ́"
- A ti rí Ọọ̀nì ''crocodile'' 27 nínú àwọn tó sálọ, àmọ́ a ṣì ń wá àwọn tó kù, ẹ̀yin ará ìlú, Ẹ ṣọ́ra!
Yemisi ṣalaye pe loju ọna Ibokun / Osogbo lawọn ajinigbe wọn yi ti jin awọn arinrinajo naa gbe lọjọ Iṣẹgun.
Lasiko ikọlu yi, a gbọ pe eeyan kan ku ti awọn meji si farapa lasiko ti awọn ajinigbe yi ṣe ikọlu si wọn labule Ajebandele ni ijọba ibilẹ Ibokun.
Agbofinro Yemisi ko sọ boya awọn ri awọn ajinigbe ọhun mu ṣugbọn o ni niṣe ni wọn tu awọn arinrinajo naa silẹ nigba ti awọn fungun mọ wọn.
O tẹsiwaju pe awọn ti wọn doola ko ni pẹ darapọ mọ mọlẹbi wọn.
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọlọ́mọ mẹ́jọ ká nítorí pé ọkọ rí àwọn òbí ìyàwó fín
- Ọpẹ́lọpẹ́ àjẹsára, ó yẹ kí n ti kú lẹ́yìn tí àwọn jàǹdúkú ṣá mi ní àdá - Oyinkansola Elebuibon
- Gbèdéke ẹ̀mí gígùn àwọn ọmọ Naijiria kò ju ọdún 54 lọ - Ẹgbẹ́ àwọn Dókítà
- Àwọn panápaná ti pa iná tó ṣẹ́yọ nídàjí òní nílé epo NNPC ní Akute nitòsí Berger báyìí









