Sasa crisis, MURIC: Ó yẹ kí ìjọba sanwó gbà mábínú fún darandaran àtàwọn àgbẹ̀ tó faragbá nínú rògbòdòdìyàn Sasa

Oríṣun àwòrán, Gertty
Ẹgbẹ ajafẹtọ awọn Musulumi, MURIC, ti rọ ijọpa apapọ lati fofin de awọn Fulani darandaran to n gbe ibọn Ak-47 rin laarin ilu.
Adari ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Ishaq Akintola lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi ṣowọ si awọn akọroyin lori rogbodiyan to waye laarin awọn ẹya Hausa ati Yoruba lagbegbe Sasa, niluu Ibadan.
MURIC sọ pe irufẹ ija bẹẹ kii ṣe ohun to bojumu ati pe ija ẹlẹyamẹya kii bimọ ire.
- Akẹ́kọ̀ọ́ 27, òṣìṣẹ́ méjì àti mọ̀lẹ́bí méjìlá ni àwọ́n agbébọn jí gbé ní ìpínlẹ̀ Niger
- Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano ṣèrànwọ́ ₦18.5m fún àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ rẹ̀ tó faragbá nínú rògbòdìyàn tó wáyé ní Sasa
- Kíní ìtumọ̀ àyájọ́ Ọ̀jọ ''Ash Wednesday' tó wáyé lóní?
- Wo àwọn ohun méje tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ngozi Okonjo-Iwealla àti ọkọ rẹ̀ Ikemba
Akintola rọ Aarẹ Muhammadu Buhari lori ọna to le gba lati dẹkun irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.
Lakọkọ, o ni o yẹ ki ijọba san owo gba mabinu fun gbogbo awọn agbẹ ti maluu ti jẹ nnkan ere oko wọn tabi ti wọn ba oko wọn kẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akintola sọ siwaju si pe o ye ki ijọba tun fun awọn Fulani to ba ni ẹri aridaju pe wọn padanu maluu wọn ninu iṣẹlẹ naa lowo to jọju.
- Wo ohun 10 tó yẹ́ kó mọ̀ nípà Ọ̀gà EFCC, Abdulrasheed Bawa tí ààrẹ̀ Buhari yàn
- Ọmọ Nàìjíríà Invictus Obinwanne Okeke rẹ́wọ̀n ọdún mẹwàá he l'Amerika lórí ẹ̀sùn jìbìtì $11m
- Ìrọ́ ní ò, a o fí ìgbà kankan fí Olupelumi Fagboyegun, Ìbátan Akeredolu sí ẹ̀wọ̀n- Iléẹ́jọ́ ìpínlẹ̀ Ondo
- Kílódé tí àwọn èèyàn ṣe ń gbé òkú pamọ̀ sílé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìlú yìí?
Ko tan sibẹ, Akintola tun rọ ijọba apapọ lati pese owo gọbọi fun awọn darandaran ki wọn le fi irufẹ owo bẹẹ kọ awọn ile ti awọn maluu naa yoo maa gbe.
O ni eyi yoo jẹ lọna ati pana ija laarin awọn agbẹ atawọn darandaran.
Atẹjade naa tẹsiwaju pe o yẹ ki ijọba apapọ fofin de bi awọn darandaran ṣe maa n ko maluu kiri laarin igboro.
Pe eyi yoo jẹ gẹgẹ bi ọna kan gboogi lati lati yanju ija lemọlemọ laarin awọn Fulani ọhun atawọn agbẹ ni Naijiria.
Akintola pari ọrọ rẹ pe o yẹ ki ile asọfin agba ṣe agbeyẹwo ofin to lodi si sisọ ọrọ ikorira lori ayelujara, o ni awọn ọrọ ikorira lo tunbọ da kun rogbodiyan to waye ni Sasa.
Lẹyin naa lo ke si ijọba ipinlẹ Oyo lati ṣe iwadii ohun to bi rogbodiyan naa, ko si fi gbogbo awọn ti aje ọrọ na ba ṣi mọ ori jofin.













