Ọyọ Kingship Tussle: Ìdí rè é tí adájọ́ fí yọ ọba bí jìgá ní ìlú Ọyọ́...

Oríṣun àwòrán, Google
Ileẹjọ giga nipinlẹ Oyo ti paṣẹ ki Alajaawa ti Ajaawa ni agbegbe Ogo-Oluwa, Oba Thompson Oyetunji lati kuro lori oye, ki o si sọra lati ma a farahan bii ọba ilu naa.
Bakan naa ni ileẹjọ naa paṣẹ fun gomina ati kọmisọnna fun ijọba ibilẹ lati gba sabuke rẹ pada.
Ileẹjọ ni sabuke naa tapa si aṣẹ ileẹjọ ti wọn da ni Ọjọ Kọkanla, Osu Kẹta, ọdun 2021.
Adajọ Sherifat Adeyemi to yọ ọba naa ni ilana ti wọn fi gbe ọba naa wọle ko ba ofin mu.
Wọn ni iwadii fihan pe ọba gbe igbeṣẹ naa pẹlu gomina tako aṣẹ ileẹjọ, nitori adajọ ko i ti dajọ lori ẹni ti ipo ọba naa tọsi.
Nibayii, ọba naa ti pasẹ fun Oyetunde lati sọra fun pipe ara rẹ ni ọba naa ni agbegbe ọhun titi ti idajọ yoo fi pari lori ọrọ ẹni ti ọba naa tọsi.
Adajọ fikun wi pe ko si aridaju pe awọn to pe ẹjọ ti ṣetan lati gba alaafia laaye lai lọ si ileẹjọ mọ.
- Mo ṣetán láti tún àwọn ilé tó jóná ní ọjà Shasha kọ́- Makinde
- Ọ̀gá àgbà ileeṣẹ ọlọpaa fi àwọn ọlọ́pàá kògbérégbè ṣowọ́ sí ìpińlẹ̀ Oyo lẹ́yìn rògbòdìyàn tó wáyé ní Sasa
- Àwọn darandaran gbẹ̀mí èèyàn mẹ́ta níjọba ìbílẹ̀ Ariwa Yewa lẹ́yìn àbẹ̀wò àwọn aṣojú ìjọba ní ìpínlẹ̀ Ogun
- Lọ́jọ́ Aje, ààrùn COVID-19 pa èèyàn mẹ́jọ ní Nàìjíríà
- Wọ́n ti kéde Ngozi Okonjo Iweala gẹ́gẹ́ bíi alákóso WTO
Bakan naa ni adajọ ọhun wa sun igbejọ naa di ọjọ Kẹrindinlogbọn, Oṣu Kẹrin, ọdun 2021.
Lara awọn ti wọn pe ẹjọ mọ ni Gomina ipinlẹ Oyo, Olotu eto idajọ nipinlẹ naa, kọmisọna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye, Ọmọọba Thompson Oyetunji, Oloye Adewale Erinle, Oloye Ademola Ishola, Oloye Adegbite Adeleke, Oloye Oyegoke Oyegbami, Oloye Oladele Akinbola ati ọmọọba Gideon Oyekunle.















