Shasha crisis in Ibadan:- Mi ò fẹ́ kí ẹ̀mí kankan ṣòfò mọ́- Makinde

Àkọlé fídíò, Sasa crisis in Ibadan: Ìbànújẹ́ ńlá ni ìṣẹ̀lẹ̀ Sasa jẹ́ fún mi - Makinde

Gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn tó wáyé ní Sasa ni yóò fojú winá òfin - Seyi Makinde

Ìbànújẹ́ ńlá ni ìṣẹ̀lẹ̀ Sasa jẹ́ fún mi ni koko ọrọ ti gomina Makinde ba awọn eeyan sọ.

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọ pe gbogbo awọ to lọwọ ninu rogbodiyan to waye lọja Sasa nipinlẹ naa ni yoo foju wina ofin laipẹ.

Makinde lo kede bẹẹ ninu fọran kan to fi lede loju opo Twitter rẹ, eyii to fi ba awọn eeyan ipinlẹ naa sọrọ.

O ni "mo ti paṣẹ pe ki wọn bẹrẹ iwadii lori ohun to fa ṣababi rogbodiyan naa, eyii to mu ẹmi awọn kan lọ."

Gomina ọhun sọ pe "mo ṣabẹwo si ọja Sasa ati Ojo ni ijọba ibilẹ Akinyele, mo si ri awọn ti ọrọ naa kan, o jẹ ohun to ba mi ninu jẹ gidi pe awọn eeyan kan ba iṣẹlẹ naa lọ."

Makinde

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde

"Ṣugbọn mo fẹ fi da yin loju pe, gbogbo ohun to yẹ ni a maa ṣe lori iṣẹlẹ naa, mo ti gbe iwadii dide lati mọ ohun to fa iṣẹlẹ naa, mo ṣi ṣeleri fun yin pe gbogbo awọn to lọwọ ninu rogbodoyan ọhun ni yoo foju wina ofin."

Makinde tẹsiwaju pe ijọba ohun yoo ṣe iranlọwọ fun gbogbo awọn to faragba ninu iṣẹlẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Ondo Fulani Herdsmen: Àgbe mẹ́ta ní àwọn Fulani darandaran tún pa Ọ̀wọ̀, Ondo

Bakan naa lo kilọ fun gbogbo awọn to n dana ogun ẹlẹyemẹya nipinlẹ Oyo lati ṣora ṣe.

Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ gbogbo awọn oṣiṣẹ eto abo fun akitiyan wọn lati mu ki alaafia jọba nipinlẹ naa.

Sasa

A san owó f'áwọn sọ́jà tó dóòlà ẹ̀mí wa ní Sasa ká tó sá àsálà- Oníṣòwò Hausa

Lati opin ọsẹ to kọja yii ni ija ti bẹ sile laarin awọn Yoruba ati Hausa ni ọja ata ti wọn n pe ni Sasa ni ilu Ibadan ni eyi to si ti bi iroyin lorisiirisi.

Akọwe ẹgbẹ awọn oniṣowo ni Sasa, ti wọn pe ni Sasa Traders Association, Ilyas Bala Muhammed ba BC sọrọ ni kikun lori iṣẹlẹ naa.

Iliyas ni pe ọpẹlọpẹ awọn ọmọ ogun ilẹ Naijiria ti wọn ni wọn gba owo lọwọ awọn lo ba awọn yanju eto aabowọn lati ribi salọ.

Iroyin ti gbogbo ero ọja sọ nipe awọn ṣọja pese iranlọwọ fun awọn oniṣowo Hausa lati ribi sa lọ ṣugbọn a ko le fidi ẹ mulẹ boya tootọ ni wọn gba owo naa tabi bẹẹ kọ.

Sasa

Ki lo ṣẹlẹ ni Sasa gangan lọjọbọ to kọja?

Akọwe ẹgbẹ oniṣowo Hausa ni Sasa, Iliyas ṣalaye fun BBC pe lootọ ni ọkunrin ọmọ Yoruba kan doloogbe ni ọja naa lọjọbọ.

O ni eyi waye lataari ede aiyede laarin ọmọ Yoruba kan ati ọmọ Hausa kan.

O ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ laari alaboyun ọmọ yoruba kan ati alagbase omọ Hausa kan ni eyi ti ọkunirn yoruba kan da si ọrọ naa pe ọrọ pẹlẹ ni ọrọ awọn alaboyun.

Ni eyi ti alagbaṣe ọmọ Hausa naa si di ija laarin awọn ọkunrin mejeeji.

Iliyas ni pe irọ ni pe ọmọ Hausa naa na ọmọ Yoruba ọhun loogun to fi ku.

Akọwe awọn Hausa oniṣowo naa ni tootọ ni ọkunrin Yoruba naa gbe ẹmi mi lẹyin o rẹyin lẹyin ti wọn gbe e lọ sile iwosan fun itọju.

Bala Muhammed bu ẹnu atẹ lu awọn agbofinro ati awọn oṣiṣẹ eleto aabo pe wọn ko pese aabo to peye nigba ti ọrọ daru tan.

O ni niṣe ni awọn eleto aabo n woran laida si iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni Bala tun fẹsun kan ijọba pe wọn ko tete dide si iṣẹlẹ naa bi o ti yẹ ni oju tirẹ.

Ọpọlọpọ ile, ṣọọbu ati ọja ni wọn dan a sun ninu ọja Sasa.

Awọn oniṣowo Yoruba ati ti Hausa naa lo si ti n ka iye adanu ti wọn ṣofo rẹ.

Àkọlé fídíò, Lori iro: Ká ni àwọn Òbí mi gbà fún mí, èmi àti Sunny Ade á jọ máa 'Compete- Baba Lórí ir

Kini o n ṣẹlẹ ni Sasa bayii?

Bayii ti ikọ BBC de si Sasa ni a ri i pe ohun gbogbo ti wa ni irọwọrọsẹ.

Bẹẹ la tun ri awọn oṣiṣẹ eleto aabo pọ nibẹ loni ọjọ Aje ti a kan sibẹ.

Gomina Seyi Makinde ti pe fun alaafia o si ti fi ofin konile-o-gbele sibẹ.