Borno Dr Isa Akinbode: Gómìnà Zulum ti Borno fún Dókítà Akinbode ní àmì ẹ̀yẹ fún ìṣẹ́ takuntakun ní iléèwòsàn ìjọba

Borno

Oríṣun àwòrán, Borno State Government

Gomina ipinlẹ Borno, Ọjọgbọn Babagana Umara Zulum ti fi ọkọ tuntun ati iye owo to le ni miliọnu mẹtala da dokita Isa Akinbode lọla.

Gomina Zulum dupẹ lọwọ rẹ fun iṣẹ takuntakun to ṣe nigba to wa ni ẹnu iṣẹ ijọba gẹgẹ bi dokita.

O ni ọpọlọpọ awọn eniyan lo sa kuro ni agbegbe Mongono lasiko ikọlu ikọ Boko Haram si agbegbe naa, amọ dokita naa duro digbidigbi.

Dokita Isa Akinbode si pẹlu awọn eniyan ti ikọ Boko Haram ji gbe, amọ ti wọn fi silẹ.

Ọdun mejilelogun ni Dokita Akinbode fi ṣiṣẹ ni ileewosan gbogboogbo ti Mongono, nipinlẹ Borno.

Borno

Oríṣun àwòrán, Borno state Government

Gomina ipinlẹ Borno ni o ṣe pataki ki awọn da dokita naa lọl nitori o sin araalu ati orilẹede rẹ pẹlu gbogbo ipa rẹ.

Bakan naa ni wọn fun ọmọbinrin Dokita Akinbode ni iṣẹ lẹṣẹkẹsẹ, ti wọn si tun ṣeleri lati san owo oṣu fun dokita naa fun gbogbo ọdun to fi ṣiṣẹ ijọba pẹlu ajẹmọnu rẹ.

Gomina ọhun rọ awọn ọmọ Dokita Akinbode lati tọju baba wọn nitori alaanu eniyan lojẹ ni gbogbo ọjọ to fi ṣiṣẹ.

Borno

Oríṣun àwòrán, Borno State Government

Dokita Akinbode lo wa lati ipinlẹ Ogun, amọ o lọ si fasiti ipinlẹ Maiduguri to si durọ si ipinlẹ ọhun lati igba naa titi ti o fi fẹyinti lẹyin ọdun mejilelogun.

Borno

Oríṣun àwòrán, Borno State Government

Ikọ Boko Haram ti wa nipinlẹ Borno lati bi ọdun mẹwaa ṣẹyin, ti wọn si ti fi ọpọlọpọ ẹmi ṣofo lati igba ti wọn ti n ṣe ikọlu si agbegbe naa.

Àkọlé fídíò, Bí àlááfíà yóò ṣe wà láàrin Fulani àti Yorùbá ni Ooni bá lọ sọ́dọ̀ Buhari- Ààfin Ile Ife