Fuel price in Nigeria: Kò sí òótọ́ kankan nínú ìkéde pé ìjọba Naijiria fẹ́ fi kún owó epo - Mísísítà

Queue
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Minisita abẹle fun ọrọ epo bẹntiro, Timipre Sylva ti tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria fun idamu to ba wọn lẹyin ti ijọba apapọ kede afikun owo epo bẹntiro.

Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin, Sylva ṣalaye pe oun tabi Aarẹ Muhammadu Buhari ko buwọlu ₦212 gẹgẹ bii afikun owo epo tuntun.

O ni "bo tilẹ jẹ pe ikede naa wa lati ọdọ ajọ to n ṣoju ijọba apapọ, mo fẹ fi da yin loju pe ko si ootọ kankan ninu ikede ọhun."

"Gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ, o ti to ọjọ mẹta kan ti ijọba ti n ṣe ipade pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lori ọna abayọ si epo rọbi to gbowo lori lagbaye, ko ṣeeṣẹ ki a da ajọsọ wa nu lasiko yii lọna ati ṣe afikun owo epo."

Ṣaaju ni ajọ to n ṣakoso iye owo epo bẹntiro ni Naijiria, PPPRA, ti kọkọ kede afikun naa lorumọju ọjọ Ẹti, pe owo epo tuntunti di ₦212.

Ikede naa yọri si oriṣiriṣi awuyewuye, lẹyin ti ọpọ ọmọ Naijiria ni afikun ọhun yoo mu inira ba ọpọ eeyan.

Afi to ya ti ileeṣẹ ipọnpo NNPC naa tun fi atẹjade tiwọn sita pe irọ ni, ko si igbesẹ kankan lati fi owo kun owo epo bẹntiroo.

Lẹyin ikede NNPC yii ni PPPRA fa atẹjade afikun owo epo naa kuro loju opo ileeṣẹ wọn ni http://pppra.gov.ng/pms-guiding-price-for-march-2021.

Ṣé òótọ́ ni pé owó epo bẹntiró ti di ₦212.61 ní Naijiria àbí ìjọba yí ẹnu padà?

Epo Bẹntirol

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ṣe lawọn ọmọ Naijiria faraya lẹ́yìn tí ìjọba àpapọ̀ kéde ₦212.61 gẹ́gẹ́ bíi owó epo bẹntiró tuntun

Iroyin ti ọpọ ọmọ Naijiria ji ri ni afẹmọju ọjọ Ẹti ni pe ijọba apapọ ti fi owo le owo epo bẹntiro.

Gẹgẹ bii iroyin naa ṣe sọ, iye ti wọn yoo maa ta epo bẹntiro ti di ₦212.61.

Ṣaaju ni ajọ to n ṣakoso iye owo epo bẹntiro ni Naijiria, PPPRA, ti kọkọ kede afikun naa lorumọju.

Àkọlé fídíò, Mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ jijà ní ọmọ ọdún méjì, inú mi dùn pé bàbá mi fi mí sí ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ jíjà - Tijani Azeez

Afi to ya ni ileeṣẹ ipọnpo NNPC fi atẹjade sita pe irọ ni, ko si igbesẹ kankan lati fi owo kun owo epo bẹntiroo.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bo tilẹ jẹ pe ajọ to n bojuto ọrọ epo bẹntiro ni Naijiria, NNPC, ti kọkọ fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ko ni si afikun owo epo ninu oṣu Kẹta ti a wa yii, ikede ti PPPRA ṣe jẹ eyii ti ko dun mọ ọpọ ọmọ Naijiria ninu.

Bi awọn kan ṣe n naka abuku si ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari lori ikede naa, lawọn mii n bu ẹtẹ lu ajọ NNPC ati PPPRA, koda awọn miii tilẹ ti n mura ifẹhonuhan.

Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun ọpọ ara ilu nitori lẹyin wakati diẹ ti iroyin naa jade ni PPPRA tun pohunda.

Kii ṣe pe PPPRA kede iye owo tuntun miran fun epo bẹntiro, ṣugbọn wọn yọ atẹjade akọkọ ti wọn fi kede iye owo tuntun ọhun kuro loju opo ileeṣẹ wọn.

Àkọlé fídíò, Wo obìnrin kanṣoso láàrin àwọ́n ọkunrin agunẹṣin gbafẹ́ nílùú Ilorin àmọ́ tọ́kàn rẹ̀ yii

Igbesẹ tuntun ti wọn gbe yii ti wa mu ki ọpọ eeyan maa woye ohun gan to n ṣẹlẹ ni pato lori ọrọ owo epo bẹntiro ni Naijiria.

Ẹwẹ, ọpọ ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori ọrọ naa lori ayelujara.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe o ṣeeṣe ki ijọba yi ero rẹ pada lori afikun owo epo bẹntiro, lawọn mii n sọ pe ijọba yoo pada ṣafikun owo ọhun bopẹ boya.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ipari ọdun to kọja ni ijọba apapọ ṣe afikun owo ina mọnamọna, igbesẹ eyii ti ko dun mọ ọpọ ara ilu ninu.