Ohun mẹ́ta tó yípadà nílẹ̀ Niger lẹ́yìn ọdún kan tí ológun dìtẹ̀ gbàjọba
Ni osu kẹfa fun 2023 ni rogbodiyan gbode ni orilẹede Niger nigba ti awọn ologun gba ijọba eyi ti ọgagun Abdourahamane Tchiani lewaju rẹ.
Koko ohun ti awọn ologun yii sọ pe o mu ki awọn gbe igbesẹ iditẹ gba ijọba naa ni lati mu ayipada rere ba orilẹede naa.
Amọ nibayii to pe ọdun kan ti awọn ologun ti ditẹ gba ijọba lorilẹede Niger, awọn ayipada rere wo lo ti waye ni orilẹede naa?
Ninu iwadi BBC, a se akiyesi awọn ayipada mẹta gboogi to waye lorilẹede naa bẹrẹ lati dun to kọja ti awọn ologun ti gba ijọba

Ayipada mẹta to waye lorilẹede Niger lẹyin dun kan ti ikọ ologun ditẹ gba ijọba
Lile awọn ologun to wa lati oke okun lọ
Akọkọ ayipada to waye lẹyin tawọn ologun ditẹ gba ijọba lorilẹede Niger ni bawọn ologun naa se juwe ọna ile fun awọn ologun ọmọ ilẹ okeere to tẹdo silu naa.
Ikọ ologun lati ilẹ Faranse ati ajọ isọkan ilẹ Yuroopu, EU ni wọn le kuro ni orilẹede Niger.
Leyin naa ni awọn ologun to wa lati ilẹ Amẹrika ti wọn n gbero bayii lati kuro nilẹ Niger.
Saaju ete iditẹ gbajọba naa, orilẹede Niger lo jẹ alajọsepọ awọn orilẹede alagbara lagbaye.
Idi si ree ti awọn orilẹede alagbara naa se tẹdo si ilẹ naa lati maa kọju oro sawọn ikọ alakatakiti agbesunmọmi.
Ijọba ilẹ Amẹrika nikan ti kọ ibudo ologun ti owo rẹ le ni gọrun miliọnu Dọla.
Amọ ni bayii, awọn orilẹede alagbara lagbaye wo wa ni ọrẹ ilẹ Niger?
Orilẹede Russia ati Turkey si ni ọrẹ ilẹ Niger bayii.
Eto ọrọ aje ilẹ Niger ti n gbera sọ bayii, ti ilẹ Turkey si sẹsẹ tọwọ bọ iwe adehun pẹlu Niger fun eto iwakusa.
Kiko eeyan wọle
Ayipada keji to tun ba orilẹede Niger lẹyin tawọn ologun ditẹ gba ijọba ni fifi aaye gba kiko eeyan wọle.
Ni ọdun mẹjọ sẹyin, ajọ EU jẹ ki Niger buwọlu ofin to tako kiko eeyan wọle si orilẹede naa amọ nibayii, wọn ti wgile ofin naa.
Gẹgẹ bi ajọ isọkan agbaye, UN ti wi, afikun ida aadọta ti ba iye eeyan to n gba ẹnu bode Niger wọle si orilẹede naa.

Oríṣun àwòrán, ORTN
Kikuro ninu ajọ ECOWAS
Ayipada kẹta to tun ba orilẹede Niger lẹyin tawọn ologun ditẹ gba ijọba ni bi orilẹede naa se kuro ninu ajọ to wa fun ifọwọsowọpọ okoowo laarin awọn orilẹede to wa lẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika (ECOWAS)
Laipẹ yii ni orilẹede Niger pẹlu Mali ati Burkina Faso kuro ninu ajọ ECOWAS, ti wọn si ni awọn ijọba orilẹede kan loke okun lo n se akoso ajọ naa.
Awọn orilẹede mẹtẹẹta yii ti wa se ẹda ajọ isọkan tiwọn ti orukọ rẹ n jẹ ‘The Alliance of Sahel States’
Ki ni ọjọ ọla to n bọ yoo ni fun orilẹede Niger?
Ọna ibi ti ijọba Niger dojukọ ni ko ye ọpọ eeyan, ti ọpọ ọmọ orilẹede naa si n beere pe kawọn ologun to ditẹ gba ijọba gbe ijọba kalẹ fawọn alagbada.
Amọ awọn ologun naa ni awọn yoo nilo to ọdun mẹta lati mu ayipada rere ba orilẹede naa, ki awọn to gbe ijọba silẹ.
Ki wa lẹ ro pe ọjọ ọla to n bọ yoo ni fun orilẹede Niger?






