Níbo ni nnkan dé dúró ní Niger lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba? Nnkan tí a mọ̀ rèé

Ileeṣẹ ijọba to wa fun ọrọ abẹle ni Niger, ti fofin de iwọde lẹyin ti awọn alatilẹyin iditẹgbajọba naa dana sun olu ile ẹgbẹ oṣelu to n ṣe ijọba lọwọ, ti wọn si ba ọpọlọpọ dukia.
Ọjọ Iṣẹgun ni awọn ologun kede pe awọn ti gba ijọba.
Niṣe ni wọn dana sun ile ẹgbẹ oṣelu naa, ti wọn si tun fi okuta ati iná ba awọn ọkọ̀ ti wọn gbe si ita ibẹ jẹ́.
Yatọ si eyi, awọn kan lara awọn oluwọde naa to korajọ pọ siwaju ile aṣofin ta awọn asia orilẹ-ede Russia, ti awọn kan si gbe akọle dani pe awọn ko ṣe ti France mọ́.
Ninu atẹjade kan, ileeṣẹ ijọba naa sọ pe oun ko ni fi aaye gba ki ẹnikẹni fi nnkan ìní ijọba ṣofo, ati pe wọn o fi iya jẹ ẹnikẹni ti ọwọ́ ba tẹ.
United Nations da eto iranwọ duro ni Niger
Ajọ United Nations sọ pe oun ti da eto iranlọwọ duro ni Niger, lẹyin ọjọ meji ti awọn ologun kede iditẹgbajọba ni orilẹ-ede naa.
UN sọ pe o le ni miliọnu mẹrin eeyan ti nilo iranlọwọ pajawiri ni Niger. Amọ ko daju boya nitori iditẹgbajọba to waye lo fa idaduro naa.
Bakan naa ni Akọwe Agba ajọ naa, Antonio Guterres pè fun itusilẹ Aarẹ Mohamed Bazoum, ti awọn ologun fi si ahamọ wọn.
Aarẹ Mohamed Bazoum wa ni alaafia
Ninu iroyin mii, orilẹ-ede France ti sọ pe Aarẹ Mohamed Bazoum wa ni ilera pipe.
Minisita fun ọrọ ilẹ okeere, Catherine Colonna sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe iditẹgbajọba naa kii ṣe “opin”.
O ni Ọgbẹni Bazoum ti ba Aarẹ Emmanuel Macron sọrọ, o si fi kun un pe “ọna abayọ” wa fun awọn to ditẹ gba ijọba, ti wọn ba fi gbọ nnkan ti awujọ agbaye n sọ.
Lọwọlọwọ, a ko tii le sọ ẹni to n dari orilẹ-ede Niger, nitori pe awọn to kede iditẹgbajọba naa ko tii kede adari wọn.
Niluu Niamey, to jẹ olu ilu Niger, ṣiṣi ni awọn ile itaja ati ọja wa.












