Ìjì líle Typhoon Gaemi kọlu China, èèyàn 150,000 fi ilé wọn sílẹ̀

Typhoon Gaemi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iji lile Typhoon Gaemi ti kọlu orilẹede China lẹyin to ti kọkọ ṣọṣẹ ni Taiwan ati Philippines.

Awọn eeyan to le ni 150,000 lagbegbe ila oorun China ni ijọba ti ko lọ sagbegbe Fujian lasiko ti wọn n reti iji ọhun.

Iji lile naa lo waye lẹyin iṣẹlẹ omiyale ati ilẹ yiyọ to ṣọṣẹ ni Taiwan ati Philippines, ninu eyii ti ẹmi eeyan mọkanlelogun ti sọnu.

Ni Philippines, ijọba ni oun n sare tete lati palẹmọ epo bẹntiro ti miliọnu kan abọ lita rẹ danu sori omi.

Ọkọ oju omi to gbe epo wa lara meji to ri sinu omi labegbe naa lọjọbọ.

Ṣaaju ni China ti kọkọ lede fun awọn eeyan rẹ pe ki wọn maa mura fun iji lile to n bọ lọna lalẹ Ọjọbọ.

Aarẹ Xi Jinping ti ṣe ipade pajawiri pẹlu awọn ti yoo koju iji lile naa ti won yo si dabo bo araalu.

Ijọba ti dawọ irinajo oju irin duro ni Fujian, o si tun ti kede pe awọn ojo to n bọ laipẹ le yọri si omiyale ati ilẹ yiyọ.

Segesege ni oju ọjọ n ṣe lọwọ yii ni China ti ojo ti maa n rọ laarin oṣu Keje si aarin oṣu Kẹjọ ọdun.

Ojo arọrọda lo n rọ ni ila oorun ati guusu, nigba ti oru amuju n ba wọn finra ni ariwa.

Lọwọ yii ni Taiwan, ijọba ti n fọ epo to da sori omi lẹyin iji lile to waye nibẹ.