Wo kókó pàtàkì nípa ìgbé ayé Emmanuel Iwuanyanwu, ààrẹ ẹgbẹ́ Ohaneze Ndigbo ní àgbáyé tó kú

Emmanuel Iwuanyanwu

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ni irọlẹ ọjọbọ ni iroyin gbalẹ kan pe aarẹ ẹgbẹ apapọ awọn ọmọ bibi ilẹ Igbo, Ohaneze Ndigbo, Emmanuel Iwuanyanwu, ti jade laye.

Ẹni ọdun mejilelọgrin ni oloogbe naa, nigba to fi papoda.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ Ohaneze Ndigbo, Alex Ogbonna lo si fidi iku Iwuanyanwu mulẹ fun BBC lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ.

Bakan naa lo fikun pe lati ile iwosan ni oloogbe naa gba lọ sile, sọdọ awọn ẹbi rẹ.

Bakan naa, ọmọkunrin fun oloogbe ọhun, Jide Iwuanyanwu, naa fi ikede miran sita pe baba oun ti jade laye lasiko aisan ranpẹ ni Ọjọbọ.

Jide ni “A maa kede eto isinku lọjọ iwaju lẹyin ti a ba ti fi isẹlẹ naa to gbogbo ẹbi leti.”

Ki ni awọn koko pataki nipa igbe aye Emmanuel Iwuanyanwu?

  • Iwuanyanwu dele aye ninu osu Kẹsan ọdun 1942 nilu Atta to wa labẹ ijọba ibilẹ Ikeduru nipinlẹ Imo
  • O kawe alakọbẹrẹ ati girama, ko to kọja l si fasiti ilẹ wa to wa nilu Nsukka lati kẹkọ gboye nipa imọ ẹrọ, Civil Engineering
  • Lẹyin naa lo wa sisẹ nileesẹ abanikle Hardel ati Erics amọ to pada ra ileesẹ naa lọwọ awọn ọmọ ilẹ okeere to da ileesẹ naa silẹ
  • Oloselu ati olookowo to gbajumọ ni a mọ Emmanuel Iwuanyanwu si yika orilẹede yii ati kaakiri agbaye
  • Ololufẹ ere idaraya si tun ni oloogbe naa, to si da ẹgbẹ agbabọọlu Nationale tilu Owerri silẹ eyi to pada di ẹgbẹ agbabọọlu Heartland bayii
  • Orukọ aya akọfẹ rẹ ni Eudora Ozinyereaku Anyanwu, ẹni to ti jẹ Ọlọrun nipa, to si bi ọmọ mẹjọ, ọkunrin mẹta ati obinrin marun
  • Lẹyin eyi ni Iwuanyanwu tun fẹ Frances, ti wọn si bi ọpọ ọmọ ati ọmọ-ọmọ pupọ.
  • Lara ọmọ Iwuanyanwu to gbajumọ ni Nwadiuto Iheakanwa to jẹ oludari iwe iroin Champion
  • Iwuanyanwu si ni alaga fun apapọ ẹgbẹ awọn agbaagba ninu ẹgbẹ ọmọ bibi ilẹ Igbo, Ohaneze Ndigbo, ki wọn to wa yan ni aarẹ ẹgbẹ naa kaakiri agbaye.
  • Ọgbọnjọ osu kẹrin ọdun 2023 to kọja si ni ikọ awọn agbaagba ninu ẹgbẹ naa yan sipo aarẹ apapọ ẹgbẹ lẹyin ti aarẹ ẹgbẹ naa tẹlẹ, George Obiozor ku ldun 2022.