Wo àwọn èèkàn ilẹ̀ Áfíríkà tó ń kópa nínú ìdíje Olympic

Àkọlé fídíò, Wo àwọn èèkàn ilé Áfíríkà tó ń kópa nínú ìdíje Olympic
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Idije Olympics ti gbera sọ bayii niluu Paris ni orilẹede France to si jẹ pe ọpọ ọmọ ilẹ Afrika ni yoo kopa ninu idije naa.

BBC se afihan awọn eekan ilẹ Afrika to ọpọ n foju si lara pe wọn yoo gbe oga ilẹ sita fun gbogbo agbaye.

Ti a ba si n sọrọ nipa awọn elere idaraya to fi itan lẹlẹ, ọpọ wọn lo wa lati ilẹ Afrika.

Ẹ wo fọnran yii lati mọ nipa awọn eekan elere idaraya to wa lati ilẹ Afrika.

Gbọngan mẹẹdogun ni idije Olympics yoo ti waye.

Papa iṣere Stade de France ni yoo gbalejo awọn oniruuru ere sisa ati awọn ere idaraya mii.

Ilu mẹfa kaakiri awọn ẹkun to wa ni France ni ere bọọlu yoo ti waye.

Ilu Marseille to wa ni bebe okun ni ere idaraya ọkọ oju omi yoo ti maa waye.

Teahupo'o ni Tahiti ni awọn to n lefo lori omi to n ru yoo ti ṣe ere idaraya ti wọn.

Aworan idije Olympic France

Oríṣun àwòrán, Getty Images