Ògbóǹtarìgì oníṣòwò oògùn olóro tó làmìlaaka jùlọ lágbàáyé ti dèrò àhámọ́

Oríṣun àwòrán, REUTERS/DEA
Ọwọ ofin ti tẹ ogbontarigi oniṣowo oogun oloro lagbaaye ni El Paso, nipinlẹ Texas lorilẹede Amẹrika.
Ismael 'El Mayo' Zambada, pẹlu akẹgbẹ rẹ, El Chapo Guzman ni wọn ti n wa tipẹ tori wọn da ẹgbẹ to n gbe oogun oloro Sinaloa silẹ lorilẹede Mexico.
'El Mayo' Zambada jẹ ologun oloro to gbajugbaja julọ lagbaaye, oun naa si ni afurasi ọdaran ti wọn n wa julọ lẹkun Ariwa ati Guusu Amẹrika.
Ijọba orilẹede Amẹrika ti gbe $15m silẹ fun ẹnikẹni to ba ri ogbontarigi oniṣowo oogun oloro yii tipẹ.
Amọ, o ti pe ọdun mẹwaa ti El Mayo ti n sa fun awọn alaṣẹ ijọba Amẹrika.
Eyii gan na lo jẹ ki iroyin wi pe ọwọ ofin ti tẹ ẹ jẹ iyanlẹnu fun ọpọ eeyan lorilẹede Mexico.
Aṣeyọri nla ni eyi jẹ fawọn ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti oogun oloro ni Amẹrika jẹ.
Iroyin tun fidi rẹ mulẹ pe El Mayo ati ọmọkunrin rẹ ni wọn jọ mu papọ.
Joaquin 'El Chapo' Guzman toun naa jẹ gbajugbaja lagbo oogun oloro tita naa ti dero ẹwọn.
Iroyin ko le sọ ni pato ibi ti wọn wa bayii gan an, ṣugbọn ohun ti a mọ ni pe orilẹede Amẹrika naa wọn wa.
Bi ọrọ ṣe n lọ lori bi ọwọ ṣe tẹ awọn ogbontarigi oniṣowo oogun oloro mejeeji yii, ko si ani-ani nibi wi pe aṣeyọri nla ni eyi jẹ fun ajọ to n gbogun ti oogun oloro labẹ aṣẹ ijọba Aarẹ Joe Biden to n palẹmọ lati kogba wọle lorilẹede Amẹrika.
Awọn mejeeji yoo foju ba ile ẹjọ lori ẹsun ṣiṣe kara-kata oogun oloro, kiko owo lọ pamọ silu okeere ati ẹsun to ni ṣe iwa ipa tori oogun oloro l’Amẹrika.















