Wo ewu tuntun tí Niger ń kojú báyìí lẹ́yìn ọdún kan táwọn ológun dìtẹ̀ gbàjọba níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, FPL
- Author, Azeezat Olaoluwa & Chris Ewokor
- Role, BBC Senior Journalist Reporters
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
O ti pe ọdun bayii tawọn ologun ditẹ gbajọba lọwọ aarẹ orilẹede Niger, Mohamed Bazoum.
Lati igba naa ni aarẹ Bazoum ti wọn doju ijọba rẹ bolẹ ati iyawo rẹ ti wa lahamọ awọn ologun.
Ninu ibẹru-bojo ni Bazoum wa bayii tori o ṣee ṣe ki wọn fẹsun iditẹmọ ijọba kan an eyi to le ja si idajọ iku fun un.
Agbẹjọro aarẹ ana ọhun, Moussa Coulibaly, sọ fun BBC pe ile ẹjọ ti yoo ṣe idajọ Bazoum kii ṣe ile ẹjọ to daduro ti kii ṣegbe lẹyin ẹnikan.
Coulibaly ni ko si ohun to jọ titẹ le ofin mọ lorilẹede Niger lọwọ yii.
Ijọba ologun labẹ alaṣẹ Ọgagun Abdourahamane Tchiani ṣeleri lati wa ojutuu si eto abo to mẹhẹ, ṣe atunṣe ọrọ-aje to dẹnukọlẹ ati lati mu aye dẹrun fun araalu nigba ti wọn gbajọba.
Olori iditẹgbajọba ọhun kọ ẹyin sawọn ọmogun ilẹ okeere lati ilẹ Yuroopu ati Amẹrika.
Amọ, o ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu orilẹede Russia, Turkey ati Iran.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọgọọrọ eeyan ko ara wọn jọ loju popo ti wọn n yọ lẹyin tawọn ologun gbajọba ni Niger.
Rabiou Hassane to jẹ adari ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni Niger sọ pe igbe aye ti rọrun sii fun araalu lati igba ti awọn ologun ti gbajọba.
Olori ẹgbẹ awọn agbẹ naa, Djibo Bagna, sọ pe ijọba ologun ti ṣe daadaa, wọn si ti ṣe itọju awọn ohun alumọni orilẹede Niger daadaa.
Amọ, ohun to daju ni pe orilẹede Niger ṣi n koju oriṣiiriṣii iṣoro.
Gẹgẹ bi ajọ oluwadii kan ni Afirika ṣe sọ, iditẹgbajọba oṣu Keje ọdun 2023 ti mu ki eto abo mẹhẹ sii nigba ti eto ọrọ-aje naa si tun ti dẹnukọlẹ sii.
Bakan naa ni ibasẹpọ Niger pẹlu awọn orilẹede to yi i ka ko dan mọran mọ bii ti tẹlẹ.
Orilẹede Mali ati Burkina Faso ni ijọba ologun Niger n ba ṣọọrẹ bayii.
Bakan naa ni Niger ti n koju iṣoro igbesunmọmi ti o ni ṣe pẹlu ẹgbẹ ẹlẹsin alakatakiti Islam al-Qaeda ati IS fun bi ọdun mẹwaa bayii eyi to ti ṣekupa ẹgbẹẹgbẹrun eeyan ti o si tun ti sọ ọpọ ọmọ Niger di alainile lori mọ.
Ijọba ologun ko tii ṣe aṣeyọri gidi nipa awọn agbesunmọmi to n yọ Niger lẹnu yii, bo tilẹ jẹ wọn ṣeleri lati wa ojutuu si iṣoro naa.
Koda, ọpọ ọmogun Niger lawọn agbesunmọmi yii ti ṣekupa.
Mohamed Seydou to jẹ oniṣowo ni Tillabery sọ fun BBC pe awọn agbẹ o le lọ soko mọ tori awọn agbesunmọmi.
Yacouba Karaou to n ṣe ọsin ẹran sọ pe lojoojumọ lawọn janduku agbebọn n yọ awọn lẹnu.
Awọn ọta tuntun
Awọn ewu tuntun lo tun ti ṣuyọ fun ijọba ologun orilẹede Niger.
Ẹgbẹ FPL to jẹ alatako ijọba ologun to wa lode ni Niger, n beere fun idapada Bazoum, ti n ṣekọlu sawọn ọmogun atawọn nnka amayedẹrun to fi mọ ọpa ẹpo rọbi.
Adari ẹgbẹ FPL, Mahamoud Sallah, ni iditẹgbajọba to waye ni Niger ti mu ifasẹyin ba orilẹede Niger.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
''A n pe fun ki Tchiani olori awọn ologun da ijọba pada fun Bazoum, ati pe aṣiṣe ni fifi ajọ Ecowas silẹ lati lọ maa dọrẹẹ pẹlu Mali ati Burkina Faso.
A ṣetan lati gba orilẹede wa pada lai bẹru.
Biba ọpa epo rọbi jẹ nnkan to buru jai fun NIger tori ijọba fẹ maa ta epo rọbi bii iwọn 90,000 barẹẹli lojumọ silẹ okeere lati le san $400m ti wọn ya lọwọ China pada.
Aawọ to n lọ lọwọ laarin ilu Niamey ati orilẹede Benin naa tun n ṣakoba fun ati maa gbe epo rọbi Niger lọ silẹ okeere.

Oríṣun àwòrán, BBC News
Bi ijọba Benin ṣe ti ibode orilẹede naa pa ti ṣakoba nla fun eto ọrọ-aje niluu Malanville debi wi pe ọpọ lo ti fi ilu naa silẹ lọ ibomiran.
Namata Sanda, to n ṣiṣẹ agbẹ ṣalaye pe bi ijọba Benin ṣe ti ibode ti ṣakoba foun.
O ni owo ti oun n ri loṣu lati igba ti ijọba ti gbe bode tipa ti ja walẹ lati $2,000 si $330.
Sanda ni nnkan n fararọ foun ati idile oun.
Ali Muhammed to n ti n ṣowo aṣọ fun bii ọgbọn ọdun ni ọrọ-aje ti dẹnukọlẹ.
Muhammed ni awọn eeyan Niger lo pọ ninu awọn onibara awọn, ṣugbọn wọn o le wa mọ lẹyin ti ijọba gbe ibode tipa.
O ni ọpọ oniṣowo lo ti jẹ gbese bayii tori ọrọ-aye ti ko lọ daadaa mọ.















