Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Eyi ni akojọpọ awọn ohun to n ṣẹlẹ to tayọ kaakiri agbaye.
Ijọba atawọn eekan ni Naijiria ti ke si awọn araalu lati ṣe suuru nitoru iṣẹ n lọwọ lati mayedẹrun fun gbogbo mutumuwa.
Arọwa yii lo n waye latari iwọde to n bọ loṣu to n bọ, eyii ti wọn yoo mi gbogbo Naijiria titi.
Ijọba ni kii ṣe iwọde ni ọrọ Naijiri kan lọwọ yii, bii ko ṣe ki gbogbo araalu ṣatilẹyin fun oun.
Ẹwẹ, awọn ẹgbẹ kan ti sọ pe awọn ko ni darapọ mọ iwọde naa
Eeyan meji ti padanu ẹmi wọn lẹyin rogbodiyan to bẹ silẹ nipilẹ Osun.
Iroyin ni ọrọ ọba jijẹ lo da wahala naa silẹ niluu Araromi Obu, to wa ni ijọba ibilẹ Ayedaade.
Awọn ọdọ dana sun ile ọba, ile araalu mejidinlogun, bẹẹ ni wọn tun sọ ina si ṣọọbu mẹtadinlọgbọn ati ọkọ ayọkẹlẹ kan.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ni iwadii ti bẹrẹ.