England tún ṣubú dàánù lẹ́ẹ̀kan si, Spain pòko ìyà fún wọn gba ife ẹ̀yẹ EURO

Aworan Nico Williams

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajura wa lọ bi ti ijankadi kọ, ẹgbẹ agbabọọlu Spain fẹyin England gbalẹ lati gba ami ẹyẹ idije EURO 2024.

Ami ayo meji si ẹyọkan ni Spain fi lu wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije EURO 2024.

Nico Williams lo koko gbayo sawon fun Spain, amo Cole Plamer da ayo naa pada.

Oyerzabal lo gbayo ti Spain fi bori wole eyi to je ibanuje fun England.

Aworan Harry Kane ati Lamina Yamal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oni lonii i jẹ, ẹni a bẹ lọwẹ, laago mẹjọ alẹ oni ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinla oṣu Keje yii ni ẹgbẹ agbabọọlu England yoo waako pẹlu akẹgbẹ wọn lati orilẹeede Spain ninu idije aṣekagba EURO 2024.

Niluu Berlin ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo ti waye lalẹ oni lorilẹede Germany to gbalejo idije naa.

Ọpọ awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji lo ti n leri wi pe didun lọsan yoo so fẹgbẹ agbabọọlu awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba EURO 2024.

Awọn ileeṣẹ iroyin lati orilẹede mejeeji naa ko gbẹyin nipa kọkọ oriṣiiriṣii iroyin lori ifẹsẹwọnsẹ ti yoo lamilaaka ọhun.

Ohun ti Harry Kane sọ lori ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije EURO 2024 ree

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Harry Kane to jẹ balogun ẹgbẹ agbabọọlu Three Lions England ti sọ pe oun ṣetan lati paarọ gbogbo ami ẹyẹ toun ti gba fun ife ẹyẹ idije EURO.

Kane ni ẹlẹsẹ ayo to gba goolu julọ sawọn fun orilẹede England.

Bakan naa, oun tun ni ẹlẹsẹ ayo to gba goolu sawọn ṣikeju julọ ninu itan idije ere bọọlu Premier League.

Amọ, Kane ko tii gba ami ẹyẹ kankan ri yala pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu England tabi ikọ agbabọọlu kankan.

Ti ẹ o gbagbe, Kane ṣe ipo keji pẹlu England lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Italy lu wọn lati gbami ẹyẹ EURO 2020.

O tun ti ṣe ipo keji pẹlu Tottenham ninu idije UEFA Champions League lẹyin ti Liverpool fiya jẹ wọn pẹlu ami ayo meji sodo ninu aṣekagba idije naa lọdun 2018.

Ṣugbọn Kane ti gba oriṣiiriṣii ami ẹyẹ ọlọdanni ni England ati ni Germany to ti n gbabọọlu jẹun fun ikọ Bayern Munich.

Amọ, Kane sọ pe ‘’lootọọ ni mi o tii gba ami ẹyẹ pẹlu ikọ agbabọọlu kankan ri, ṣugbọn mo ṣetan bayii lati yi itan yii pada.

Ko si ani ani kankan ninu wi pe mo ṣetan lati paarọ gbogbo ami ẹyẹ ọlọdanni ti mo ti gba fun ade EURO 2024 lalẹ ọjọ Aiku.’’

‘’Spain o bẹru ẹgbẹ agbabọlu England’’

Ọkan lara agbabọọlu ọwọ ẹyin fun ikọ agbabọọlu La Roja orilẹede Spain, Dani Vivian, ti sọ pe ẹru o bodo awọn ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije EURO 2024 alẹ oni.

Vivian sọ pe lootọọ ni ẹgbẹ agbabọọlu England n ṣana, amọ, o ni awọn naa ni ẹlẹsẹ ayo Lamina Yamal ati Nico Wiliiams.

Ti ẹgan si ni ẹh, awọn ọdọmọde agbabọọlu mejeeji yii ti fakọyọ fun Spain ninu idije EURO yii.

‘’Mo mọ pe England lawọn ẹlẹsẹ ayo to le fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ yii, wọn ṣi le dara oriṣiiriṣii ara pẹlu bọọlu, amọ, Yamal ati Williams wa fun Spain.

Awọn mejeeji ti mu inu wa dun ninu idije EURO yii, agbabọọlu to pegede lawọn mejeeji.

Wọn ṣi ni ajọṣepọ to dan mọran laarin ara wọn, inu wa dun wi pe a ni awọn mejeeji ninu ikọ agbabọọlu Spain.’’

Vivian ko ṣai kilọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Spain gbọdọ wa lojufo ki England ma ṣakoba fun wọn.