Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn afurasí ajínigbé tó pa bàbá ẹni ọdún 71 lẹ́yìn tí wọ́n gbowó ìtúsílẹ̀ tán l’Ógùn

Oríṣun àwòrán, SP Odutola/FB
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu awọn ọkunrin meji kan, Chukwuma Bartholomew ati Igwe Monday ti wọn jẹ ajinigbe.
Wọn ni wọn pa baba ẹni ọdun mọkanlelaadọrin, Alagba Adekunle Ifelaja lẹyin ti wọn ji i gbe tan ti wọn si tun gba owo itusilẹ lọwọ awọn ẹbi rẹ.
Yatọ si Alagba Ifelaja, ileeṣẹ ọlọpaa Ogun sọ pe awọn ajinigbe meji yii tun pa ọkunrin kan torukọ tiẹ n jẹ Ogunyemi Femi, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34), n’Ijebu-Igbo.
Alukoro ọlọpaa Ogun, SP Omolola Odutola, ṣalaye pe ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹfa ọdun 2024 yii ni ọwọ ba awọn ajinigbe ọhun lẹyin iwadii finni-finni.
‘’Awọn ni wọn maa n ji eeyan gbe n’Ijebu-Igbo.
Wọn aa ji eeyan gbe, wọn aa beere owo itusilẹ lọwọ awọn ẹbi rẹ, wọn aa si pada pa onitọhun’’
Bẹẹ ni SP Odutola sọ nipa awọn meji naa.
‘Lẹ́yìn tí wọ́n jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n mú wa lọ síbi tí wọ́n sin àwọn oku náà sí, a sì hú wọn jáde’

Oríṣun àwòrán, SP Odutola/FB
Nigba to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ lẹyin ti ọwọ ba Chukwuma ati Monday ti wọn si ti jẹwọ ẹṣe wọn, SP Odutọla sọ pe CP Abiodun Alamutu, ọga ọlọpaa Ogun, paṣẹ pe ki wọn niṣo nibi ti wọn sin awọn ti wọn ji gbe naa si.
Inu igbo kan n’Ijebu-Igbo lo ni wọn mu awọn lọ, ibẹ ni wọn ti gbẹlẹ ti ko jin, ti wọn sin Alagba Adeifẹ si pẹlu Ogunyemi.
Pẹlu aṣẹ ọga ọlọpaa, awọn ajingbe naa hu oku meji ti wọn sin jade.
‘Inú ilé ni wọ́n ti lọọ jí Alàgbà Adeife gbé lọ́jọ́ tí 2023 parí’

Oríṣun àwòrán, SP Odutola/ FB
Agbẹ ni Alagba Adekunle Ifelaja tawọn eeyan mọ si Adeife, lagbegbe Oke Sopen, n’Ijebu Igbo.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe ro o, inu ile rẹ lo wa lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2023 ti awọn ajinigbe fi wọle, ti wọn si gbe e lọ sibi ti ẹnikẹni ko mọ.
Ikọ ẹlẹni meje ni awọn ajinigbe yii bi ileeṣẹ ọlọpaa Ogun ṣe fidi ẹ mulẹ, lara wọn ni Chukwuma ati Monday tọwọ ba yii.
Awọn ajinigbe naa fi fidio ibi ti Alagba Adeife ti jokoo pọlọru lakata wọn ranṣẹ si awọn ẹbi rẹ, wọn ni ki wọn fi owo itusilẹ ranṣẹ bi wọn ko ba fẹẹ padanu rẹ.
Awọn ẹbi fi owo ọhun ranṣẹ, ṣugbọn awọn ajinigbe pada pa baba ẹni ọdun mọkanlelaadọrin naa.
Ni ti Femi Ogunyemi, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla ọdun 2023 ni wọn wọle lọọ gbe oun naa.
Wọn fi fidio bo ṣe wa lọdọ wọn ranṣẹ sawọn eeyan tiẹ naa, wọn gbowo ti wọn fi ranṣẹ, ṣugbọn wọn tun da ẹmi ọkunrin naa legbodo ni bawọn ọlọpaa ṣe sọ.
Ni bayii ṣaa, awọn ajinigbe meji naa ṣi n sọ tẹnu wọn fawọn ọlọpaa, lorii iṣẹ ibi ti wọn yan laayo.














