Èèyan 8 jóná ku nínú ìjàmbà ọkọ̀ elérò 18 ní Ogere, lójú ọ̀nà márosẹ̀ Eko si Ibadan

Oríṣun àwòrán, Ogun FRSC
Ajọ to n ri si aabo loju popo, FRSC, ti sọ pe ko din ni eeyan mẹjọ to jona ku ninu ijamba ọkọ kan to waye lọjọ kẹtala, oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii.
Florence Okpe, Agbẹnusọ fun ajọ ẹsọ loju popo, FRSC, ẹka tipinlẹ Ogun ṣe ṣalaye, agbegbe Malo nitosi Ogere, loju ọna marosẹ Eko si Ibadan, ni ijamba naa ti waye.
Atẹjade kan ti ajọ FRSC fisita lori isẹlẹ naa ni bọọsi akero kan ti nọmba rẹ jẹ DDA 733XA ni ijamba naa kan.
Eeyan mẹrindinlogun lo wa ninu ọkọ naa, ọkunrin mejila, obinrin agbalagba mẹta ati ọmọdebinrin kekere kan gẹgẹ bi ajọ naa ṣe wi.
Awọn ọkunrin mẹrin farapa, nigba ti eeyan mejila jona ku.
Mọ́to kankan kò kọlu bọ́ọ̀sì tó gbiná, òun fúnra rẹ̀ ló fẹ́ẹ́ ya àwọn ọkọ̀ mi-in sílẹ lọ́nà àìtọ́-FRSC
Ninu alaye FRSC nipa bi ijamba naa ṣe ṣẹlẹ, ajọ yii sọ pe ko si mọto kankan to kọlu bọọsi akero to gbina yii.
Wọn ni nibi ti dẹrẹba ọkọ naa ti n gbiyanju lati ya awọn ọkọ mi-in silẹ lọna aitọ lo ti padanu ijanu ọkọ. Bi eyi ṣe ṣẹlẹ ni mọto ọhun lọọ kọlu pepele ti wọn fi da ọna si meji,bayii ni ọkọ naa takiti, o si gba ina lẹsẹkẹsẹ.
Ileewosan kan ni wọn sare ko awọn to farapa ṣugbọn ti wọn ko ti i ku lọ.
Nigba to n kẹdun ijamba yii, ọga FRSC nipinlẹ Ogun, CC Akinwunmi Fasakin, sọ pe ijamba ọkọ to ṣee dena lo ṣẹlẹ yii.
O koro oju si awọn awakọ ti wọn maa n wa iwakuwa loju popo lai bikita fun ẹmi awọn eeyan.
CC Fasakin rọ awọn awakọ lati maa tẹle ofin irinna, o ni ki wọn ma sare kọja onka ti ofin irinna la kalẹ, ki ẹmi ti wọn o le da ma baa maa ti ọwọ wọn bọ bi eyi.














