Àwọn olùwọ́de ebi ń pa mí, tó yabo ilé ẹjọ́ giga ní Kano, ti jí fáìlì ẹjọ́ ìwà àjẹbanu Ganduje lọ - Ìjọba

Aworan Abdullahi Umar Ganduje

Oríṣun àwòrán, Dr Abdullahi Umar Ganduje/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Kano ti ke gbajare wi pe awọn janduku ti wọn yabo ile ẹjọ giga ipinlẹ Kano lasiko iwọde 'ebi n pa wa' to lọ, ti ji iwe ẹjọ iwa ajẹbanu gomina ipinlẹ naa, tẹlẹ ri, Abdullahi Umar Ganduje lọ.

Gomina Abba Kabir Yusuf lo fidi ọrọ yii mulẹ lasiko to ṣabẹwo si ile ẹjọ naa lati mọ bi o ṣe bajẹ si lẹyin ikọlu awọn janduku.

Kọmiṣọna eto idajọ, Haruna Isah Dederi, akọwe ile ẹjọ giga naa, Abdullahi Ado Bayero at'awọn eekan mii ni ẹka eto idajọ ni wọn kọwọrin pẹlu gomina.

Gomina Yusuf ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ọna lati doju ẹjọ iwa ibajẹ Ganduje bolẹ

Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Sanusi Dawakin Tofa, to jẹ agbẹnusọ fun gomina Gomina Yusuf fisita, o ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ọna lati doju ẹjọ iwa ibajẹ Ganduje bolẹ.

"Nnkan to ba ni ninu jẹ ni pe awọn ọta ipinlẹ Kano lọ ya awọn kọlọrọsi ẹda kan lati ba ọkan lara ohun ini ipinlẹ Kano jẹ tori ati doju ẹjọ iwa ibajẹ ti adele alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Ganduje ati ẹbi rẹ at'awọn amugbalẹgbẹ rẹ n jẹ lọwọ bolẹ," Gomina lo sọ bẹẹ.

Iroyin sọ pe oniruuru ẹka l'awọn janduku ọhun bajẹ ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Kano, to fi mọ ọfiisi adajọ agba gan an.

Atunṣe ile ẹjọ giga yii ni a gbọ pe yoo na ijọba to biliọnu kan naira tori awọn janduku ba oriṣiiriṣii ohun elo ọfiisi jẹ, bakan naa ni wọn si tun dana sun awọn ọkọ at'awọn iwe ipejọ.

Gomina Yusuf wa rọ awọn ọdọ lati yago fun iwa jagidijagan, ṣugbọn ki wọn wa imọ ti yoo ṣe wọn lanfaani lọjọ iwaju.

Gomina fi da araalu loju pe ijọba oun yoo ri daju pe ẹka eto idajọ ko ni kuna ninu ojuṣe rẹ gẹgẹ bi ireti awọn eeyan ti ko lẹnu lawujọ.

"Ijọba ko ni kaarẹ nipa didaabo bo araalu ati dukia wọn''

Gomina Yusuf paṣẹ ni kiakia pe ki atunṣe ile ẹjọ naa bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ.

"Ijọba ko ni kaarẹ nipa didaabo bo araalu ati dukia wọn.

A gbọdọ daabo bo ẹka eto idajọ ki idajọ ododo le wa fun gbogbo eeyan," gomina ṣeleri.

Gomina tun kaanu pẹlu adajọ agba, Dije Abdu Aboki ati gbogbo oṣiṣẹ ẹka eto idajọ lori ohun to ṣẹlẹ, o rọ wọn pe ki wọn maa kaarẹ lẹnu iṣẹ sisọ ododo ti wọn n ṣe.

Gomina Yusuf ko ṣai dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Kano fun atilẹyin wọn fun ijọba oun, o gbadura pe alaafia, iṣọkan ati idagbasoke eto ọrọaje ipinlẹ naa yoo maa tẹsiwaju.