Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ oníṣègùn pẹ̀lú àgbárí èèyàn mẹ́rìnlélógún, ó ní ìwòsàn lòun fi ṣe

Oríṣun àwòrán, Noeline Nabukenya
Ọwọ ọlọpaa Uganda ti tẹ ọkunrin kan pẹlu agbari eeyan mẹrinlelogun.
Ọlọpaa ni o ṣeeṣe ki ọkunrin naa ri ẹwọn gbere he lẹyin igbagbọ pe ṣe lo fi ori awọn eeyan naa joogun.
Agbẹnusọ ọlọpaa, Patrick Onyango sọ pe awọn yoo pe afurasi ọhun, Ddamulira Godfrey, lẹjọ labẹ ofin to tako fifi eeyan ṣoogun.
Yatọ si ori eeyan, wọn tun ri oniruru awọ ẹranko lojubọ ọgbẹni Godfrey to wa niluu Kampala, to jẹ olu ilu orilẹede naa.
Titi di asiko yii ni ọlọpaa fi n ṣayẹwo ojubọ naa boya wọn ṣi le ri awọn ẹya ara mii nibẹ.
Onyango sọ pe “a o pe e lẹjọ labe ofin Prevention and ‘Prohibition of Human Sacrifice Act’, eyii to fofin de ẹnikẹni lati ni ẹya ara eeyan ni ikawọ rẹ fun ṣiṣe oogun.
“To ba jẹbi ẹsun naa, yoo fi ẹwọn gbere jura.”
Nigba to n sọrọ, afurasi naa sọ pe oniṣegun ati babalawo ni oun, iwosan oniruru aisan si loun n ṣe.
Wayi o, ẹgbẹ awọn oniṣegun orilẹede naa ti sọ pe afurasi ọhun kii ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti irufẹ iroyin bayii yoo ti Uganda jade wa laarin ọsẹ diẹ sẹyin.
Loṣu to kọja, ọlọpaa ṣawari agbari eeyan mẹtadinlogun niluu Mpigi, to jẹ kilomita mọkanlelogoji siluu Kampala.
Ọlọpaa sọ pe ṣe ni wọn fi awọn eeyan ti wọn ri agbari wọn naa joogun.















