Ṣó o Láyà: Funke Akindele kópa nínú ìdánwò nípa àṣà àti èdè Yorùbá

Àkọlé fídíò, Ṣó o Láyà: Funke Akindele kópa nínú ìdánwò nípa àṣà àti èdè Yorùbá
Ṣó o Láyà: Funke Akindele kópa nínú ìdánwò nípa àṣà àti èdè Yorùbá

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Funke Akindele ti kopa lori eto Ṣó o laya ti BBC Yorùbá ṣe fun un.

Nibẹ lo ti dahun awọn ibeere lọkan o jọkan eyi to nii ṣe pẹlu ede Yoruba, aṣa ati iṣe wa.

Nigba ti a gbe igba Ṣe o laya naa de iwaju Funke Akindele, oun to ti ẹnu rẹ jade ni pe oun “laya bajẹ!”

O fi kun pe ọmọ Yoruba gidi ni oun ati pe oun ki ni ṣi eyikeyi ninu awọn ibere to wa ninu igba naa.

Amọ ṣe lootọ ni Funke laya “bajẹ” gẹgẹ bii ojulowo ọmọ Yoruba?

Ẹ wa nnkan fidi le, lati gbadun Funke lori ibeere ti BBC Yoruba bi lori eto wa, Ṣó o Láyà.