Ǹjẹ́ ìjọba lè pàṣẹ iye tí owó ọjà yóò jẹ́ ní Nàíjíríà?

Nigerian amrket

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ajọ to n ri sọrọ owo ọja, Nigerian Price and Consumer Protection Commission (FCCPC) ti fun gbogbo awọn ọlọja patapata ni gbedeke oṣu kan gbako lati ja owo ti wọn n ta awọn ọja wọn walẹ, bi bẹẹ kọ, wọn yoo foju winna ofin.

Ninu atẹjade ti igbakeji alaga ajọ FCCPC, Tunji Bello gbe jade l’Ọjọbọ, ọsẹ yii nibi ipade ti wọn ṣe, ajọ ọhun sọ pe awọn ṣagbekalẹ ipade ọhun lati yannanaa ọrọ lori ọna lati dẹkun ọwọngogo to wa lori awọn ọja kaakaa, eyi to lawọn oniṣowo n fa lai ronu.

Igbakeji alaga naa sọ pe lẹyin oṣu kan to jẹ gbedeke ọjọ yii, bi awọn oniṣowo ati alagbata ba kọ lati ja owo ọja wọn wale, yoo fi dandan lati lo ipa lori wọn.

Ki lo de ti ijọba fi sọ pe ki wọn ja owo ọja wa silẹ?

Aworan Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, State House

Gẹgẹ bi alaga FCCPC ṣe sọ, o lawọn gbe igbesẹ yii lẹyin iwadii ti awọn ṣe, ti awọn si ṣakiyesi pe iye owo ọja ti lọ soke kọja afẹnusọ ni Naijiria.

O ṣalaye pe, “A ṣakiyesi iye owo ọja ti wọn n ko wọ orileede yii yatọ si ara wọn lawọn agbegbe ọtọọtọ.

“Bo tilẹ jẹ pe awa na gba wi pe iṣoro wa nibi eto paṣipaarọ owo, eyi to n ṣakoba fun owo ọja, ṣugbọn sibẹ, a tun mọ pe awọn eeyan kan n bukun owo ọja ni.”

Orileede Naijiria n dojukọ alekun owo gidi. Pẹlu bo ṣe jẹ pe ninu oṣu keje, akọsilẹ ileeṣẹ to n ṣagbeyẹwo ni Naijiria ṣe sọ pe alekun owo ọja ti ja wa silẹ fun igba akọkọ, sibẹ ko si iyatọ kankan to foju han lawọn aarin ọja kaakiri.

Ninu abajade wọn, ileeṣẹ naa sọ pe alekun owo ọja ja silẹ lati ida mẹrinlelọgbọn le ni ọkandinlogun (34.19%) ninu oṣu Kẹfa, si ida mẹtalelọgbọn le mẹrin (33.0%) ninu oṣu Keje.

Fun ọpọlọpọ ọdun, awọn ọmọ ati olugbe Naijiria ti n koju iṣoro alekun lori owo ọja, koda latigba iṣakoso Aarẹ ana, Muhammadu Buhari.

Ṣugbọn sibẹ, latigba ti Aarẹ Bola Tinubu de ori aleefa ni nnkan tun ti bajẹ kọja sisọ.

Awọn igbesẹ ti aarẹ gbe ni kete to de ipo iṣakoso lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 ti jẹ ki alekun lori owo awọn ọja ti lọ soke gidi.

Yiyọ owo iranwọ ori epo, iyẹn sọbsidy, ati jijẹ ki owo naira sọ iye ti yoo jẹ lọja paṣipaarọ ti fa a ki owo ọja lọ soke.

Ohun to ṣẹlẹ yii lo fa a to fi jẹ pe ni ibẹrẹ oṣu Kẹjọ, awọn araalu dide lati fi ẹhonu wọn han kaakiri awọn ilu to wa lorileede naa.

Ki wa ni ojuṣe ajọ FCCPC?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ajọ Federal Competition and Consumer Protection Commission (FCCPC), jẹ ileeṣẹ ti wọn da silẹ labẹ ofin Naijiria lọdun 2018, pẹlu ojuṣe lati maa ṣabojuto ati daabobo awọn onraja lọwọ ipalara to ṣee ṣe ko waye lati ọdọ awọn ileeṣẹ to n figagbaga.

Iṣẹ wọn ni lati rii daju pe awọn ileeṣẹ to n ṣe ohun elo jade n ṣe e ni ibamu pẹlu ilana, ati lati rii daju pe awọn ohun elo ọhun ko ṣe ipalara kankan faraalu.

Ṣugbọn ṣa, njẹ FCCPC lagbara lati ṣagbekalẹ iye owo ọja?

Nigbakugba ti iṣoro ba waye lori alekun owo ori ọja, bii iru eyi ti Naijiria n koju lọwọ yii, nibi ti awọn araalu ti n koju iṣoro alekun lori owo ọja lojoojumọ, ohun ti awọn alakoso le ṣe ni lati ‘paṣẹ’ ati ‘amọran’ fun awọn ileeṣẹ tabi awọn ọlọja lati ja owo ọja walẹ.

Ṣugbọn “awọn alakoso naa ko ni agbara lati sọ iye ti owo ọja gbọdọ jẹ”, akọṣẹmọṣẹ amofin ati olukọ ni fasiti, Ọmọwe Sulaiman Santuraki lo sọ eyi di mimọ.

Sibẹ, gẹgẹ bo ṣe sọ, ajọ naa lagbara lati fiya jẹ ẹnikẹni to ba kọ lati tẹle aṣẹ wọn lọna to pọ.

Lara igbesẹ naa ni ki wọn sọ fawọn to ba tapa si aṣẹ wọn lati san owo itanran tabi ti okoowo tabi ileeṣẹ naa to ba kọ pa.

Yatọ si eyi, ile-ẹjọ kan tun wa ti yoo gbọ ẹjọ ti ajọ ọhun ba pe lati tako ẹnikẹni tabi ileeṣẹ yoowu to ba tapa si aṣẹ wọn, bakan naa ni ile-ẹjọ ọhun tun ni aṣẹ lati gbọ ẹjọ awọn ileeṣẹ tabi olokoowo ti wọn ba ro pe ajọ naa ko ṣe wọn daadaa bo ti tọ.

‘Idunkooko lasan lo jẹ’

Ọjọgbọn Muhamnmad Muttaqa Usman, to jẹ onimọ nipa eto ọrọ aje ni fasiti Ahmadu Bello to wa ni Zaria lorileede Naijiria, sọ pe aṣẹ ti ajọ FCCPC pa fawọn olokoowo ati ọlọja ko ṣee ṣe, ati pe “idunkooko lasan lo jẹ” bi a ba ṣagbeyẹwo eto ṣiṣe okoowo, eyi ti wọn pe ni ‘capitalism’.

O sọ pe ohun akọkọ to nilo lati wo ni “bawo ni ijọba ṣe fẹẹ mọ iye ti awon ontaja ra ọja wọn, ati iru iṣẹ ti wọn ṣe ko to di pe wọn gbe ọja ọhun de ibusọ itaja wọn lati ri ere?”

Ọjọgbọn naa tun sọ pe idiwọ miran ti ajọ naa yoo koju ni aisi oṣiṣẹ to to lati rii pe aṣẹ wọn gbe kalẹ, awọn eeyan n tẹle e.

“Wọn ko ni oṣiṣẹ to to lati fẹsẹ aṣẹ yii mulẹ, ohun ti wọn n sọ pe wọn fẹẹ ṣe kaakiri ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria,” o sọ fun BBC.

Ọmọwe Nasiru Sa'id Musa, toun naa jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa eto ọrọ aje ni fasiti Lead Prenour to wa niluu Abuja, sọ fun BBC pe ilana eto ọrọ aje Naijiria lasiko yii ko faaye gba Naijiria lati ṣagbekalẹ owo ori awọn ọja.

O ni: “Ijọba ko lagbara nigba ti ẹ ba ra ọja lai jẹ pe wọn ran yin lọwọ, ti wọn si wa de lọjọ kan lati sọ pe awọn yoo gbe ilana titaja ati iye ti owo ọja kọọkan gbọdọ jẹ, eyi ko dara to, ayafi to ba jẹ pe ohun miran ni wọn ṣe.”

Akọṣẹmọṣẹ naa sọ pe, idunkooko ijọba yii lati jẹ awọn ọlọja ja owo ọja walẹ ko le so eso kankan, to si ni eyi yoo tun jẹ kowo ọja lọ soke ni.

Ọna abayọ si ọwọngogo

Nipa ọna abayọ si iṣoro ọwọngogo ọja lorileede Naijiria, Ọjọgbọn Muhamnmad Muttaqa Usman sọ fun BBC pe ninu eto ọrọ aje, ọja okoowo naa n wa iye owo tirẹ.

Bi ijọba ba fẹ ki owo ọja ja wa silẹ, ki wọn mu adinku ba owo ori, ati pe ki wọn ṣe awọn opopona ti yoo jẹ ki awọn ọlọja maa gbe ọja wọn nirọrun lai ni iṣoro. Ki ijọba si rii daju pe awọn oṣiṣẹ wọn ko di wọn lọwọ, igba naa ni ijọba le lẹnu ọrọ lati sọ pe awọn nnkan tohun ti ṣe ree, nnkan tohun fẹ ki wọn ṣe ree lati mu adinku ba owo ọja.

Ati pe, “bi ijọba ba fẹẹ ja owo ọja walẹ, ki wọn ko awọn ọja ọhun pamọ rẹpẹtẹ, ki wọn si ko o jade rẹpẹtẹ sita fun awọn ontaja lowo kekere, eyii ni yoo sọ bi owo ọja yoo ṣe ja walẹ,” o sọ bẹẹ

Bakan naa, Ọmọwe Nasiru Sa'id Musa, sọ pe awọn igbesẹ asiko perete, atigbadegba ati asiko ọlọjọ pipẹ wa.

O sọ pe igbesẹ akọkọ ni ki ijọba mu owo ori to wa lori awọn ọja kan kuro, nitori pe nibikibi ti owo ọja naa ti han, owo ori wọn lo n ṣokunfa rẹ.

Ẹlẹẹkeji ni pe, ki ijọba sọ iye ti owo dọla yoo jẹ, ki wọn si pese owo dọla naa fawọn ọlọja ati awọn ileeṣẹ lati ko ọja wọle.

“Bi wọn ko ba ṣe awọn nnkan wọnyi, ofuutufẹẹtẹ ni gbogbo nnakn ti wọn ba n ṣe, ṣiṣe sọbsidi ko nii yọ awọn eeyan kuro ninu iṣẹ ati oṣi, ko nii ṣe pẹlu iye tirela irẹsi ti wọn pin, ko nii tan iṣoro to wa nilẹ,” o ṣalaye.

Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ pe: “Igbesẹ atigbadegba ati ọlọjọ pipẹ yii ni yoo jẹ ki ohun ti wọn n fẹ jẹyọ laarin asiko ti wọn ba fi silẹ.”