Ètò ìsìnkú Taiwo Akinkunmi, tó ṣe àsìá Nàíjíríà bẹ̀rẹ̀ n‘Ibadan

Ilana isinku Alagba Taiwo Akinkunmi
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ilana eto isinku Alagba Taiwo Micheal Akinkunmi, ẹni to se agbekalẹ asia Naijiria, yoo gbera ni irọlẹ oni Ọjọru nilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Oyo.

Oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 ni Alagba Akinkunmi jade laye ni ẹni ọdun mẹtadinlaadọrun.

Ọpọlọpọ awuyewuye lo rọ mọ eto isinku Oloogbe naa lori ipa to yẹ ki ijọba apapọ ko si eyo isisnku naa eyi to mu ko pẹ diẹ ki wọn to sin oloogbe naa.

Sugbọn lẹyin ọdun kan, gbogbo ọrọ naa ti ni iyanju, eto si ti to fun isinku Oloogbe naa bayii.

Aṣoju mọlẹbi Akinkunmi, Samuel Akinkunmi ṣe alaye fun BBC Yoruba wi pe ọjọ mẹta gbako ni ẹyẹ ikẹyin yoo fi waye fun baba wọn.

Ẹyẹ ikẹyin naa ni yoo waye laarin oni, Ọjọru, ọjọ kẹrin oṣu kẹsan an, si ọjọ Ẹti ọtunla, ọjọ kẹfa oṣu kẹsan an ọdun 2024.

Taiwo Akinkunmi

Oríṣun àwòrán, Taiwo Akinkunmi

Bi ilana isinku Alagba Taiwo Akinkunmi yoo se waye ni ọjọ kọọkan

Ọjọru, Ọjọ Kẹrin Oṣu Kẹsan an:

Akanṣe eto aṣalẹ orin yoo waye ni iranti Oloogbe naa ninu ọgba ile ẹkọ girama, 'Ibadan Grammar School', bẹrẹ lati aago mẹta ọsan.

Ọjọbọ, Ọjọ Karun un Oṣu Kẹsan an:

Aisun onigbagbọ yoo waye ninu ọgba ile ẹkọ girama, 'Ibadan Grammar School', bẹrẹ lati aago mẹta ọsan.

Ọjọ Ẹti, Ọjọ Kẹfa Oṣu Kẹsan an:

Isin onigbagbọ ati afihan ara Oloogbe yoo waye ni papa iṣere 'Liberty Stadium' to n bẹ ni agbegbe Ring Road niluu Ibadan.

Aago mẹjọ owurọ ni afihan ara oloogbe naa yoo waye, ko to di pe wọn yoo lọ bo aṣiri Oloogbe naa si ile rẹ to n bẹ ni agbegbe Ẹlẹbu niluu Ibadan.

Ohun ti o kan lẹyin isinku ni ayẹyẹ igbalejo ni agbegbe kan naa.

Yatọ si iranlọwọ ti wọn n reti lati ọwọ ijọba apapọ, saaju asiko yii ni aṣoju mọlẹbi Akinkunmi, ti fi idi ọrọ mulẹ fun awọn oniroyin wi pe, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde gbe owo kalẹ fun eto isinku Oloogbe Akinkunmi.

Alagba Taiwo Akinkunmi

Oríṣun àwòrán, Abdullahi

Ta ni Michael Taiwo Akinkunmi

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ Kẹwa osu Karun ọdun 1936 ni Michael taiwo Akinkunmi fori sọlẹ silu Ibadan, ọmọ bibi Ibadan si nii se pẹlu

Taiwo, gẹgẹ bi orukọ rẹ ti salaye, jẹ ibeji, oun si ni akọkọ ninu awọn ọmọ meji to wa saye lasiko kannaa, latinu iya kannaa, a ko si gbọ nipa ikeji rẹ, tii se Kẹhinde, titi di oni oloni, o si seese ko ma si laye mọ

Taiwo gbe lọdọ baba rẹ titi to fi pe ọmọ ọdun ọdun mẹjọ, ko to di pe isẹ gbe baba rẹ lọ si ẹkun ariwa Naijiria, nibẹ si lo ti bẹrẹ ileẹkọ alakọbẹrẹ rẹ, lẹyin ti baba rẹ fẹyin ti si ni wọn pada wa silẹ Kaarọ Oojire nihin

Lẹyin ti wọn pada de, Taiwo Akinkunmi fi orukọ silẹ nile ẹkọ alakọbẹrẹ onitẹbọmi to wa ni adugbo Idikan nilu Ibadan, to si pari lọdun 1949

Ọdun 1950 lo lọ sile ẹkọ girama Ibadan Grammar School, to si kẹkọ jade kuro nibẹ lọdun 1955, pẹlu iwe ẹri oniwe mẹwa. Lọgan ti Taiwo Akinkunmi ni iwe ẹri girama, lo gba isẹ labẹ ijọba ẹkun iwọ oorun guusu ilẹ yii ijọun, gẹgẹ bii osisẹ ijọba eleto ọgbin lọgba Secretariat

Taiwo sisẹ fun ọdun diẹ, ko to tẹkọ leti lọ silu London lati kọ ẹkọ nipa imọ ẹrọ to nii se pẹlu ina ọba, taa mọ si Electrical Engineering, nile ẹkọ ẹkọsẹ ọwọ ti Norwood Technical College

Ileẹkọ yii ni Taiwo Akinkunmi wa, to fi ri ikede kan ka loju ewe iwe iroyin pe wọn n wa awọn to lee ya aworan asia fun orilẹede Naijiria, to n gbaradi lati gba ominira lọwọ awọn oyinbo aminisin nigba naa, aworan asia Naijiria to ya si ni awọn eebo kan saara si pe o pegede, o fi gbọọrọ jẹka, laarin awọn asia yoku ti awọn miran se lọdun 1958

Awọ eweko ati funfun si ni Taiwo Akinkunmi fi se asia Naijiria. Awọ eweko naa duro fun ọrọ aje Naijiria tii se eto ọgbin lasiko igba naa, eyiun ilẹ ti eto ọgbin ti n gbooro, ilẹ to lọra fun ohun ọgbin nigba ti awọ funfun tumọ si alaafia

Ọjọ Kinni, osu Kẹwa ọdun 1960 ti Naijiria gba ominira si ni wọn fi asia Naijiria naa lọlẹ fun lilo, tijọba si san ọgọrun pọun (£100) fun Taiwo Akinkunmi, eyi tii se ọrinlerugba ati ẹyọ kan dọla, ($281), ta ba si sọ di Naira, o jẹ ẹgbẹrun lọna mejilelogoji ati aadọjọ naira, (₦ 42,150)

Taiwo Akinkunmi pada si orilẹede Naijiria lẹyin ẹkọ rẹ lọdun 1963, to si pada si ẹka isẹ ọgbin to ti kuro tẹlẹ lati maa sisẹ titi di ọdun 1994 to fẹyinti

Ọjọ Kọkandinlọgbọn osu Kẹsan ọdun 2014 ni ijọba apapọ fun Taiwo Akinkunmi ni ami ẹyẹ OFR nilu Abuja, lati mọriri ọgbọn inu ati ẹbun atinuda to lo fi gbe asia Naijiria, to jẹ oju ni gbese kalẹ

Gẹgẹ bii ẹni ti isẹ ọwọ rẹ wu lori, Taiwo Akinkunmi maa n wọ asọ agbada toke tilẹ to jẹ awọ asia ilẹ Naijiria, eyi to tun ba asa Yoruba to ti wa mu

Agbo ile baba Taiwo Akinkunmi to wa ni adugbo Ekotẹdo nilu Ibadan ni baba naa n gbe lẹyin to fẹyin ti lẹnu isẹ ọba tan, ti atijẹun si di ọtọtọ ọran

Amọ pẹlu igbe awọn akọroyin, ijọba ipinlẹ Ọyọ, lasiko isejọba Ọtunba Christopher Adebayọ Alao Akala, kọ ile kan fun ni adugbo Ayepe, Academy loju ọna Iwo Road nilu Ibadan

Koda, awọ eweko ati funfun, tii se asia ilẹ wa ni wọn fi kun ile ọhun

Taiwo Akinkunmi ni iyawo, to si bi ọmọ, ilu abinibi rẹ, Ibadan si lo tẹdo si lọjọ ogbo rẹ ko to dagbere faye

Oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 ni Alagba Akinkunmi jade laye ni ẹni ọdun mẹtadinlaadọrun.