Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
N jẹ o ti gbọ nipa omi ati ọṣẹ iyanu ti ile ijọsin kan n ta fawọn eeyan?
ẹn hẹ ẹn, mi ti gbọ o, o ya jami si
Ajọ NAFDAC to n ṣamojuto ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria lo ti kilọ faraalu wi pe ki wọn sọra fun omi ati ọsẹ ti ile ijọsin Christ Mercy Land n ta
Eyi ma tun gbenu tan o
Ajọ naa ni awọn ko fonte lu omi ati ọṣẹ ti ile ijọsin naa n ta
Ti o ba fẹ mọ sii nipa omi ati ọṣẹ iyanu yii, kan si oju opo BBC.com/ Yoruba
Pekele pekele, arugbo jẹ gbese tani o san?
Ki lo tun de o?
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lo maa ti nawọ gan an aarẹ ẹgbẹ osisẹ NLC, Joe Ajaero
Agbẹnusọ ẹgbẹ NLC, Benson Upah ni lasiko ti Ajaero fẹ wọ baalu sorilẹede UK fun ipade kan ni wọn mu un
Duro na, ẹsẹ wo gan an ni Ajaero ṣe to bẹẹ?
Wo ma laagun jina, kan soju opo wa fun ẹkunrẹrẹ
Iro to jina si otitọ nio, ẹ ma da wọn lohun
Ileeṣẹ ologun Naijiria ti sọ pe irọ nla niroyin to sọ pe ọgọọrọ omogun n kọwe fiṣẹ silẹ tori airi itọju
Kan si oju opo BBC.com/Yoruba fun ẹkunrẹrẹ iroyin naa
