Àbọ̀ ìwádìí BBC rèé lórí ìdí tí àwọn agbẹ̀bí ṣe ń pa àwọn ọmọdébìnrin jòjòló ní India

Siro
    • Author, Amitabh Parashar
    • Role, BBC Eye Investigations
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Siro Devi ati Monica n di mọ ara wọn lẹyin ọpọ ọdun ti wọn kọkọ pade.

Ọdun diẹ lo ku ki Monica pe ẹni ̣ọgbọn ọdun bayii to pada si India nibi ti wọn ti bi oun ati ọpọ ọmọde lọpọ ọdun sẹyin.

Ṣaaju ki wọn to bi Monica, ni ṣe ni awọn agbẹbi maa n ṣekupa awọn ọmọ to jẹ obinrin.

Iwadii fi han pe Monica wa lara awọn ọmọ to yẹ ki wọn pa amọ ti Devi gbala.

Akọroyin BBC, Amitabh Parashar ti kọkọ ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun Devi atawọn agbẹbi mii lọdun 1996.

Ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba sọ pe awọn agbẹbi naa maa n ṣekupa awọn ọmọ obirin nipa fifun wọn lọrun pa tabi ki wọn fun wọn ni kẹmika, lẹyin ti iya awọn ọmọ naa ba ni ki wọn ṣe bẹẹ.

Olori awọn agbẹbi naa, Hakiya Devi sọ fun akọroyin BBC pe oun ti pa ọmọbinrin ti iye wọn to mejila si mẹtala.

Agbẹbi miran, Dharmi Devi sọ pe oun ti ṣekupa ọmọbinrin ti iye wọn je mẹẹdogun si ogun.

O ṣoro lati sọ ni pato iye ọmọbinrin ti wọn ti ṣekupa lagbegbe ti iṣẹlẹ naa ti n waye ṣugbọn iwadii ti ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba ṣe sọ pe, o le ni ẹgbẹrun kan ọmọdebinrin ti awọn agbẹbi ṣekupa.

Hakiya sọ fun BBC pe o ṣoro fun awọn gẹgẹ bii agbẹbi lati kọ lati pa awọn ọmọ naa.

O ni “awọn mọlẹbi wọn yo duro ṣeyin ilẹkun pẹlu ẹgba pe a gbọdọ pa awọn ọmọ ọhun.

“Wọn maa n sọ fun wa pe… a ti bi ọmọbinrin mẹrin si marun un tẹlẹ, ko ni si owo lọwọ wa mọ ti a ba san owo ori lori obinrin mẹrin, bayii a tun ti bi obinrin mii, ẹ ba wa pa wọn.

“Ta ni a fẹ ro tiwa fun? Ẹru n ba wa. Ti a ba lọ sọ fun ọlọpaa a maa ko sinu wahala, niṣe ni awọn obi naa maa n dunkoko mọ wa.”

Agba akọroyin Amitabh Parashar
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọpọ igba lawọn eeyan maa n lo awọn agbẹbi ti wọn ba fẹ bi ọmọ ni India, paapaa lawọn igberiko.

Pupọ ninu awọn agbẹbi naa ni ko rọwọ họri.

Agba akọroyin BBC, Amitabh Parashar jabọ pe nigba mii apo irẹsi, apo agbado tabi owo perete ni wọn maa n fun awọn agbẹbi naa lati gbẹmi ọmọ tuntun.

Nigba mii ẹwẹ ni wọn kii ri owo iṣe wọn gba paapaa, amọ ti wọn gbẹbi ọkunrin, agbẹbi naa le pa owo ti iye rẹ to ẹgbẹrun kan rupee.

Eyii ko ṣẹyin pe ni India, obinrin lo maa n san owo ori fun idile ọkunrin.

Lootọ ni wọn ti wọgile aṣa naa lọdun 1961, amọ awọn eeyan ṣi n mu aṣa naa lo titi di ibẹrẹ ọdun 1990 ati titi di oni yii.

Oniruru nnkan ni wọn n san gẹgẹ bii owo ori, o le jẹ owo, ẹṣọ ara, awọn ohun elo idana inu ile, ati bẹẹ lọ.

Ṣugbọn fun ọpọ idile, dandan ni owo ori naa jẹ.

Eredi ree ti wọn fi maa n ri ọmọkunrin gẹgẹ bii alubarika ti wọn si maa n ri ọmọbinrin gẹgẹ bii gbese ọjọ iwaju.

Siro

“Oke tente ni ọmọkunrun wa, nigba ti ọmọbinrin wa ni isalẹ, ko ni ṣe boya ọkunrin naa tọju awọn obi rẹ, ohun ti gbogbo wọn n fẹ ni ọmọkunrin.”

Anila atawọn obinrin ni ibẹrẹ ọdun 1990

Lẹyin ti akọroyin BBC ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun awọn obinrin naa lọdun 1996, iyatọ diẹ diẹ bẹrẹ si n waye.

Awọn agbẹbi ọhun bẹrẹ si n kọ lati maa pa awọn ọmọbinrin jojolo.

Obinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Anila Kumari lo bẹrẹ ayipada ọhun lẹyin to bẹrẹ iwadii bi awọn ọmọdebinrin ṣe n ku to n si n la awọn obi lọyẹ.

Ọna ti Anila gbe gba ni bibere lọwọ awọn agbẹbi naa pe “to ba jẹ ọmọ yin ni ṣe ẹ maa gbẹmi rẹ nitori o jẹ obinrin?”

Grey line
Grey line

Anila ati obinrin kan, Medha Shekar ni wọn jọjọ n tọju awọn ọmọ ti Anila ba doola lọwọ iku.

Ti wọn ba ti doola awọn ọmọ naa tan ni wọn maa n ko wọn lọ si ọọfisi ajọ ti kii ṣe ti ijọba, eyii to jẹ ti Medha Shekar.

Lẹyin naa ni wọn fa awọn ọmọ ọhun le awọn to n gba ọmọ tọ lọwọ.

Gbogbo awọn ọmọ ti Anila doola lo fi “Kosi” si ibẹrẹ orukọ fun idanimọ.

Monica ati baba re
Àkọlé àwòrán, Monica ree pẹlu baba to gba a tọ lati ọmọ ọdun mẹta

Kosi yii ni orukọ odo kan niluu Bihar ti wọn ti wa, lara awọn ọmọ to doola to si fi Kosi si ara orukọ wọn ni Monica wa.

Lẹyin ọpọ iwadii, ẹri fi han pe Monica wa lara awọn ọmọdebinrin ti Anila atawọn marun un mii doola lọpọ ọdun sẹyin.

Nigba ti Monica n ba BBC sọrọ, o ni inu oun dun pe awọn to gba oun tọ jẹ mọlẹbi to dara.

Anila
Àkọlé àwòrán, Anila ati Monica

Niṣe ni Anila n wa ẹkun mu lẹyin ti oun ati Monica pade.

Bo ṣe di mọ ọdọbin rin naa lo tun n fi irun rẹ ṣere.

newborn baby
Àkọlé àwòrán, Ọkan lara awọn ọmọbinrin ti BBC ri lasiko ti a n ko irioyin yii jọ, eyiin ti iya rẹ ju sọnu

Lẹyin naa lo sọ fun pe “mo gbe ọ lọ sile ọmọ alainiya lati doola ẹmi rẹ, ọkan mi ṣẹṣẹ ni isinimi ni bayii.”

Wayi o, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan ko pa ọmọ obinrin mọ bayii ni india, wọn kan ṣi n ṣẹ oyun inu ti wọn ba ti mọ pe obiinrin ni.