Àwọn obìnrin Kenya ń bèrè ìdajọ́ òdodo lẹ́yìn tí ọkùnrin kan dáná sun ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP
- Author, Esther Kahumbi & Celestine Karoney
- Role, BBC News, Nairobi
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Awọn obinrin ni Kenya ti bẹrẹ si n koro oju si iṣekupani awọn akẹgbẹ wọn bayii lẹyin iku Rebecca Cheptegei, to jẹ elere odaraya Olympic ti ọrẹkunrin rẹ ṣekupa.
Rebecca, to jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn jade laye lẹyin ọjọ diẹ ti ọrẹkunrin rẹ tijọ, da epo bẹntiro si ori rẹ, to si ṣana si.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti irufẹ nnkan bẹẹ yoo ṣelẹ latari pe orilẹede Kenya ni iwa ipa si awọn obirin ti pu julọ nilẹ adulawọ.
Iroyin ni, ninu oṣu Kinni ọdun yii nikan ṣoṣo, obinrin mẹwaa lo ṣalabapade iku wọn latari wọn o jẹ obinrin.
Jane (ki ṣe orukọ abisọ rẹ) sọ fun BBC pe oun ti di ẹni to n farapa pamọ bayii latari iwa ipa ninu ile.
O ni oun ko to ẹni to n lọ ibiṣẹ oojọ oun latari ipalara ti ọkọ rẹ atijọ ṣe fun un.
O ni “afojusun rẹ ni lati gbẹmi mi, o gun mi lọbẹ o si fi mi silẹ ki n ku.
“Ti kii ba ṣe ti awọn alabagbe to doola mi ni, o yẹ ki n ti jade laye.
Jane ṣalaye fun wa pe fun ọpọ ọdun loun fi n jiya lọwọ ọkunrin naa ki oun to ko ẹru oun kuro lọdọ rẹ.
O ṣalaye pe “afi bii igba ti eeyan ba wa ni ọrun apaadi ni asiko naa ri fun mi amọ mi o tilẹ le ṣalaye bi mo ṣe rọju lati duro sibẹ gan.”
Titi di asiko yi ni ọkunrin naa ṣi maa halẹ mọ.
Jani ni “inu ibẹru ni mo n gbe, o ni oun fẹ yanju mi patapata.
“Mi o le sun loru, mo ti di ẹni to n lo ogun bayii nitori ilera ọpọlọ mi, emi kọ ni mo n wu iwa ti ko dara o ṣugbọn niṣe lo da bii pe inu ahamọ ni mo wa,”

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lọdun 2018, ajọ WHO jabọ pe ida 38% awọn obirin ni Kenya laarin ọdun mẹẹdogun si mọkandinlaadọta lo ti ni iriri iwa ipa lati ọwọ ololufẹ wọn.
Awọn ẹgbẹ to n ṣeranwọ fun awọn to ni iriri iwa ipa sọ pe ọdọdun ni iwa bururu naa n peleke si lorilẹede ọhun.
Njeri Migwi sọ fun BBC pe “nigba mii a maa n gba ipe bii aadọta, ti nnkan bii ogun eeyan si maa n wa ba wa ni ọọfisi wa lojumọ lati wa fi ọrọ nipa iwa ipa to wa leti.
Migwi ni adari ajọ Usikimye – to tumọ si “maṣe dakẹ gbera” ni ede Swahili.
Lọdun 2021, Aarẹ Uhuru Kenyata kede pe iwa si awọn obnrin gẹgẹ ti di iṣoro orilẹede Kenya.
Lẹyin ọdun kan, iwadii ijọba kan fi han pe ida 41% awọn obinrin to wa nile ọkọ ni lo n koju iwa ipa ninu ile.
Iwadii kan ti ajọ Africa Data Hub ṣe laarin ọdun 2016 si ọdun 2023 fi han pe o le ni obinrin 500 ti wọn pa ni Kenya laarin awọn ọdun naa.
Ninu atẹjade ti ajọ UN fi lede laipẹ yii nipa bi wọn ṣe n pa obinrin lagbaye, nnkan bii 20,000 obinrin ni wọn pa ni Afrika nikan ṣoṣo, eyii to jẹ eyii to pọju lagbaye.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Elere idaraya mii, Joan Chelimo sọ pe iku Cheptegei da omi tutu si oun lọkan.
O ni “mi o le sun ni gbogbo igba ti mo ba n ro pe ṣe ni wọn dana sun odidi eeyan laaye.”
Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ọrẹkunrin Cheptegei funra rẹ jade laye latari ina to jo oun funra rẹ lasiko to sọ ina si oloogbe ọhun.
Chelimo jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ Tirop’s Angels, to jẹ ẹgbẹ ajafẹtọ ti wọn gbe kalẹ lẹyin ti wọn ṣekupa alare idaray mii, Agnes Tirop.
O ṣalaye pe Cheptegei fi ọrọ naa lọ ọlọpaa nipa iwa ipa amọ ọlọpa ko gbe igbesẹ kankan nipa rẹ.
Amọ ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe ologbe naa ko fi ọrọ ọhun lọ awọn.
Bo tilẹ jẹ pe Kenya ti gbe ofin to lodi si iwa ipa si awọn obinrin kalẹ, Awọn eeyan gbagbọ pe ofin naa ko mulẹ rara.
Judy Gitau, to jẹ adari ajọ Equality Now ni Afrika sọ pe “ijọba kan ro pe ti wọn ti gbe ofin kalẹ o ti tan niyẹn, amọ wọn ko mọ pe ofin naa ko ni fiya jẹ arufin funra rẹ.”

Oríṣun àwòrán, AFP
Lọdun 2004, ijọba Kenya ṣeto kan ti yoo mu ko rọrun fun awọn obinrin lati fi ọrọ nipa iwa ipa to ọlọpaa leti.
Ṣugbọn idaji agọ ọlọpaa ni ko ni irufẹ eto bẹẹ, ọlọpaa sọ pe oun to fa a ko ṣẹyin awọn ohun elo ati oṣiṣẹ ti ko to.
Niluu Trans Nzoia ti Cheptegei gbe ṣaaju iku rẹ, agọ ọlọpaa marun pere lo wa nibẹ amọ ko si eyikeyi ninu wọn ti araalu ti le lọ fi ẹjọ sun nipa iwa ipa ninu ile.
Olori awọn oluwadii iwa ọdaran lagbegbe naa, Kennedy Apindi sọ pe “o ṣoro lati lọ fi ẹjọ sun ọlọpaa.
“Lọpọ igba lo maa n pẹ ki awọn eeyan to lọ fi ọrọ naa sun, tabi ki wọn ma tilẹ fi ọrọ ọhun to ọlọpaa leti paapaa titi ti yoo fi pẹ ju.”
Cheptegie ni obinrin elere idaraya kẹta ti ololufẹ rẹ yoo ṣekupa ni Kenya laarin ọdun mẹta sẹyin.
Ni 2021 ni wọn ṣadede ba oku Agnes Tirop ninu ile rẹ lẹyin to gba ife ẹyẹ ere 10km ni Germany.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin oṣu mẹfa pere ti wọn pa Tirop ni wọn ba oku Damaris Muthee Mutua, to jẹ ọmọ orilẹede Kenya to n sare fun Bahrain ninu ile rẹ lagbegbe Rift Valley.
Iwadii ọlọpaa fi han pe ṣe ni wọn fun ọrun rẹ pa.
Ẹnikẹni ko tii jẹjọ titi di asiko yii nipa iku naa.
Amọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn n wa ọrẹkun rẹ gẹgẹ bii afurasi lori iku ọhun.
Gẹgẹ bo ṣe ṣẹlẹ si Cheptegei, iroyin sọ pe wahala bẹrẹ laarin awọn ololufẹ naa lori ọrọ owo.















