Ìbúgbàmù ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ “pager” tún pa èèyàn mẹ́rìnlá ní orílẹ̀-èdè Lebanon

- Author, Joya Berbery & Carine Torbey
- Role, BBC News Arabic, Beirut
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ìbúgbàmù mìíràn tún wáyé ní orílẹ̀ èdè Lebanon lásìkò táwọn èèyàn péjọ láti ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ 'pager' bẹ̀rẹ̀ sí ní bú gbàmù mọ́ àwọn èèyàn lápò.
Iléeṣẹ́ ètò ìlera orílẹ̀ èdè Lebanon ní kò dín ní èèyàn mẹ́rìnlá tó pàdánù ẹ̀mí wọn táwọn 450 sì farapa nígbà tí àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tún bẹ̀rẹ̀ sí ní bú gbàmù.
Níbi ètò ìsìnkú náà, àwọn èèyàn ń fi ìbínú wọn hàn nígbà tí wọ́n ń bá BBC sọ̀rọ̀.
Àwọn dókítà júwe àwọn egbò tí wọ́n ń tọ́jú bíi àwọn èyí tó burú jáì.
Ikọ̀ BBC tó wà ní orílẹ̀ èdè Lebanon ti ń ṣe àkójọ ìròyìn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà káàkiri olú ìlú Beirut.
Joya Berbery ní ẹkùn Ghobeiry, Beirut

Níṣe ni àwọn èèyàn ń kíyèsí ara wọn pàápàá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe àmúlò fóònù àtàwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ míì látàrí ìbúgbàmù tó wáyé pẹ̀lú àwọn pager àti ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀.
Lásìkò ètò ìsìnkú àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìbúgbàmù àkọ́kọ́ ń lọ lọ́wọ́ ni ìbúgbàmù mìíràn tún dún táwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wà nínú ìbẹ̀rùbojo, tí wan sì ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.
Ikọ̀ BBC tó wà níbẹ̀ nílò láti kúrò níbi ètò ìsìnkú náà lọ sí ibi tí ààbò láti dóòlà ẹ̀mí ara wọn.
Àwọn èèyàn tó bá BBC sọ̀rọ̀ sọ pé àwọn wà níbi ètò ìsìnkú náà láti ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún ọmọ ọdún mọ́kànlá kan àti ikọ̀ Hezbollah mẹ́ta tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìbúgbàmù tó wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Àwọn ọkùnrin, obìnrin tó fi mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n ya sí òpópónà láti fi ẹ̀hónú wọn hàn pẹ̀lú àkọ́lé àti àwòrán ọmọ náà lọ́wọ́.
Bí àwọn kan ṣe mú àsíá Hezbollah dání, ni àwọn mìíràn mú fíláàgì dúdú tó ní àwòrán olórí ikọ̀ Hezbollah, Hassan Nasrallah dání.
Àwọn obìnrin tó wọ aṣọ dúdú ni wọ́n ń da òdòdó sórí pósí àwọn èèyàn tó jáde láyé.
Àwọn òbí mìíràn mú àwọn ọmọ dání.
Àwọn èèyàn ní àwọn gbàgbọ́ pé ìwà tó burú jáì sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ni nǹkan tó wáyé náà àmọ́ ó tún mú kí ìpinnu àwọn túnbọ̀ dúró ṣinṣin si ni.

Nígbà tí ikọ̀ wa bèèrè lọ́wọ́ ọkùnrin kan pé ṣé ó mọ ẹnikẹ́ni lára àwọn tó farapa, ó fèsì pé gbogbo àwọn ni àwọn mọra àti pé ìnira tí àwọn èèyàn náà ní yálà látara ojú ọgbẹ́ ni tàbí nínú ọkàn wúwo púpọ̀ gidi.
“Àmọ́ kìí ṣe nǹkan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣẹlẹ̀, a ò ní kó àárẹ̀ ọkàn.”
Obìnrin ẹni ọdún márùndínláàdọ́ta tó wà níbi ètò ìsìnkú náà sọ pé ìkọlù náà yóò túnbọ̀ mú ọkàn àwọn le si ni àti pé ẹni tó bá pàdánù ojú kan yóò fi ojú kejì jà àti pé gbogbo àwọn yóò dúró ti ara àwọn láti jà fúnra àwọn.

Carine Torbey ní ilé ìwòsàn Mount Lebanon Hospital University Medical Center

Níṣe ni àwọn èrò pọ̀ ní iwájú ilé ìwòsàn tí wọ́n fẹ́ gba nípa àwọn èèyàn wọn tó ń gba ìtọ́jú àti láti mọ ipò ìlera wọn.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Elias Warrak, tó jẹ́ dókítà ojú ní ilé ìwòsàn Mount Lebanon Hospital University Medical Center ní ọjọ́ ìṣẹ́gun ni ọjọ́ tó burú jù nínú ìgbésí ayé òun.
Ó ní ojú tí òun yọ kúrò lórí àwọn èèyàn lálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun náà pọ̀ ju iye tí òun ti yọ láti ìgbà tí òun ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí dókítà ojú ní ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n sẹ́yìn.
“Mo gbìyànjú láti dóòlà ojú kan fún àwọn kan àmọ́ mi ò ri ṣe fún àwọn ẹlòmíràn, mo yọ ojú méjéèjì ni nítorí ìbúgbàmù náà ti ba ojú wọn jẹ́.
“Mi ò rí nǹkan tí mo rí ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun náà rí láyé mi.”
Dókítà Warrak tó fi ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ hàn ní ọ̀pọ̀ àwọn tí òun yọ ojú wọn ló jẹ́ pé ọjọ́ orí wọn wà láàárín ogún ọdún ó lé díẹ̀.
Ó ṣàlàyé òun kò ì tíì ráyé sinmi láti ìgbà tí òun ti ń ṣiṣẹ́ fún odidi ọjọ́ kan.

Ó wá kan sáárá sáwọn ẹbí àwọn tó farapa náà fún bí wọ́n ṣe fi sùúrù gba nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn wọn.
Èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ló ti farapa , táwọn tó lé ní igba sì wà nínú ìrora tó lágbára.
Nínú ìbúgbàmù kejì tó wáyé, kò dí ní èèyàn mẹ́rìnlá tó ti dágbére fáyé táwọn tó sì farapa sì lé ní 450 gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ètò ìlera ṣe sọ.

Hezbollah, tí Iran ń ṣe àtìlẹyìn fún ní àwọn òṣìṣẹ́ Hezbollah tó wà káàkiri àwọn iléeṣẹ́ ló ni àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ pager tí wọ́n sì fìdí ikú àwọn èèyàn wọn múlẹ̀.
Orílẹ̀ èdè Israel ni Hezbollah àti olóòtú ìjọba Lebanon di ẹ̀bi ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù náà rù.
Iléeṣẹ́ ológun ks láti sọ ohunkóhun lórí ẹ̀sùn náà.
Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn ní ọgbẹ́ tí ìbúgbàmù náà dá sí àwọn èèyàn lára kọjá nǹkan tí èèyàn lè máa fi ẹnu ròyìn.
Ó ní ojú, ìbàdí, ọwọ́ ni àwọn èèyàn ti farapa jùlọ.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn gan ni ẹ̀yà ara wọn kò pé mọ́.
Gbogbo àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè náà ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá lójijì tí wọn kò sì le sọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ gan.













