Kí gan-an ló ń ṣẹlẹ̀ láàrin Yahaya Bello àti EFCC?

Àsíá EFCC àti Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, YAHAYA BELLO/FACEBOOK

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Níṣe ni ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ lórí àbẹ̀wò tí wọ́n ní gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Kogi, Yahaya Bello ṣe sí iléeṣẹ́ àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu ní Nàìjìríà ìyẹn Economic and Financial Crimes Commission (EFCC).

Agbẹnusọ Yahaya Bello, Ohiare Michael lọ́jọ́rú fi ìròyìn síta pé ọ̀gá òun ti lọ sí ọ́fíìsì EFCC láti lọ jẹ́ ìpè tí wan ti ń pè é láti bíi oṣù mélòó kan sẹ́yìn.

Àmọ́ nírọ̀lẹ́ ọjọ́rú kan náà ni EFCC fi àtẹ̀jáde síta lórí ìkànnì ayélujára X wọn pé Yahaya Bello kò sí ní àkàtà àwọn àti pé àwọn ṣì ń wà gẹ́gẹ́ bí àwọn ti fi léde ṣáájú fún ẹ̀sùn ṣíṣe owó tó lé ní ọgọ́rin bílíọ̀nù náírà kúmọkùmọ.

Àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ Yahaya Bello, Ohiare Michael fi síta ní òwúrọ̀ ọjọ́rú ló ti sọ pé ọ̀gá òun ti lọ sí olú ilé iṣẹ́ EFCC tó wà ní ìlú Abuja láti jẹ́ ìpè tí wọ́n fi ránṣẹ́ láti oṣù díẹ̀ sẹ́yìn.

Michael sọ nínú àtẹ̀jáde náà pé lẹ́yìn tí ọ̀gá òun ti kàn sáwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ àtàwọn tí wọ́n jẹ́ èèkàn fún-un ló pinnu láti yọjú sí EFCC.

Ó ní ọ̀gá òun ní ọ̀wọ̀ tó pọ̀ fún òfin, tó sì máa ń fẹ́ ṣe nǹkan rẹ̀ ní ìlànà tí òfin bá là kalẹ̀ àti pé ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn rẹ̀ ló ń jà fún ló ṣe kọ̀ láti yọjú sí EFCC láti ọjọ́ yìí.

Ó ṣàlàyé pé Yahaya Bello lo àkókò tó fi lọ sí ọ́fíìsì EFCC láti lọ ṣe àfọ̀mọ́ orúkọ ara rẹ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án náà.

Michael fi kun pé “ẹjọ́ náà ti wà níwájú ilé ẹjọ́ tí àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ sì ti ń ṣojú rẹ̀ níbi gbogbo ìgbẹ́jọ́ tó ti wáyé sẹ́yìn àmọ́ ó pọn dandan kí Yahaya Bello lọ dá EFFC lóhùn ìpè wọn, kó lè wẹ ara rẹ̀ mọ́ pé òun kò ní ẹbọ lẹ́rù tí òun ń fi pamọ́.”

Ó fi kun àtẹ̀jáde rẹ̀ pé àwọn lọ́ọ́kọ lóókì èèyàn lágbo òṣèlú ló tẹ̀lé Yahaya Bello lọ sí iléeṣẹ́ EFCC náà àti pé àwọn máa fi nǹkan tí àwọn bábọ̀ láti ibẹ̀ léde tó bá yá.

Yahaya Bello kò sí ní àhámọ́ wa - EFCC

Àmọ́ níṣe ni ọ̀rọ̀ gba ibòmíràn yọ nígbà tí EFCC fi ìròyìn léde pé gómìnà tẹ́lẹ̀ rí náà kò sí ní àháma àwọn.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale fi sórí ìkànnì X rẹ̀ ní àwọn ṣì ń wá Yahaya Bello lórí ẹ̀sùn tó wà lọ́rùn rẹ̀.

Wọ́n ní àwọn ri nínú ìròyìn pé wọ́n ní Yahaya Bello wà ní àkàtà àwọn àmọ́ fẹ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà nítorí kò sí lọ́dọ̀ àwọn.

“Bello tí a ti kéde pé à ń wá ni a ṣì ń wá títí di àsìkò yìí, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwé àṣẹ tí a rí gbà láti fi nawọ́ gan ṣì wà lọ́wọ́ wa,” EFCC sọ nínú àtẹ̀jáde náà.

Àtẹ̀jáde EFCC yìí tako nǹkan tí agbẹnusọ Yahaya Bello ti fi síta ṣíwájú pé ó ti yọjú sí EFCC.

EFCC kò fọ̀rọ̀ wá Yahaya Bello lẹ́nu wò, wọ́n ní kó máa ló sílé.

Àtẹ̀jáde tí EFCC fi síta

Oríṣun àwòrán, EFCC/X

Ẹ̀wẹ̀, nínú àtẹ̀jáde míì tí agbẹnusọ Yahaya Bello, Ohiare Michael tún fi síta tẹnumọ pé ọ̀gá òun yọjú sí ọgbà EFCC àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà kò fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò.

Michael ní gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi, Usman Ododo wà lára àwọn tó tẹ̀lé Yahaya Bello lọ sọ́dọ̀ àwọn EFCC.

Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ EFCC ní kí Yahaya Bello máa lọ sílé, pé wọn kò fọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò nígbà tó yọjú sí wọn àmọ́ àwọn kò mọ nǹkan tí wọ́n sọ náà túmọ̀ sí.

Èyí ti ń mú kí àwọn ọmọ Nàìjíríà máa sọ̀rọ̀ láti mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ gan láàárín EFCC àti Yahaya Bello.

Àwọn èèyàn ń sọ pé báwo ni ẹni tí EFCC ti kéde pé àwọn ń wá fún ọ̀pọ̀ oṣù ṣe máa yọjú sí iléeṣẹ́ wọn tí wọn yóò sì sọ pé kó máa lọ láì fọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò.

Ní ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án ni ìgbẹ́jọ́ láàárín EFCC àti Yahaya Bello yóò tún wáyé.

Ẹjọ́ tó wà lọ́rùn Yahaya Bello

Àwòrán ọ̀gá àgbà EFCC, Ola Olukoyede àti Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, EFCC/KOGI STATE GOVT

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ọdún 2022 ni EFCC fi ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu owó bílíọ̀nù mẹ́wàá náírà kan àwọn tó jẹ́ abẹ́ṣinkáwọ́ Yahaya Bello, tó fi mọ́ ìbátan rẹ̀ kan, Ali Bello.

Nígbà tó di ọjọ́ Karùn-ún oṣù Kejì ọdún 2024, èyí tó jẹ́ ọ̀sẹ̀ kan tí Yahaya Bello parí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi, ni EFCC ṣe àtúnṣe sí ẹ̀sùn náà, tí wọ́n sì sọ ẹ̀sùn náà di mẹ́tàdínlógún, tí wọ́n sì dárúkọ Yahaya Bello gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn tó wà nídìí ìwà àjẹbánu ọ̀hún.

EFCC fẹ̀sùn kan Yahaya Bello pé ó lẹ̀dí àpòpọ̀ pẹ̀lú Ali Bello, Dauda Sukeiman àti Abdulsalam Hudu láti kó owó tó lé ní ọgọ́rin bílíọ̀nù náírà tó jẹ́ owó ìpínlẹ̀ Kogi sí àpò ara wọn nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún 2015.

Èyí ló jẹ́ bíi oṣù mẹ́rin kí Yahaya Bello tó di gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi ní 2016.

Ẹjọ́ náà ṣì wà níwájú adájọ́ James Omotosho ti ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja.

Ẹ̀wẹ̀, EFCC tún pe ẹjọ́ ẹlẹ́sùn mọ́kàndínlógún mìíràn síwájú adájọ́ Emeka Nwite ti ilé ẹjọ́ gíga Abuja bákan náà.

Àwọn ẹ̀sùn tuntun yìí fara jọ èyí tí wọ́n kà si Yahaya Bello lọ́rùn tẹ́lẹ̀ àmọ́ wọ́n ní oṣù Kejì ọdún 2016 ni ìwà àjẹbánu náà wáyé.