Ikọ̀ alákatakítí ẹ̀sìn tó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Al-Qaeda ní àwọn ló wà nídìí ìkọlù Mali

Àwọn ará ìlú ń fi èrò wọn hàn lórí ìkọlù náà

Oríṣun àwòrán, EPA

    • Author, Wedaeli Chibelushi & Paul Njie
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ikọ̀ alákatakítí ẹ̀sìn tí wọ́n ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú al-Qaeda ní àwọn ló wà nídìí ìkọlù tó wáyé ní ìlú Bamako tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀ èdè Mali.

Àwọn aláṣẹ orílẹ̀ èdè náà sọ pé àwọn agbébọn tí wọ́n pè ní àwọn agbéṣùmọ̀mí ló ṣèkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni ológun àtàwọn agbègbè míì ní ìlú náà.

Ikọ̀ alákatakítí ẹ̀sìn Jama’at Nusrat al-Islam wal Muslimin (JNIM) ní àwọn ló wà nídìí ìkọlù náà.

Ìkọlù náà ni àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tí yóò wáyé ní Bamako. Kó tó di ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ìlú Bamako kò ní ìkọlù àwọn alákatakítí ẹ̀sìn tó ti ń bá orílẹ̀ èdè Mali fínra láti bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.

Ikọ̀ JNIM jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn alákatakítí ẹ̀sìn tó ń ṣọṣẹ́ ní ẹkùn Sahel, tí wọ́n sì ti ṣe ìkọlù lọ́kan-ò-jọ̀kan ní orílẹ̀ èdè Mali, Burkina Faso àti Niger.

Wọ́n ní àkànṣe ìkọlù náà tó wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun jẹ́ ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni àti pápákọ̀ òfurufú àwọn ọmọ ogun ní èyí tó ṣokùnfà ikú àwọn ọmọ ogún.

Iléeṣẹ́ ìròyìn New York Times ròyìn pé àwọn ọmọ ogun Mali sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ológun ni wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn, tí àwọn mìíràn sì farapa. Bákan náà ni wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọkọ̀ adóòlà ẹ̀mí ni wọ́n fi gbé àwọn ọmọ ogun lọ sí ilé ìwòsàn.

Ìjọba kò sọ nǹkan tí wan pàdánù pàtó àmọ́ tí wan sọ pé ilé ẹ̀kọ́ àwọn ológun náà wà lára ibi tí àwọn agbéṣùmọ̀mí náà ṣe ìkọlù sí.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ iléeṣẹ́ ológun Mali ní àwọn ń ṣe àmójútó ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún àti pé àwọn èèyàn lè máa bá iṣẹ́ wọn lọ láì sí ìbẹ̀rù tàbí ìfòyà kankan.

Iléeṣẹ́ ìròyìn AFP ní àwọn agbéṣùmọ̀mí náà àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ni wọ́n kojú ìbọn síra wọn ní ọ̀sán ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́ ọlọ́pàá tó ń mójútó pápákọ̀ òfurufú.

Ní àsìkò yẹn kan náà ni ikọ̀ JNIM ní àwọn ti gba àkóso pápákọ̀ òfurufú iléeṣẹ́ ológun àmọ́ BBC kò ì tíì lè fìdí èyí múlẹ̀.

Ṣáájú ni iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán Mali ṣàfihàn àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí iye wọn tó ogún, tí wọ́n fi aṣọ bo ojú wọn, tí wọ́n sì di ọwọ́ wón pẹ̀lú.

Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun, Oumar Diarra nínú ìròyìn iléeṣẹ́ náà ní ọwọ́ ti tẹ àwọn agbéṣùmọ̀mí náà àti pé àwọn ń ṣe iṣẹ́ láti ri pé wọ́n fọ orílẹ̀ èdè náà mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn agbéṣùmọ̀mí.

Bákan náà ni ìròyìn náà tún ṣàfihàn àwọn èèyàn bíi mẹ́ta tó wà nílẹ̀ láì mira.

Àwọn àjọ àgbáyé tó wà ní Mali bíi UN ti ṣèkìlọ̀ fún àwọn èèyàn wọn láti ṣọ́ra nígbà tí wọ́n bá ń jáde, kí wọ́n sì mọ ojú ibi tí wọn yóò máa lọ.

Àwọn fídíò tó gba orí ayélujára ṣàfihàn bí èéfí dúdú ṣe ń ru ní àwọn apá ibìkan ní ìlú náà.

Lẹ́yìn ìkọlù náà ni wan ti pápákọ̀ òfurufú Modibo Keita tó wà ní Bamako pa.

Ní ọdún 2021 ni àwọn ológun fipá gba ìjọba lọ́wa ìjọba alágbádá fẹ́sùn wí pé wọn kò ṣe ohun tó yẹ láti fòpin sí ìwà ìgbéṣùmọ̀mí.

Àwọn ológun náà lé ikọ̀ ọmọ ogun France àti àwọn apẹ̀tù sááwọ̀ àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN kúrò ní Mali, tí wọ́n sì ránṣẹ́ sí ikọ̀ ọmọ ogun Wagner ti Russia láti báwọn kojú àwọn alákatakítí ẹ̀sìn náà àmọ́ ó jọ́ wí pé ìgbéṣùmọ̀mí kò ṣetán láti parẹ́ ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún lásíkò yìí.

Èéfín tó ń jáde ní Bamako, Mali

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Footage shows plumes of smoke rising above the city