Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ ní Naijiria tí wọ́n bá ṣí adágún odò Lagdo ni Cameroon?

Lọdọdun ti wọn ba ti n mura silẹ lati ṣi adagun odogun odo Lagdo to wa ni Cameroon ni aya ọpọ eeyan maa n ja ni Naijiria.
Ọpọ ẹmi lo ti sọnu sẹyin lẹyin ti wọn ba ti ṣi odo naa silẹ ti yoo si tun sọ ọpọ eeyan di alairilgbe.
Lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni ajọ to n ri si ọrọ oju ọjọ ni Naijiria, Nigerian Hydrological Services Agency (NIHSA), ṣe ikilọ pe o ṣeeṣe ki iṣẹlẹ omiyale waye lawọn ipinlẹ mọkanla ni Naijiria lẹyin ti Cameroon ba ṣi omi naa tan.
Lara awọn ilu to ṣeeṣe ki ọrọ naa kan ni Adamawa, Anambra, Bayelsa, Benue, Cross River, Delta, Edo, Kogi, Nasarawa, Rivers, ati Taraba latari pe ẹkun omi maa n gba adugbo lawọ ipinlẹ ọhun lẹyin ti Cameroon ba ṣi omi naa tan.
Amọ adari ajọ NIHSA, Umar Mohammed ti sọ pe awọn yoo gbe igbesẹ lati ma jẹ ki omi naa pọ lagbegbe River Benue lọna ati dena omiyale ni Naijiria.
Ki ni eredi ti adagun omi Lagdo to wa ni Camerron ṣe maa n da wahala silẹ ni Naijiria?
Adagun odo Lagdo ni wọn ṣe lọdun 1982 lati pese ina mọnamọna fun ariwa Cameroon ati lati pese omi fun awọn ohun ọgbin kan nibẹ.
Amọ adagun odo naa maa n kun akunfaya nigba mii, ti yoo si nilo ki wọn ṣi silẹ lati jo diẹ lara omi ọhun.
Iroyin ni o yẹ ki ijọba Naijiria kọ adagun odo tirẹ, iyẹn ‘Dasin Hausa Dam’ nipinlẹ Adamawa ti yoo maa gba omi to ba n ṣan bọ lati Cameroon amọ ijọba ko tii pari kikọ adagun naa.
Eredi ree ti omi to n ṣan lati Lagdo fi n ṣakoba ni Naijiria.
Ipa wo ni ṣiṣi adagun odo Lagdo n ni lara Naijiria?
Lọdun to kọja, ijọba Naijiria sọ pe omiyala ṣekupa eeyan mejidinlọgbọn, o si sọ eeyan to le ni ẹgbẹrun mejidinlaadọta di alairilegbe latari adagun odo lagdo ti wọn ṣi ni Cameroon.
Lọdun 2022, eeyan 612 lo jade laye, nigba ti eeyan to le ni miliọnu meji di alainilelori ni Naijiria latari pe wọn ṣi odo Lagdo ni Cameroon.
Lọdun naa lọhun, ile gbigbe 181,600 lo ba omi lọ, nigba ti ile 123,807 mii faragba nibẹ, ti omi tun wọ eeka ilẹ 176,852 lọ, to fi mọ eeka ilẹ oko 392,399.
Ki ni yoo ṣẹlẹ lọdun yii?
Ibrahim Audu Usaini, to jẹ olori ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Adama sọ fun BBC pe awọn ti bẹrẹ ilanilọyẹ fun awọn eeyan agbegbe ti omi le gbe lọ.
Usaini fi kun pe awọn tun ti bẹrẹ si n ko awọn eeyan kuro lawọn agbegbe ti o ṣeeṣe ki ọrọ naa kan.
O ni “a oo tun pese ounjẹ atawọn nnkan mii fun wọn nitori pupọ ninu wọn ni ko fẹ fi ile ati adugbo wọn silẹ.
O ni gbogbo ohun to yẹ lawọn n ṣe lati gbaradi fun odo naa ti wọn yoo ṣi laipẹ.















