Seyi Makinde bẹ̀rẹ̀ ètò sísọ pápákọ̀ òfúfurú Ibadan di ti àgbáyé pẹ̀lú ₦41b

Ni ibi akanṣe eto to waye l'Ọjọru ni papakọ ofurufu Samuel Ladoke Akintọla to n bẹ ni agbegbe Alakia niluu Ibadan ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Maknde ti ṣe ifilọlẹ eto lati sọ papakọ ofurufu naa di ibi ti awọn arinrinajo yoo maa gba lọ oke okun.
Ninu ọrọ ti o sọ ni ibi ipejọpọ naa, Makinde ni awọn eeyan kan le ro wi pe imugbooro papakọ ofurufu naa kọ ni nnkan to yẹ ki ijọba maa mojuto lasiko yii, ṣugbọn igbesẹ ti ijọba oun gbe lo da lori iṣẹ iwadii ati ọgbọn ori.
O tẹsiwaju wi pe oun ṣetan lati takurọsọ ni itagbangba pẹlu ẹnikẹni to ba fẹ ṣe ariyanjiyan lori igbesẹ naa.
Makinde ni akanṣẹ iṣe ti wọn fi lọlẹ lonii yoo na ijọba ipinlẹ Ọyọ ni owo ti o to Billiọnu mọkanlelogoji Naira ki o to yọri.
O ṣalaye pe iṣẹ naa yoo pari laarin oṣu mejila (botilẹ jẹ wi pe oṣu mẹrindilogun ni igbimọ ẹlẹni mọkanla to n ṣe akoso akanṣe iṣẹ naa da fun ijọba ipinlẹ Ọyọ).
Makinde tẹ siwaju wi pe imugbooro papakọ ofurufu naa yoo pakun eto ọrọ aje ipinlẹ Ọyọ lati ode agbaye, gẹgẹ bi o ṣe n ṣalaye wi pe wọn ko ṣe ifilọlẹ iṣẹ naa lati ṣe afẹfẹ-yẹyẹ bikoṣe lati ṣe agbekalẹ idokowo to ni anfani ninu, ti iye owo ti wọn o na lori iṣẹ naa ko si ni ṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ni eegun ẹyin.

O ni igun akọkọ ninu eto imugbooro papakọ ofurufu naa ni wọn fi lọlẹ lonii.
Afojusun awọn igun to ku ni ibi ti awọn ọkọ ofurufu yoo maa ba si, ibi ti awọn arinrinajo yoo ti maa wọ ọkọ ofurufu ati awọn ina ti wọn o ṣe si ibi ti ọkọ ofurufu yoo ti maa ba.
Makinde fi kun ọrọ rẹ wi pe akanṣe iṣẹ naa ko ni nnkan kan ṣe pẹlu ẹya tabi ẹgbẹ oṣelu ti ẹnikẹni n ṣe. O ni ohun to ṣe pataki julọ ni ki awọn ri akọṣemọṣẹ to danto to si le ṣe aṣepe iṣẹ fun imugbooro papakọ ofurufu naa.
O fi idi ọrọ mulẹ wi pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni alaga igbimọ ẹlẹni mọkanla to gbe kalẹ fun iṣẹ naa, ẹya Igbo ati Hausa kan naa si wa ninu wọn.
Ṣeyi Makinde dupẹ lọwọ Aarẹ Bọla Tinubu fun bi o ṣe buwọlu igbesẹ lati mu papakọ ofurufu naa gbooro sii, bakan naa ni o nawọ idupẹ si gbogbo ẹni to lọwọ si igbesẹ naa, awọn ladelade-loyeloye, aṣiwaju ẹsin, ati mọlẹbi Samuel Ladoke Akintola ti wọn yọnda ile ti baba wọn kọ si ilu Ogbomọṣọ fun ijọba ipinlẹ Ọyọ.

Ninu ọrọ tiẹ nibi ipejọpọ naa, Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adekele ki Gomina Ṣeyi Makinde ku oriire fun igbesẹ naa. O ni ipinlẹ Ọṣun naa ti n sa ipa lati yọri papakọ ofurufu ilu Oṣogbo ti wọn ti wa lẹnu rẹ fun ọdun mejila gbako.
O fi kun ọrọ wi pe gbogbo ipa ni ijọba ipinlẹ naa yoo sa lati riidaju wi pe wọn ṣe agbekale papakọ ofurufu naa nilana igbalode.
Lara awọn alejo pataki to ba wọn pejupesẹ si ibi akanṣe eto naa ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke ti o ge okun ti wọn fi ṣe ami ifilọlẹ iṣẹ naa. Gomina Ṣeyi Makinde si fi idi rẹ mulẹ wi pe Adeleke naa ni yoo ṣi papakọ ofurufu naa bi iṣẹ ba yọri.
Awọn alejo pataki mii to wa ni ibi eto ni igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ, Adebayọ Lawal, Adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Họnọrebu Debọ Ogundoyin, Sẹnatọ ile igbimọ aṣofin agba ti o tun jẹ alaga igbimọ ile to n ri si ọrọ irinajo ofurufu lorilẹede yii.
Sẹnatọ Fatai Buhari, oludije tẹlẹri si ipo Gomina ipinlẹ Ogun, Ladi Adebutu, aṣoju Olubadan ilẹ Ibadan, Oba Owolabi Olakulehin, Ṣọun ile Ogbomọṣọ, Oba Ghandi Olaoye, Okere Ṣaki.

Awọn mii ni Ọba Khalid Oyeniyi Olabisi, Asẹyin ilu Isẹyin, Oba Sefiu Olawale Oyebola, Olugbọn ile Igbọn, Oba Francis Alao ati bẹẹ bẹẹ lọ. Awọn aṣiwaju ẹsin ati awọn ẹṣọ aabo naa ko gbẹyin ni ibi akanṣe eto naa.
Ninu oṣu kẹfa ọdun 1982 ni wọn ṣe agbekalẹ papakọ ofurufu ilẹ Ibadan lati ọwọ adari ile igbimọ aṣofin agba nigba naa, Joseph Wayas.
Imugbooro ti Gomina Ṣeyi Makinde fi lọlẹ lonii ni yoo si jẹ ki awọn arinrinajo ni anfani lati maa gba ibẹ lọ si oke okun nigba ti iṣẹ ba yori tan.















