Wo àfijọ tó wà láàárín Arsenal àti ilẹ̀ Afirika

Aworan Ian Wright, Nwankwo Kanu ati Bukayo Saka

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Ameer Ahmed and Khadidiatou Cisse
    • Role, BBC Sport Africa
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ni ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan an ọdun 2002, ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal di ẹgbẹ agbabọọlu akọkọ lati darukọ awọn agbabọọlu to jẹ eeyan dudu mẹsan an lara awọn agbabọọlu ti yoo gba ifẹsẹwọnsẹ ninu idije liigi Premier League.

Mẹta ninu awọn agbabọọlu yii - Thierry Henry, Nwankwo Kanu ati Kolo Toure – mi awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ naa bi Gunners ṣe bori Leed United pẹlu 4-1.

“Iṣe wọn lasiko ifẹsẹwọnsẹ naa ṣe pataki fun ẹya eeyan dudu,” Dokita Chijoike Nwonka, Ọjọgbọn ni Fasiti London, sọ fun BBC Africa.

"O fihan pe wọn sisẹ de ibi aṣeyọri wọn."

Dokita Nwonka ti ṣawari ipa ti ẹgbẹ agbabọọlu naa ti ko ninu itan aṣa dudu gẹgẹ bi olootu ti iwe Black Arsenal to tẹ jade laipẹ, eyi ti o pẹlu awọn ẹri ati fọtoyiya lati ọdọ awọn ti o ni ajọsepọ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu ariwa London.

"Mo jẹ ọmọ Naijiria ti Ilu Gẹẹsi, riri awọn agbabọọlu dudu ati awọn agbabọọlu Afirika ti o ṣoju ni bọọlu Gẹẹsi ṣe pataki fun mi,” o sọ.

Aworan Dr Clive Chijioke Nwonka h
Àkọlé àwòrán, y

Apakan ti iwe naa ṣe itupalẹ ipa ti Arsenal ko fun awọn agbabọọlu ẹya dudu ni idije liigi Premier League ati bi awọn ololufẹ wọn ti wọn jẹ obinrin se n gboro si ni papa iṣere Emirates ti ẹgbẹ naa.

"Nigba gbogbo mo ma mọ pe nnkan kan wa ti o ṣe pataki, ti a ni lati ṣawari, nipa awọn ọna ti awọn eniyan dudu fi ni ajọsepọ pẹlu Arsenal," Dokita Nwonka sọ.

Fun awọn ololufẹ, atilẹyin fun ẹgbẹ agbabọọlu wọn lo se koko ni igbesi aye ojoojumọ wọn, ati pe ifaramọ yii han ninu iwe naa.

"Ti mo ba sọ Arsenal, o tumọ aṣa bi Arsenal ṣe ṣe pataki si awọn eniyan dudu," Dokita Nwonka fi kun.

"Kii ṣe awọn biriki ati amọ ti ẹgbẹ agbabọọlu naa, ṣugbọn awọn ọna ti a rii Arsenal lati ṣe itọkasi ibujoko ayọ fun aṣa ẹya dudu - boya awọn ibi iṣẹ wa, awọn ile-gẹrigẹri ati ni ile ijọsin."

Wenger ati Afrika

Aworan akọnimọgba Arsene Wenger ati Balogun Patrick Vieira

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, t

Ian Wright jẹ agbabọọlu kan ti ọpọlọpọ awọn ololufẹ Arsenal dudu fẹran ni ọdun 1990, pẹlu eyin goolu rẹ, iwa akikanju ati bi o se n gba goolu wọle fun Arsenal.

Kii ṣe ọpọlọpọ awọn alatilẹyin Gunners ni yoo ko gba pẹlu fọto rẹ ti o wa loju iwe Black Arsenal ṣugbọn, fun Dokita Nwonka ati awọn ọmọ Naijiria miiran, agbabọọlu pataki miiran wa.

Wọn ranti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria to na Argentina lati gba ami ẹyẹ goolu Olympic ni ọdun 1996, ati paapaa ẹni to gba ami ayo to se pataki wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Brazil – Kanu.

Wọn bi ni ilu Imo, agbaboolu naa darapo mo Arsenal lati inu agbaboolu Inter Milan ni odun 1999.

“Wiwa rẹ si Arsenal jẹ pataki fun mi ati eniyan bii te mi,” Dokita Nwonka sọ.

Arsene Wenger, akọnimọgba Arsenal nigba naa, jẹ olokiki fun rira awọn agbabọọlu Faranse ati Afirika, ti yoo si sọ wọn di olorukọ nla ni ọdun mejilelogun ti o lo lati 1996 si 2018.

Akọnimọgba ọmọ Faranse ni ọpọ ni ibowo nla fun bi o se n dari ẹgbẹ naa ati iṣakoso rẹ nigbati Arsenal gba liigi ni ṣaa 2003-04.

Ijagunmolu yẹn jẹ ilọsiwaju nipasẹ bi ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ko se padanu ifẹsẹwọnsẹ kankan - aṣeyọri ti a ko ti ri mii iru rẹ.

Ẹgbẹ naa , ti a pe ni Invincibles, pẹlu olugbeja wọn, ọmọ orilẹede Ivory Coast Toure ati agbawọ-ọtun Cameroon Lauren, pẹlu Kanu.

"O jẹ ohun kan lati ni awọn agbabọọlu Afirika ti o n ṣe daradara ti wọn si nṣe ere, ṣugbọn iṣẹgun mu wọn da yatọ," Dokita Nwonka sọ.

Jija pada lati tako ẹlẹyamẹya

Aworan awọn agbabọọlu Arsenal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Pẹlu aṣeyọri oniyalẹnu ti awọn agbabọọlu dudu, ẹlẹyamẹya jẹ ọrọ ti o tan kaakiri lori papa.

Ni ọdun 2021, lẹyin ti wọn fidi rẹ mi ni ipele aṣekagba Euro 2020, awọn agbabọọlu England mẹta - Bukayo Saka, Jadon Sancho ati Marcus Rashford - dojuko ẹlẹyamẹya lori ayelujara lẹyin ti o padanu awọn pẹnariti.

Eniyan mọkanla ni wọn mu, Arsenal si gbe atẹjade sitan lati ṣe atilẹyin Saka ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ mẹta yooku.

“Eyi ko le tẹsiwaju, ati pe awọn alakoso ayelujara ati awọn alaṣẹ gbọdọ ṣiṣẹ lati rii daju ẹlẹyamẹya tẹnubọ omi,” o sọ.

Ẹwẹ, Saka ti gba eebu dii lẹyin pipadanu si Nottingham Forest ni ọdun to kọja.

Ojo iwaju Arsenal

Aworan Bukayo Saka

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni saa yii Arsenal ti ṣe ayẹyẹ ohun-ini Afirika wọn ati asopọ wọn pẹlu ile adulawọ pẹlu aṣọ wọn to ni awọ asia Afrika.

Foday Dumbuya, ọmọ bi ilu Sierra Leone lo ṣe aṣọ naa ati pe ifilọlẹ rẹ waye ni Freetown olu-ilu orilẹ-ede naa.

"O dara lati mu pada si ibi ti mo ti wa, lati wo ni ọna ti awọn ọmọde yoo ni ajọsepọ pẹlu ere bọọlu afẹsẹgba, ọna ti awọn eniyan n wo bọọlu pada ni Afirika, nitori pe bọọlu jẹ igbesi aye," Dumbuya sọ.

Gẹgẹ bi eeyan ti o dagba ni Ilu London, Dokita Nwonka ṣe apejuwe aṣọ Arsenal gẹgẹ bi “aṣọ idanimọ” ti ilu naa.

O ro pe aṣa ti n waye ni nilẹ Afirika.

Saka, ti wọn bi ni Ilu London ti awọn rẹ Naijiria, ni ọpọ awọn ololufẹ Arsenal n ri gẹgẹbi 'Ọmọ irawọ' - ọrọ sisọ kan fun ọdọmọkunrin olokiki

Ẹni ọdun mẹtalelogun naa ti kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ to le ni igba fun Gunners, to si n sọrọ soke nipa ija ẹlẹyamẹya ati aibikita aṣa ninu ere naa.

O jẹ agbabọọlu tuntun ninu itan-akọọlẹ ti Arsenal nipa awọn eeyan dudu.