'Ẹ fipá bámi lòpọ̀, ẹ má fọwọ́ kàwọn ọmọbìnrin mi'

Oríṣun àwòrán, BBC/Mohanad Hashim
- Author, Barbara Plett Usher
- Role, BBC Africa correspondent, Omdurman
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bí èèyàn nínú wà nínú ìròyìn yìí.
Lẹ́yìn oṣù mẹ́tàdínlógún tí ogun abẹ́lé ti ń wáyé ní orílẹ̀ èdè Sudan, iléeṣẹ́ ológun ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù tó lágbára sí olú ìlú Khartoum.
Oríko àwọn ikọ̀ ọmọ ogun Rapid Support Forces (RSF) ni wọ́n gbèrò láti ṣe àwọn ìkọlù náà sí.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ogun ọ̀hún ni àwọn ikọ̀ RSF gba ọ̀pọ̀ àwọn igboro Khartoum nígbà tí iléeṣẹ́ ológun ń ṣe àkóso agbègbè Omdurman tó wà ní ẹ̀yin River Nile.
Àmọ́ àwọn ibòmíràn wà tí àwọn èèyàn lè gbà láti fi já sí ara wọn.
Mo pàdé àwọn obìnrin kan ní irú àwọn agbègbè yìí, wọ́n ti rìn fún wákàtí mẹ́rin láti lọ sí ọjà tó wà ní ẹkùn tí àwọn iléeṣẹ́ ológun ń ṣe àkóso rẹ̀ ní ẹ̀bá Omdurman níbi tí oúnjẹ ti wà lọ́pọ̀.
Láti Dar es Salaam, ti àwọn RSF ni àwọn obìnrin náà ti wá.
Àwọn obìnrin náà sọ fún mi pé àwọn ọkọ àwọn kìí jáde nílé mọ́ nítorí àwọn ọmọ ogun RSF máa ń lù wọ́n, gba owó lọ́wọ́ wọn tàbí kí wọ́n fi wọ́n sí àhámọ́ láti gba owó ìtúsílẹ̀ wọn.
“À ń fi orí ti àwọn ìdojúkọ yìí nítorí à ti bọ́ àwọn ọmọ wa. Ebi ń pa wá, a nílò oúnjẹ.”
Mo bèèrè pé ṣé ààbò wà fún àwọn obìnrin ju ọkùnrin lọ ni? Ìfipábánilòpọ̀ ńkọ́?
Ọ̀kan fún mi lésì pé “níbo ni àgbáyé wà? Kí ló dé tí ẹ kò ràn wá lọ́wọ́?
“Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ni wọ́n ti fipá bá lòpọ̀ àmọ́ wọn kò lè sọ ohunkóhun.
“Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ni àwọn RSF máa ní kí wọ́n sùn sí orí títì lálẹ́. Tí wọ́n bá fi lè pẹ́ kúrò ní ọjà yìí, RSF lè fi wọ́n sí àhámọ́ fún ọjọ́ márùn-ún sí mẹ́fà.”
Bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀ ni ìyá rẹ̀ ń sunkún tí àwọn obìnrin tó wà níbẹ̀ náà sì ń sunkún.
“Ṣé tí ìwọ kò bá rí ọmọ tìrẹ ó máa fi sílẹ̀? Àmọ́ kí ni àwa fẹ́ ṣe? Kò sí nǹkankan lọ́wọ́ wa, kò sí ẹni tó rán wa.”
I said to the RSF: 'If you want to rape anyone it has to be me.' They hit me and ordered me to take off my clothes. Before I took them off, I told my girls to leave
Ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìn-àjò ni wọ́n júwe àwọn ìwà kò tọ́ tí wọ́n ń wù sí wọn.
Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN ní èèyàn tó ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́wàá ló ti sá kúrò ní ilé wọn láti ìgbà tí ogun náà ti bẹ̀rẹ̀.
Ìwà Ìfipábánilòpọ̀ ti di nǹkan tó jẹ́ ohun tí ó ń wáyé lemọ́lemọ́.
Ìfaǹfà lórí ipò agbára láàárín iléeṣẹ́ ológun àti ikọ̀ RSF ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ogun náà, tí àwọn fijilanté láti orílẹ̀ èdè tó súnmọ́ ti darapọ̀ mọ́ wọn.
Ọ̀gá àgbà Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ní àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, Volter Turk ni wọ́n ń lo Ìfipábánilòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà ogun.
Ìwádìí UN kan ṣàfihàn rẹ̀ pé àwọn ọmọ ogun ń fipá bá àwọn èèyàn lòpọ̀ àti pé ọ̀pọ̀ ìwà Ìfipábánilòpọ̀ tó pọ̀ jùlọ ló wáyé látọwọ́ àwọn ikọ̀ RSF àtàwọn ajagùntà.
Ọ̀kan lára àwọn obìnrin tó bá BBC sọ̀rọ̀ ní ikọ̀ RSF ló fipá bá òun lòpọ̀.
Ní ọjà Souk al-Har ni a ti pàdé rẹ̀.
Láti ìgbà tí ogun náà ti bẹ̀rẹ̀ ni ọjà náà ti ń kún púpọ̀ nítorí àwọn ọjà rẹ̀ tó dínwó.

Oríṣun àwòrán, BBC/Ed Habershon
Miriam, kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gangan nìyí, sá kúrò ní ilé rẹ̀ tó wà ní Dar es Salaam láti lọ máa gbé pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
Nígbà tí ogun ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, Miriam ní àwọn ọkùnrin méjì pẹ̀lú ohun ìjà ogun lọ́wọ́, yawọ ilé òun tí wọ́n sì fẹ́ fi ipá bá àwọn ọmọbìnrin òun méjì tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọdún mẹ́wàá àti mẹ́tàdínlógún lòpọ̀.
“Mo ni kí àwọn ọmọ mi dúró sí ẹ̀yìn mi, mo sọ fún àwọn ọmọ ogun RSF pé èmi ni kí wọ́n fipá bá lòpọ̀.”
“Wọ́n ní kí n bọ́ aṣọ mi, mo sọ fún àwọn ọmọ mi láti jáde. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun náà sì fipá bá mi lòpọ̀.”
Ikọ̀ RSF sọ fún àwọn olùwádìí pé gbogbo ọ̀nà ni àwọn ń sá láti ri pé àwọn dènà ìwà Ìfipábánilòpọ̀.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fatima, kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gangan, sọ fún mi pé òun wá bímọ sí Omdurman, òun kò sì ní èròńgbà láti padà.
Ó ní ọmọ ará ilé òun, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún náà wà nínú oyún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun RSF mẹ́rin fipá bá òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún lòpọ̀.
Igbe ẹkún ló jí àwọn èèyàn, tí wọ́n sì sáré jáde láti mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ àmọ́ àwọn ọmọ ogun ní àwọn máa yìnbọn mọ́ wọn tí wọn kò bá padà sẹ́yìn.
“Láti ìgbà tí àwọn ọmọ ogun RSF ti dé ni a ti ń gbọ́ nípa Ìfipábánilòpọ̀ àyàfi ìgbà tí a rí báyìí.”
Àwọn obìnrin yòókù ti ń péjọ láti padà sílé wọn ní agbègbè tí àwọn RSF ń ṣàkóso, wọn kò ní owó láti lọ bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun bíi ti Fatima tó fi Dar es Salaam kalẹ̀.
Níwọ̀n ìgbà tí ogun náà bá ṣì ń tẹ̀síwájú, wọn kò lè ṣe ohunkóhun àyàfi kí wọ́n padà sí ìgbé ayé wọn.















