Wo àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa àjọ ìdàgbàsókè ilẹ̀ Yorùbá tí ilé aṣòfin àgbà l'Abuja buwọ́lù

Oríṣun àwòrán, Dipo Awojide/X
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní Nàìjíríà ti buwọ́lu ìdásílẹ̀ àjọ tí yóò máa rí sí ìdàgbàsókè ẹkùn ìwọ oòrùn gúúsù Nàìjíríà ìyẹn South West Development Commission (SWDC).
Ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án ọdún 2024 ni ilé aṣòfin àgbà buwọ́lu àbá náà lẹ́yìn tí alága ìgbìmọ̀ tó ń rí sí àkànṣe iṣẹ́ nílé aṣòfin, Kaka Shehu ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀.
Igbákejì Ààrẹ ilé aṣòfin, Barau Jibrin, tó ṣíwájú ìjíròrò ilé ló buwọ́lu àbá náà lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ àwọn aṣòfin ṣe àtìlẹyìn fún-un.
Aṣòfin Gbenga Daniel, tó fi ìgbà kan jẹ́ gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ogun, ló ṣe àgbékalẹ̀ àbá ọ̀hún síwájú ilé aṣòfin.
Gẹ́gẹ́ bí àbá náà ṣe sọ, tí ó bá dòfin tán, àwọn ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ ìwọ oòrùn gúúsù Nàìjíríà yóò máa gba owó láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀ fún kíkọ́ àti àtúnṣe àwọn nǹkan tó jẹ́ ohun amáyédẹrùn ní ẹkùn náà.
Àwọn ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ ìwọ oòrùn gúúsù Nàìjíríà ni Èkó, Osun, Ogun, Ondo, Oyo ati Ekiti.
Àbá ọ̀hún ni wọn yóò fi ṣọwọ́ sí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fún ìbuwọ́lù láti sọ ọ́ di òfin lẹ́yìn tí ilé aṣòfin àgbà bá ti jíròrò pẹ̀lú ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin.
Àwọn àǹfàní wo ló wà nínú ìdásílẹ̀ àjọ náà?

Oríṣun àwòrán, @SENATENGR
Nígbà tó ń gbé ìjábọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ fún ilé aṣòfin, Shehu ní àbá náà wà ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo àwọn ìlànà tó yẹ kí o tẹ̀lé àti pé yóò mú ìdàgbàsókè bá ẹkùn ìwọ oòrùn gúúsù Nàìjíríà.
Ó ní yóò mú kí àwọn èèyàn ẹkùn náà jẹ mùkúndùn ìjọba àwaarawa ju ti àtẹ̀yìnwá lọ àti pé yóò jẹ́ kí àǹfàní ìjọba àpapọ̀ tètè máa tẹ àwọn èèyàn ẹkùn náà lọ́wọ́.
Ó ní òun gbèrò pé kí wọ́n tètè buwọ́lu àbá náà fún ìdàgbàsókè ẹkùn náà.
Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn ìpèníjà tí ẹkùn ìwọ oòrùn Nàìjíríà ń kojú ni àbá náà yóò wà ojútùú sí.
Àbá yìí, tí Ààrẹ Tinubu bá buwọ́lù ú, yóò jẹ́ ìgbìmọ̀ irú rẹ̀ karùn-ún ní Nàìjíríà.
Afenifere sọ̀rọ̀
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìbuwọ́lu àbá náà, igbákejì alága ẹgbẹ́ Afenifere, Oba Oladipo Olaitan ní àbá tó da ni ó jẹ́ àmọ́ kìí ṣe ohun tí Nàìjíríà nílò lásìkò yìí.
Olaitan wòye pé ìgbésẹ̀ náà yóò mú ìtura fún ìgbà díẹ̀ ni, pé kò lè tán ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú.
Ó ní ìjọba àpapọ̀ nílò láti ṣe àtúntò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, kí wọ́n pín agbára sí ẹkùn kọ̀ọ̀kan, àwọn ọmọ Nàìjíríà lè mú ìdàgbàsókè bá ẹkùn wọn.
Ó ṣàlàyé pé àwọn irúfẹ́ àjọ báyìí tó ti ṣáájú wà ní Nàìjíríà kò so èso rere kankan àti pé òun kò rí ìyàtọ̀ tí èyí náà yóò mú dání.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ní tirẹ̀, agbenusọ ẹgbẹ́ Afenifere, Jare Ajayi ní nǹkan tó dára ní ilé aṣòfin àgbà ṣe àti pé òun ń retí kí ilé aṣojúṣòfin náà buwọ́lu àbá náà láìpẹ́.
Ajayi ní òun gbàgbọ́ pé Ààrẹ yóò buwọ́lu àbá náà ní kété tí wọ́n bá ti fi ṣọwọ́ si.
Ó ní èyí yóò fún àwọn ìpínlẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá ní àǹfàní láti máa gba owó láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀ yàtọ̀ sí owó oṣooṣù tí wọ́n ń pín láti fi mú ìdàgbàsókè bá àwọn ìpínlẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá.















